Nọ́ńbà 10:1-36

  • Kàkàkí tí wọ́n fi fàdákà ṣe (1-10)

  • Wọ́n kúrò ní Sínáì (11-13)

  • Bí wọ́n ṣe máa tò tẹ̀ léra tí wọ́n bá ń lọ (14-28)

  • Mósè ní kí Hóbábù fi ọ̀nà han Ísírẹ́lì (29-34)

  • Àdúrà Mósè tí wọ́n bá ń tú àgọ́ ká (35, 36)

10  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Ṣe kàkàkí+ méjì fún ara rẹ, fàdákà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí o fi ṣe é. Kí o máa fi pe àwọn èèyàn náà jọ pọ̀, kí o sì máa fi sọ fún wọn pé kí wọ́n tú àgọ́ wọn ká.  Tí wọ́n bá fun kàkàkí méjèèjì, kí gbogbo àpéjọ náà wá sọ́dọ̀ rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+  Tó bá jẹ́ pé kàkàkí kan ni wọ́n fun, àwọn ìjòyè, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì nìkan ni kó pé jọ sọ́dọ̀ rẹ.+  “Tí ẹ bá fi kàkàkí náà fun ìró tó ń lọ sókè sódò, kí àwọn tó pàgọ́ sí apá ìlà oòrùn+ gbéra.  Tí ẹ bá fi kàkàkí náà fun ìró tó ń lọ sókè sódò lẹ́ẹ̀kejì, kí àwọn tó pàgọ́ sí apá gúúsù+ gbéra. Bí wọ́n á ṣe máa fun kàkàkí náà nìyí ní gbogbo ìgbà tí àwùjọ kọ̀ọ̀kan bá fẹ́ gbéra.  “Tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn èèyàn náà jọ, kí ẹ fun àwọn kàkàkí+ náà, àmọ́ kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ìró rẹ̀ lọ sókè sódò.  Àwọn ọmọ Áárónì, àwọn àlùfáà, ni kó máa fun àwọn kàkàkí+ náà. Kí ẹ máa lò ó, kó jẹ́ àṣẹ tó máa wà títí lọ fún yín jálẹ̀ àwọn ìran yín.  “Tí ẹ bá lọ bá ọ̀tá tó ń ni yín lára jagun ní ilẹ̀ yín, ẹ fi àwọn kàkàkí+ náà kéde ogun, Jèhófà Ọlọ́run yín yóò sì rántí yín, yóò gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 10  “Bákan náà, ní àwọn ọjọ́ ayọ̀+ yín, ìyẹn, nígbà àwọn àjọyọ̀+ yín àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù yín, kí ẹ fun àwọn kàkàkí náà sórí àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ yín; wọ́n máa jẹ́ ohun ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run yín. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run+ yín.” 11  Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ọdún kejì,+ ìkùukùu* náà gbéra lórí àgọ́+ Ẹ̀rí. 12  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní aginjù Sínáì, wọ́n tẹ̀ lé ètò tó wà nílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa gbéra,+ ìkùukùu náà sì dúró ní aginjù Páránì.+ 13  Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n gbéra bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 14  Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Júdà ló kọ́kọ́ gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù sì ni olórí àwùjọ náà. 15  Nétánélì+ ọmọ Súárì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákà. 16  Élíábù+ ọmọ Hélónì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Sébúlúnì. 17  Nígbà tí wọ́n tú àgọ́ ìjọsìn palẹ̀,+ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ àti àwọn ọmọ Mérárì+ tí wọ́n ru àgọ́ ìjọsìn náà gbéra. 18  Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì wá gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì sì ni olórí àwùjọ náà. 19  Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì. 20  Élíásáfù+ ọmọ Déúélì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Gádì. 21  Àwọn ọmọ Kóhátì tí wọ́n ru àwọn ohun èlò+ ibi mímọ́ wá gbéra. Wọ́n á ti to àgọ́ ìjọsìn náà tán kí wọ́n tó dé. 22  Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Éfúrémù náà gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù sì ni olórí àwùjọ náà. 23  Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè. 24  Ábídánì+ ọmọ Gídéónì sì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì. 25  Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Dánì wá gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* àwọn ni wọ́n wà lẹ́yìn tí wọ́n ń ṣọ́ gbogbo ibùdó náà. Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì ni olórí àwùjọ náà. 26  Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì. 27  Áhírà+ ọmọ Énánì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfútálì. 28  Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn àwùjọ wọn* ṣe máa ń tò tẹ̀ léra nìyí tí wọ́n bá fẹ́ gbéra.+ 29  Mósè sọ fún Hóbábù ọmọ Réúẹ́lì*+ ọmọ ilẹ̀ Mídíánì, bàbá ìyàwó Mósè pé: “À ń lọ síbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Èmi yóò fún yín.’+ Bá wa lọ,+ a ó sì tọ́jú rẹ dáadáa, torí Jèhófà ti ṣèlérí àwọn ohun rere fún Ísírẹ́lì.”+ 30  Àmọ́ ó fèsì pé: “Mi ò ní bá yín lọ. Mo máa pa dà sí ilẹ̀ mi àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi.” 31  Ni Mósè bá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, má fi wá sílẹ̀, torí o mọ ibi tí a lè pàgọ́ sí nínú aginjù, o sì lè fọ̀nà hàn wá.* 32  Tí o bá sì bá wa lọ,+ ó dájú pé ohun rere èyíkéyìí tí Jèhófà bá ṣe fún wa la máa ṣe fún ọ.” 33  Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní òkè Jèhófà,+ wọ́n rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta, àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà sì ń lọ níwájú wọn ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti wá ibi ìsinmi fún wọn.+ 34  Ìkùukùu+ Jèhófà sì wà lórí wọn ní ọ̀sán nígbà tí wọ́n gbéra ní ibùdó. 35  Nígbàkigbà tí wọ́n bá gbé Àpótí náà, Mósè á sọ pé: “Dìde, Jèhófà,+ jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká, kí àwọn tó kórìíra rẹ sì sá kúrò níwájú rẹ.” 36  Nígbà tí wọ́n bá sì gbé e kalẹ̀, á sọ pé: “Jèhófà, pa dà sọ́dọ̀ àìmọye ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Ísírẹ́lì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ìyẹn, Jẹ́tírò.
Tàbí “ṣe bí ojú fún wa.”
Tàbí “ọ̀kẹ́ àìmọye.”