Nọ́ńbà 26:1-65

  • Wọ́n ka àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kejì (1-65)

26  Lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àrùn+ náà kásẹ̀ nílẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì pé:  “Ẹ ka gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ẹni ogún (20) ọdún sókè, ní agbo ilé bàbá kọ̀ọ̀kan, kí ẹ ka gbogbo àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì.”+  Mósè àti àlùfáà Élíásárì+ wá bá wọn sọ̀rọ̀ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù,+ nítòsí Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò+ pé:  “Ẹ kà wọ́n láti ẹni ogún (20) ọdún sókè, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.”+ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì nìyí:  Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Ísírẹ́lì; àwọn ọmọ+ Rúbẹ́nì nìyí: látọ̀dọ̀ Hánókù, ìdílé àwọn ọmọ Hánókù; látọ̀dọ̀ Pálù, ìdílé àwọn ọmọ Pálù;  látọ̀dọ̀ Hésírónì, ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì; látọ̀dọ̀ Kámì, ìdílé àwọn ọmọ Kámì.  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ọgbọ̀n (43,730).+  Ọmọ Pálù ni Élíábù.  Àwọn ọmọ Élíábù ni: Némúẹ́lì, Dátánì àti Ábírámù. Dátánì àti Ábírámù yìí ni wọ́n yàn nínú àpéjọ náà, àwọn ló bá Mósè+ àti Áárónì jà pẹ̀lú àwọn tí Kórà kó jọ+ nígbà tí wọ́n bá Jèhófà+ jà. 10  Ilẹ̀ lanu,* ó sì gbé wọn mì. Ní ti Kórà, òun àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn kú nígbà tí iná jó igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin+ run. Wọ́n wá di àpẹẹrẹ tó jẹ́ ìkìlọ̀.+ 11  Àmọ́, àwọn ọmọ Kórà kò kú.+ 12  Àwọn ọmọ Síméónì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Némúẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Némúẹ́lì; látọ̀dọ̀ Jámínì, ìdílé àwọn ọmọ Jámínì; látọ̀dọ̀ Jákínì, ìdílé àwọn ọmọ Jákínì; 13  látọ̀dọ̀ Síírà, ìdílé àwọn ọmọ Síírà; látọ̀dọ̀ Ṣéọ́lù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣéọ́lù. 14  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Síméónì: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba (22,200).+ 15  Àwọn ọmọ Gádì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Séfónì, ìdílé àwọn ọmọ Séfónì; látọ̀dọ̀ Hágì, ìdílé àwọn ọmọ Hágì; látọ̀dọ̀ Ṣúnì, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúnì; 16  látọ̀dọ̀ Ósínì, ìdílé àwọn ọmọ Ósínì; látọ̀dọ̀ Érì, ìdílé àwọn ọmọ Érì; 17  látọ̀dọ̀ Áródù, ìdílé àwọn ọmọ Áródù; látọ̀dọ̀ Árélì, ìdílé àwọn ọmọ Árélì. 18  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Gádì, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).+ 19  Àwọn ọmọ Júdà+ ni Éérì àti Ónánì.+ Àmọ́ Éérì àti Ónánì kú sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 20  Àwọn ọmọ Júdà nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ṣélà,+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣélà; látọ̀dọ̀ Pérésì,+ ìdílé àwọn ọmọ Pérésì; látọ̀dọ̀ Síírà,+ ìdílé àwọn ọmọ Síírà. 21  Àwọn ọmọ Pérésì nìyí: látọ̀dọ̀ Hésírónì,+ ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì; látọ̀dọ̀ Hámúlù,+ ìdílé àwọn ọmọ Hámúlù. 22  Ìwọ̀nyí ni ìdílé Júdà, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (76,500).+ 23  Àwọn ọmọ Ísákà+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Tólà,+ ìdílé àwọn ọmọ Tólà; látọ̀dọ̀ Púfà, ìdílé àwọn Púnì; 24  látọ̀dọ̀ Jáṣúbù, ìdílé àwọn ọmọ Jáṣúbù; látọ̀dọ̀ Ṣímúrónì, ìdílé àwọn ọmọ Ṣímúrónì. 25  Ìwọ̀nyí ni ìdílé Ísákà, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (64,300).+ 26  Àwọn ọmọ Sébúlúnì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Sérédì, ìdílé àwọn ọmọ Sérédì; látọ̀dọ̀ Élónì, ìdílé àwọn ọmọ Élónì; látọ̀dọ̀ Jálíẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Jálíẹ́lì. 27  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sébúlúnì, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (60,500).+ 28  Àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: Mánásè àti Éfúrémù.+ 29  Àwọn ọmọ Mánásè+ nìyí: látọ̀dọ̀ Mákírù,+ ìdílé àwọn ọmọ Mákírù; Mákírù wá bí Gílíádì;+ látọ̀dọ̀ Gílíádì, ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì. 30  Àwọn ọmọ Gílíádì nìyí: látọ̀dọ̀ Yésérì, ìdílé àwọn ọmọ Yésérì; látọ̀dọ̀ Hélékì, ìdílé àwọn ọmọ Hélékì; 31  látọ̀dọ̀ Ásíríélì, ìdílé àwọn ọmọ Ásíríélì; látọ̀dọ̀ Ṣékémù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣékémù; 32  látọ̀dọ̀ Ṣẹ́mídà, ìdílé àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà; látọ̀dọ̀ Héfà, ìdílé àwọn ọmọ Héfà. 33  Ó ṣẹlẹ̀ pé, Sélóféhádì ọmọ Héfà kò bímọ ọkùnrin, obìnrin+ nìkan ló bí, orúkọ àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì+ ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 34  Ìwọ̀nyí ni ìdílé Mánásè, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (52,700).+ 35  Èyí ni àwọn ọmọ Éfúrémù+ ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ṣútélà, ìdílé àwọn ọmọ Ṣútélà;+ látọ̀dọ̀ Békérì, ìdílé àwọn ọmọ Békérì; látọ̀dọ̀ Táhánì, ìdílé àwọn ọmọ Táhánì. 36  Èyí sì ni àwọn ọmọ Ṣútélà: látọ̀dọ̀ Éránì, ìdílé àwọn ọmọ Éránì. 37  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Éfúrémù, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (32,500).+ Èyí ni àwọn ọmọ Jósẹ́fù ní ìdílé-ìdílé. 38  Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Bélà,+ ìdílé àwọn ọmọ Bélà; látọ̀dọ̀ Áṣíbélì, ìdílé àwọn ọmọ Áṣíbélì; látọ̀dọ̀ Áhírámù, ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù; 39  látọ̀dọ̀ Ṣẹ́fúfámù, ìdílé àwọn ọmọ Súfámù; látọ̀dọ̀ Húfámù, ìdílé àwọn ọmọ Húfámù. 40  Àwọn ọmọ Bélà ni Áádì àti Náámánì:+ látọ̀dọ̀ Áádì, ìdílé àwọn ọmọ Áádì; látọ̀dọ̀ Náámánì, ìdílé àwọn ọmọ Náámánì. 41  Èyí ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (45,600).+ 42  Èyí ni àwọn ọmọ Dánì+ ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ṣúhámù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù. Èyí ni àwọn ìdílé Dánì ní ìdílé-ìdílé. 43  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (64,400).+ 44  Àwọn ọmọ Áṣérì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ímúnà, ìdílé àwọn ọmọ Ímúnà; látọ̀dọ̀ Íṣífì, ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì; látọ̀dọ̀ Bẹráyà, ìdílé àwọn ọmọ Bẹráyà; 45  nínú àwọn ọmọ Bẹráyà: látọ̀dọ̀ Hébà, ìdílé àwọn ọmọ Hébà; látọ̀dọ̀ Málíkíélì, ìdílé àwọn ọmọ Málíkíélì. 46  Orúkọ ọmọbìnrin Áṣérì ni Sírà. 47  Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400).+ 48  Àwọn ọmọ Náfútálì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Jáséélì, ìdílé àwọn ọmọ Jáséélì; látọ̀dọ̀ Gúnì, ìdílé àwọn ọmọ Gúnì; 49  látọ̀dọ̀ Jésérì, ìdílé àwọn ọmọ Jésérì; látọ̀dọ̀ Ṣílẹ́mù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣílẹ́mù. 50  Èyí ni àwọn ìdílé Náfútálì ní ìdílé-ìdílé, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (45,400).+ 51  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méje àti ọgbọ̀n (601,730).+ 52  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: 53  “Kí ẹ pín ilẹ̀ náà bí ogún láàárín àwọn èèyàn yìí bí ẹ ṣe to orúkọ+ wọn.* 54  Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún+ tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Bí iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní àwùjọ kọ̀ọ̀kan bá ṣe pọ̀ tó ni kí ogún wọn ṣe pọ̀ tó. 55  Àmọ́, kèké+ ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà. Orúkọ ẹ̀yà àwọn bàbá wọn ni kí ẹ fi pín ogún fún wọn. 56  Kèké ni kí ẹ fi pinnu bí ẹ ṣe máa pín ogún kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pín in láàárín àwọn àwùjọ tó pọ̀ àtàwọn àwùjọ tó kéré.” 57  Èyí ni àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì+ ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Gẹ́ṣónì, ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì; látọ̀dọ̀ Kóhátì,+ ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì; látọ̀dọ̀ Mérárì, ìdílé àwọn ọmọ Mérárì. 58  Àwọn ìdílé àwọn ọmọ Léfì nìyí: ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,+ ìdílé àwọn ọmọ Hébúrónì,+ ìdílé àwọn ọmọ Máhílì,+ ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,+ ìdílé àwọn ọmọ Kórà. Kóhátì+ bí Ámúrámù.+ 59  Orúkọ ìyàwó Ámúrámù sì ni Jókébédì,+ ọmọ Léfì, tí ìyàwó rẹ̀ bí fún un ní Íjíbítì. Ó wá bí Áárónì àti Mósè àti Míríámù+ arábìnrin wọn fún Ámúrámù. 60  Áárónì bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítámárì.+ 61  Àmọ́ Nádábù àti Ábíhù kú torí wọ́n rú ẹbọ tí kò tọ́ níwájú Jèhófà.+ 62  Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000), gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè.+ Wọn ò forúkọ wọn sílẹ̀ pẹ̀lú ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ torí wọn ò fún wọn ní ogún kankan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 63  Èyí ni àwọn tí Mósè àti àlùfáà Élíásárì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, nítòsí Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò. 64  Àmọ́ ìkankan nínú wọn kò sí lára àwọn tí Mósè àti àlùfáà Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Sínáì.+ 65  Torí Jèhófà ti sọ nípa wọn pé: “Ó dájú pé inú aginjù+ ni wọ́n máa kú sí.” Ẹnikẹ́ni ò ṣẹ́ kù lára wọn àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọ Núnì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “la ẹnu rẹ̀.”
Tàbí “bí iye àwọn orúkọ náà bá ṣe pọ̀ tó.”