Nọ́ńbà 5:1-31

  • Yíya àwọn aláìmọ́ sọ́tọ̀ (1-4)

  • Ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti sísan nǹkan dípò (5-10)

  • Lílo omi láti mọ̀ bóyá ẹnì kan ti ṣe àgbèrè (11-31)

5  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ní kí gbogbo adẹ́tẹ̀+ jáde kúrò nínú ibùdó àti gbogbo ẹni tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ pẹ̀lú gbogbo ẹni tí òkú èèyàn*+ ti sọ di aláìmọ́.  Ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ṣe ni kí ẹ ní kí wọ́n jáde. Kí ẹ ní kí wọ́n lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kí wọ́n má bàa kó èérí bá+ àgọ́ àwọn tí mò ń gbé+ láàárín wọn.”*  Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ní kí àwọn èèyàn náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó. Ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè gẹ́lẹ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá dá èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn ń dá, tó sì hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà, ẹni* náà ti jẹ̀bi.+  Ó* gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́+ ẹ̀ṣẹ̀ tó* dá, kó san ohun tó jẹ̀bi rẹ̀ pa dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀+ kún un; kó fún ẹni tó ṣe àìdáa sí.  Àmọ́ tí ẹni náà ò bá ní mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ ọn tó máa gba ohun tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà san dípò, kó dá a pa dà fún Jèhófà, yóò sì di ti àlùfáà, yàtọ̀ sí àgbò tó máa fi ṣe ètùtù fún un.+  “‘Kí gbogbo ọrẹ mímọ́ + tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ ti àlùfáà.+ 10  Àwọn ohun mímọ́ ti kálukú yóò máa jẹ́ tirẹ̀. Ohun yòówù tí kálukú bá fún àlùfáà yóò di ti àlùfáà.’” 11  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 12  “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí tí ìyàwó ọkùnrin kan bá lọ hùwà tí kò tọ́, tó sì dalẹ̀ ọkọ rẹ̀, 13  tí ọkùnrin míì bá a+ sùn, àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò mọ̀, tí àṣírí rẹ̀ kò tú, tí obìnrin náà sì sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ àmọ́ tí kò sí ẹni tó jẹ́rìí pé ó ṣe é, tí wọn ò sì ká a mọ́: 14  Tí ọkùnrin náà bá ń jowú, tó ń fura pé ìyàwó òun ti dalẹ̀ òun, tí obìnrin náà sì ti sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ tàbí tí ọkùnrin náà ń jowú, tó ń fura pé ìyàwó òun ti dalẹ̀ òun, àmọ́ tí obìnrin náà kò sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, 15  kí ọkùnrin náà mú ìyàwó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ àlùfáà, kó mú ọrẹ dání fún un, ìyẹ̀fun ọkà bálì tó kún ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà.* Kó má da òróró sí i, kó má sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀, torí ọrẹ ọkà owú ni, ọrẹ ọkà tó ń múni rántí ẹ̀bi. 16  “‘Kí àlùfáà mú un wá síwájú, kó sì mú un dúró níwájú Jèhófà.+ 17  Kí àlùfáà bu omi mímọ́ sínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, kí àlùfáà sì bù lára iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ ìjọsìn, kó dà á sínú omi náà. 18  Kí àlùfáà mú kí obìnrin náà dúró níwájú Jèhófà, kó tú irun obìnrin náà, kó sì fi ọrẹ ọkà ìrántí sí àtẹ́lẹwọ́ obìnrin náà, ìyẹn ọrẹ ọkà owú,+ kí omi tó korò tó ń mú ègún+ wá sì wà lọ́wọ́ àlùfáà. 19  “‘Kí àlùfáà wá mú kó búra, kó sọ fún obìnrin náà pé: “Tí ọkùnrin kankan ò bá bá ọ sùn nígbà tí ọkọ rẹ ṣì ní àṣẹ+ lórí rẹ, tí o kò lọ hùwà tí kò tọ́, tí o kò sì di aláìmọ́, kí omi tó korò tó ń mú ègún wá yìí má ṣe ọ́ níbi. 20  Àmọ́ tí o bá ti lọ hùwà tí kò tọ́ nígbà tí ọkọ rẹ ṣì ní àṣẹ lórí rẹ, tí o sì fìyẹn sọ ara rẹ di aláìmọ́, tí o sì ti bá ọkùnrin míì+ tí kì í ṣe ọkọ rẹ sùn—” 21  Kí àlùfáà wá mú kí obìnrin náà búra, kó sì gégùn-ún nínú ìbúra náà, kí àlùfáà sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Jèhófà ṣe ọ́ ní ẹni ègún àti ẹni ìbúra láàárín àwọn èèyàn rẹ, kí Jèhófà mú kí itan* rẹ joro,* kí ikùn rẹ sì wú. 22  Kí omi tó ń mú ègún wá yìí wọnú ìfun rẹ, kó sì mú kí ikùn rẹ wú, kí itan* rẹ sì joro.”* Kí obìnrin náà wá fèsì pé: “Àmín! Àmín!”* 23  “‘Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà kọ àwọn ègún yìí sínú ìwé, kó sì fọ̀ ọ́ sínú omi tó korò náà. 24  Kó wá mú kí obìnrin náà mu omi tó korò tó ń mú ègún wá, omi tó ń mú ègún wá náà yóò wọnú rẹ̀, yóò sì korò. 25  Kí àlùfáà wá gba ọrẹ ọkà owú+ náà lọ́wọ́ obìnrin náà, kó fi ọrẹ ọkà náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà, kó wá gbé e sún mọ́ pẹpẹ. 26  Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ọrẹ ọkà náà láti fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ,+ lẹ́yìn náà, kó mú kí obìnrin náà mu omi náà. 27  Tó bá ti mú kí obìnrin náà mu omi náà, tí obìnrin náà bá ti sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, tó sì ti dalẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi tó ń mú ègún wá náà yóò wọnú rẹ̀, yóò sì korò, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan* rẹ̀ yóò sì joro,* obìnrin náà yóò sì di ẹni ègún láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 28  Àmọ́ tí obìnrin náà kò bá sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin, tó sì mọ́, irú ìyà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ ẹ́, ó máa lè lóyún, á sì lè bímọ. 29  “‘Èyí ni òfin nípa owú,+ tí obìnrin kan bá lọ hùwà tí kò tọ́, tó sì sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nígbà tí ọkọ rẹ̀ ṣì ní àṣẹ lórí rẹ̀, 30  tàbí tí ọkùnrin kan bá ń jowú, tó sì ń fura pé ìyàwó òun ti dalẹ̀ òun; kó mú kí ìyàwó rẹ̀ dúró níwájú Jèhófà, kí àlùfáà sì ṣe gbogbo ohun tí òfin yìí sọ fún obìnrin náà. 31  Ọkùnrin náà ò ní jẹ̀bi, àmọ́ ìyàwó rẹ̀ máa jìyà ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ẹni tí ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “pàgọ́ sáàárín wọn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Wọ́n.”
Tàbí “tí wọ́n.”
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Ó ṣe kedere pé ẹ̀yà ìbímọ ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “tín-ín-rín.” Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé kò ní rọ́mọ bí.
Ó ṣe kedere pé ẹ̀yà ìbímọ ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “tín-ín-rín.” Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé kò ní rọ́mọ bí.
Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kó rí! Bẹ́ẹ̀ ni kó rí!”
Ó ṣe kedere pé ẹ̀yà ìbímọ ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “tín-ín-rín.” Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé kò ní rọ́mọ bí.