Nọ́ńbà 12:1-16

  • Míríámù àti Áárónì sọ̀rọ̀ sí Mósè (1-3)

    • Mósè ni oníwà pẹ̀lẹ́ jù (3)

  • Jèhófà gbèjà Mósè (4-8)

  • Ẹ̀tẹ̀ bo Míríámù (9-16)

12  Míríámù àti Áárónì wá ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè torí ọmọ ilẹ̀ Kúṣì tó fi ṣe aya, torí pé ó fẹ́ ọmọbìnrin ará Kúṣì.+  Wọ́n ń sọ pé: “Ṣé ẹnu Mósè nìkan ni Jèhófà gbà sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò gbẹnu tiwa náà sọ̀rọ̀ ni?”+ Jèhófà sì ń fetí sílẹ̀.+  Ọkùnrin náà, Mósè, ló jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ jù lọ nínú gbogbo èèyàn*+ tó wà láyé.  Lójijì, Jèhófà sọ fún Mósè, Áárónì àti Míríámù pé: “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ẹ jáde lọ sí àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì lọ.  Jèhófà wá sọ̀ kalẹ̀ wá nínú ọwọ̀n ìkùukùu,*+ ó dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó sì pe Áárónì àti Míríámù. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú.  Ó wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tẹ́tí kí ẹ gbọ́ mi. Tí wòlíì Jèhófà bá wà láàárín yín, màá jẹ́ kó mọ̀ mí nínú ìran,+ màá sì bá a sọ̀rọ̀ lójú àlá.+  Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè ìránṣẹ́ mi! Ìkáwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ilé+ mi wà.*  Ojúkojú* ni mò ń bá a sọ̀rọ̀,+ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́, kì í ṣe lówelówe; ìrísí Jèhófà ló sì ń rí. Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”  Jèhófà bínú sí wọn gidigidi, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn. 10  Ìkùukùu wá kúrò lórí àgọ́ náà, wò ó! ẹ̀tẹ̀ tó funfun bíi yìnyín+ sì bo Míríámù. Ni Áárónì bá yíjú sọ́dọ̀ Míríámù, ó sì rí i pé ẹ̀tẹ̀+ ti bò ó. 11  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì sọ fún Mósè pé: “Mo bẹ̀ ọ́ olúwa mi! Jọ̀ọ́, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn! Ìwà òmùgọ̀ gbáà la hù yìí. 12  Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ ká fi sílẹ̀ báyìí bí ẹni tó ti kú, tí ìdajì ara rẹ̀ ti jẹrà kí wọ́n tó bí i!” 13  Mósè wá bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà, ó ní: “Ọlọ́run, jọ̀ọ́ mú un lára dá! Jọ̀ọ́!”+ 14  Jèhófà dá Mósè lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ bàbá rẹ̀ ló tutọ́ sí i lójú, ǹjẹ́ ọjọ́ méje kọ́ lojú fi máa tì í? Ẹ lọ sé e mọ́ ẹ̀yìn ibùdó+ fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà, kí ẹ jẹ́ kó wọlé.” 15  Torí náà, wọ́n sé Míríámù mọ́ ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje,+ àwọn èèyàn náà ò sì tú àgọ́ wọn ká títí Míríámù fi pa dà wọlé. 16  Àwọn èèyàn náà wá kúrò ní Hásérótì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pàgọ́ sí aginjù Páránì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ (jẹ́ oníwà tútù) ju gbogbo èèyàn.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “Ó ń fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ilé mi.”
Ní Héb., “Ẹnu ko ẹnu.”