Náhúmù 3:1-19
3 Ìlú tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé!
Ẹ̀tàn àti ìjanilólè pọ̀ jọjọ nínú rẹ̀.
Kò sígbà tí kì í rí nǹkan mú!
2 Ìró pàṣán ń dún, àgbá kẹ̀kẹ́ sì ń rọ́ gìrìgìrì,Ẹṣin ń bẹ́ lọ, kẹ̀kẹ́ ẹṣin sì ń pariwo.
3 Agẹṣin ń gun ẹṣin, idà ń kọ mànà, ọ̀kọ̀ sì ń dán yinrin,Àwọn tí wọ́n pa sùn lọ bẹẹrẹ, àwọn òkú sì wà ní òkìtì-òkìtì
Àwọn òkú náà kò lóǹkà.
Bí àwọn èèyàn náà ṣe ń rìn lọ, ṣe ni wọ́n ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.
4 Ó jẹ́ nítorí ọ̀pọ̀ ìṣekúṣe aṣẹ́wó náà,Ẹni tó rẹwà, tó sì fani mọ́ra, ìyálóde àwọn oníṣẹ́ àjẹ́,Ẹni tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ̀ mú àwọn orílẹ̀-èdè, tó sì ń fi iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀ mú àwọn ìdílé.
5 “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,+“Màá ká aṣọ rẹ bò ọ́ lójú;Màá jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè rí ìhòòhò rẹ,Àwọn ìjọba á sì rí ìtìjú rẹ.
6 Màá da ẹ̀gbin sí ọ lára
Màá sọ ẹ́ di ohun ìkórìíra;Màá sì jẹ́ kí o di ìran àpéwò.+
7 Gbogbo ẹni tó bá rí ọ máa sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+ á sì sọ pé,‘Nínéfè ti di ahoro!
Ta ló máa bá a kẹ́dùn?’
Ibo ni màá ti rí àwọn olùtùnú fún ọ?
8 Ṣé o sàn ju No-ámónì* lọ,+ tó jókòó sí ẹ̀gbẹ́ ipa odò Náílì?+
Omi ló yí i ká;Òkun ni ọrọ̀ rẹ̀, òkun sì ni ògiri rẹ̀.
9 Etiópíà àti Íjíbítì ló fún un ní agbára tí kò láàlà.
Pútì+ àti àwọn ará Líbíà sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.+
10 Síbẹ̀, ó dèrò ìgbèkùn;Ó sì lọ sí oko ẹrú.+
Wọ́n fọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ náà mọ́lẹ̀ ní gbogbo oríta* ojú ọ̀nà.
Wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé àwọn ọkùnrin rẹ̀ ọlọ́lá,Gbogbo èèyàn pàtàkì inú rẹ̀ ni wọ́n sì ti dè ní ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.
11 Ìwọ náà á mutí yó;+Wàá lọ fara pa mọ́.
Wàá sì wá ibi ààbò lọ́dọ̀ ọ̀tá rẹ.
12 Gbogbo ibi olódi rẹ dà bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tó ní àkọ́pọ́n èso;Tí a bá mì í jìgìjìgì, àwọn èso náà máa já bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13 Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dà bí obìnrin ní àárín rẹ.
Àwọn ẹnubodè ilẹ̀ rẹ á ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ.
Iná á sì jó àwọn ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè rẹ run.
14 Pọn omi sílẹ̀ de ìgbà tí ogun máa ká ọ mọ́!+
Mú kí àwọn ibi olódi rẹ lágbára.
Bọ́ sínú ẹrẹ̀, kí o sì fi ẹsẹ̀ tẹ amọ̀;Di ohun tí wọ́n fi ń yọ bíríkì mú gírígírí.
15 Àní ibẹ̀ ni iná á ti jó ọ run.
Idà yóò gé ọ lulẹ̀.+
Yóò jẹ ọ́ run bí àwọn ọmọ eéṣú ṣe ń jẹ nǹkan run.+
Sọ ara rẹ di púpọ̀ bí àwọn ọmọ eéṣú!
Àní, sọ ara rẹ di púpọ̀ bí àwọn eéṣú!
16 O ti mú kí àwọn oníṣòwò rẹ pọ̀ ju àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ.
Eéṣú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà bọ́ awọ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fò lọ.
17 Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ dà bí eéṣú,Àwọn ọ̀gágun rẹ sì dà bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eéṣú.
Wọ́n sá sínú ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe ní ọjọ́ òtútù,Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn ràn, wọ́n fò lọ;Kò sì sẹ́ni tó mọ ibi tí wọ́n wà.
18 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ ń tòògbé, ìwọ ọba Ásíríà;Àwọn èèyàn pàtàkì rẹ wà ní ibùgbé wọn.
Àwọn èèyàn rẹ ti fọ́n ká sórí àwọn òkè,Kò sì sẹ́ni tó máa kó wọn jọ.+
19 Ìwọ kò ní rí ìtura nínú àjálù rẹ.
Ọgbẹ́ rẹ ti kọjá èyí tó ṣeé wò sàn.
Gbogbo àwọn tó bá gbọ́ ìròyìn nípa rẹ máa pàtẹ́wọ́;+Àbí ta ni kò tíì fara gbá nínú ìwà ìkà tí ò ń hù láìdáwọ́ dúró?”+