Náhúmù 2:1-13

  • Nínéfè máa pa run (1-13)

    • “Ilẹ̀kùn àwọn odò rẹ̀ máa ṣí sílẹ̀” (6)

2  Atúniká ti dìde sí ọ.*+ Máa ṣọ́ àwọn ibi olódi. Máa ṣọ́ ọ̀nà. Gbára dì,* kí o sì sa gbogbo agbára rẹ.   Nítorí Jèhófà yóò dá ògo Jékọ́bù pa dà,Yóò dá a pa dà sí ògo Ísírẹ́lì,Nítorí àwọn apanirun ti pa wọ́n run;+Wọ́n sì ti pa àwọn ọ̀mùnú wọn run.   Apata àwọn ọkùnrin rẹ̀ alágbára ti di pupa,Aṣọ àwọn jagunjagun rẹ̀ ti rẹ̀ dòdò. Àwọn irin tí wọ́n dè mọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ń kọ mànà bí ináNí ọjọ́ tó ń múra ogun sílẹ̀,Ó sì ń ju àwọn ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi igi júnípà ṣe fìrìfìrì.   Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń sáré àsápajúdé ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń sáré sókè-sódò ní àwọn ojúde ìlú. Wọ́n ń mọ́lẹ̀ yòò bí iná ògùṣọ̀, wọ́n sì ń kọ mànà bíi mànàmáná.   Ó máa pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀. Wọ́n á kọsẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ. Wọ́n á sáré lọ sí ibi ògiri rẹ̀;Wọ́n á sì gbé ohun ìdènà kalẹ̀.   Ilẹ̀kùn àwọn odò rẹ̀ máa ṣí sílẹ̀,Ààfin rẹ̀ á sì wó lulẹ̀.*   A ti pá a láṣẹ:* Wọ́n ti tú u sí ìhòòhò,Wọ́n gbé e lọ, àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ dárò rẹ̀;Wọ́n ń ké bí àdàbà bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ lu àyà* wọn.   Láti ọjọ́ tí Nínéfè+ ti wà ló ti dà bí adágún omi,Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń sá lọ. “Ẹ dúró! Ẹ dúró!” Àmọ́ kò sí ẹni tó yíjú pa dà.+   Ẹ kó fàdákà, ẹ kó wúrà! Àwọn ìṣúra rẹ̀ kò lópin. Onírúurú ohun iyebíye ló kún inú rẹ̀. 10  Ìlú náà ti ṣófo, ó ti di ahoro, ó sì ti pa run!+ Ìbẹ̀rù ti jẹ́ kí ọkàn wọn domi, orúnkún wọn ń gbọ̀n, gbogbo ara ń ro wọ́n;Gbogbo ojú wọn sì pọ́n. 11  Ibo ni àwọn kìnnìún ń gbé,+ níbi tí àwọn ọmọ kìnnìún* ti ń jẹun,Níbi tí kìnnìún ti ń kó ọmọ rẹ̀ jáde,Tí ẹnì kankan ò sì dẹ́rù bà wọ́n? 12  Kìnnìún ń fa ọ̀pọ̀ ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀Ó sì ń fún ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀. Ó kó ẹran tí ó pa kún inú ihò rẹ̀,Àti èyí tó fà ya kún ibùgbé rẹ̀. 13  “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+“Màá mú kí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ jóná pátápátá,+Idà yóò sì pa àwọn ọmọ kìnnìún* rẹ run. Mi ò ní jẹ́ kí o mú àwọn èèyàn bí ẹran mọ́ ní ayé,A kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn òjíṣẹ́ rẹ mọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, Nínéfè.
Ní Héb., “Fún ìgbáròkó lókun.”
Tàbí “á sì yọ́.”
Tàbí “pinnu rẹ̀.”
Ní Héb., “ọkàn.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”