Míkà 6:1-16
6 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ohun tí Jèhófà ń sọ.
Ẹ dìde, ẹ gbé ẹjọ́ yín lọ síwájú àwọn òkè,Kí àwọn òkè kéékèèké sì gbọ́ ohùn yín.+
2 Ẹ gbọ́ ẹjọ́ Jèhófà, ẹ̀yin òkèÀti ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayé tó fìdí múlẹ̀,+Torí Jèhófà fẹ́ pe àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́;Yóò sì bá Ísírẹ́lì ro ẹjọ́ pé:+
3 “Ẹ̀yin èèyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?
Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi sú yín?+
Ẹ sọ ohun tí mo ṣe.
4 Mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+Mo rà yín pa dà lóko ẹrú;+Mo rán Mósè, Áárónì àti Míríámù sí yín.+
5 Ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ jọ̀ọ́, ẹ rántí ohun tí Bálákì ọba Móábù gbèrò+Àti ohun tí Báláámù ọmọ Béórì fi dá a lóhùn.+
Ẹ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ láti Ṣítímù+ títí dé Gílígálì,+Kí ẹ lè mọ̀ pé òdodo ni Jèhófà ń ṣe.”
6 Kí ni màá mú wá síwájú Jèhófà?
Kí sì ni màá mú wá tí mo bá wá tẹrí ba fún Ọlọ́run lókè?
Ṣé odindi ẹbọ sísun ni màá gbé wá síwájú rẹ̀,Àwọn ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?+
7 Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò,Sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró?+
Ṣé màá fi àkọ́bí mi ọkùnrin rúbọ torí ọ̀tẹ̀ tí mo dì,Àbí màá fi èso ikùn mi rúbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ mi?*+
8 Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé.
Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe?*
Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,*+ kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin,*+Kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ+ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!+
9 Àwọn èèyàn ìlú náà gbọ́ ohùn Jèhófà;Àwọn tó ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ yóò bẹ̀rù orúkọ rẹ.
Ẹ fiyè sí ọ̀pá náà àti ẹni tó yàn án.+
10 Ṣé àwọn ìṣúra tí wọ́n fi ìwà ìkà kó jọ ṣì wà nílé ẹni burúkúÀti òṣùwọ̀n eéfà* tí kò péye tó ń ríni lára?
11 Ṣé mo lè sọ pé ìwà* mi mọ́ tí mo bá ń lo òṣùwọ̀n èkéÀti àpò ayédèrú òkúta òṣùwọ̀n?+
12 Ìwà ipá kún ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ rẹ̀,Òpùrọ́ ni àwọn tó ń gbé inú rẹ̀;+Ahọ́n wọn ń tanni jẹ.+
13 “Torí náà, màá lù ọ́, màá sì ṣe ọ́ léṣe;+Màá sọ ọ́ di ahoro torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
14 Wàá jẹun àmọ́ o ò ní yó,Inú rẹ máa ṣófo.+
Tí o bá tiẹ̀ rí nǹkan kó, o ò ní lè kó o lọ,Tí o bá sì rí i kó lọ, màá fi í fún idà.
15 Wàá fún irúgbìn, àmọ́ o ò ní ká a.
Wàá tẹ ólífì, àmọ́ o ò ní lo òróró rẹ̀;Wàá ṣe wáìnì tuntun, àmọ́ o ò ní rí wáìnì mu.+
16 Torí ò ń tẹ̀ lé òfin Ómírì àti gbogbo ohun tí wọ́n ṣe ní ilé Áhábù,+O sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn.
Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí o di ohun tó ń bani lẹ́rù,Àwọn tó ń gbé ibẹ̀ yóò sì di ohun àrísúfèé;+Àwọn èèyàn yóò sì fi ọ́ ṣẹ̀sín.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?”
^ Tàbí “jíjẹ́ onínúure, kí ìfẹ́ rẹ má sì yẹ̀; adúrótini.” Ní Héb., “fẹ́ràn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”
^ Tàbí “ṣe òdodo; má ṣègbè.”
^ Tàbí “béèrè lọ́wọ́ rẹ.”
^ Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “ọwọ́.”