Nehemáyà 10:1-39

  • Àwọn èèyàn náà gbà láti máa pa Òfin mọ́ (1-39)

    • ‘A kò ní pa ilé Ọlọ́run wa tì’ (39)

10  Àwọn tó fọwọ́ sí i, tí wọ́n sì gbé èdìdì wọn lé e+ ni: Nehemáyà, tó jẹ́ gómìnà,* ọmọ Hakaláyà Àti Sedekáyà,  Seráyà, Asaráyà, Jeremáyà,  Páṣúrì, Amaráyà, Málíkíjà,  Hátúṣì, Ṣebanáyà, Málúkù,  Hárímù,+ Mérémótì, Ọbadáyà,  Dáníẹ́lì,+ Gínétónì, Bárúkù,  Méṣúlámù, Ábíjà, Míjámínì,  Maasáyà, Bílígáì àti Ṣemáyà; àwọn yìí jẹ́ àlùfáà.  Àwọn ọmọ Léfì tó fọwọ́ sí i ni: Jéṣúà ọmọ Asanáyà, Bínúì látinú àwọn ọmọ Hénádádì, Kádímíélì+ 10  àti arákùnrin wọn Ṣebanáyà, Hodáyà, Kélítà, Pẹláyà, Hánánì, 11  Máíkà, Réhóbù, Haṣabáyà, 12  Sákúrì, Ṣerebáyà,+ Ṣebanáyà, 13  Hodáyà, Bánì àti Bẹnínù. 14  Àwọn olórí àwọn èèyàn náà tó fọwọ́ sí i ni: Páróṣì, Pahati-móábù,+ Élámù, Sátù, Bánì, 15  Búnì, Ásígádì, Bébáì, 16  Ádóníjà, Bígífáì, Ádínì, 17  Átérì, Hẹsikáyà, Ásúrì, 18  Hodáyà, Háṣúmù, Bísáì, 19  Hárífù, Ánátótì, Nébáì, 20  Mágípíáṣì, Méṣúlámù, Hésírì, 21  Meṣesábélì, Sádókù, Jádúà, 22  Pẹlatáyà, Hánánì, Ánáyà, 23  Hóṣéà, Hananáyà, Háṣúbù, 24  Hálóhéṣì, Pílíhà, Ṣóbékì, 25  Réhúmù, Háṣábínà, Maaseáyà, 26  Áhíjà, Hánánì, Ánánì, 27  Málúkù, Hárímù àti Báánà. 28  Ìyókù àwọn èèyàn náà, ìyẹn àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* àti gbogbo àwọn tó ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká kí wọ́n lè pa Òfin Ọlọ́run tòótọ́ mọ́,+ pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn, gbogbo àwọn tó ní ìmọ̀ àti òye,* 29  dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn olókìkí àárín wọn, wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé wọ́n á máa rìn nínú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, èyí tó wá nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ àti pé àwọn á rí i pé àwọn ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Olúwa wa mọ́ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. 30  A kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, a kò sì ní fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.+ 31  Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá kó ọjà tàbí oríṣiríṣi ọkà wá ní ọjọ́ Sábáàtì, a kò ní ra ohunkóhun lọ́wọ́ wọn ní Sábáàtì+ tàbí ní ọjọ́ mímọ́.+ A tún máa fi irè oko wa tó bá jáde ní ọdún keje+ sílẹ̀ àti gbogbo gbèsè tí ẹnikẹ́ni bá jẹ wá.+ 32  Bákan náà, a gbé àṣẹ kan kalẹ̀ fún ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé, a ó máa mú ìdá mẹ́ta ṣékélì* wá lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn ilé* Ọlọ́run wa,+ 33  fún búrẹ́dì onípele,*+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo,+ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ti Sábáàtì+ pẹ̀lú ti òṣùpá tuntun+ àti fún àwọn àsè tí a yàn,+ àwọn ohun mímọ́ àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa. 34  A tún ṣẹ́ kèké lórí bí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn èèyàn náà á ṣe máa mú igi wá sí ilé Ọlọ́run wa, ní agboolé-agboolé àwọn bàbá wa, ní àkókò tí a yàn lọ́dọọdún, láti máa fi dáná lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin.+ 35  A ó tún máa mú àkọ́so èso ilẹ̀ wa àti àkọ́so èso oríṣiríṣi igi wá lọ́dọọdún sí ilé Jèhófà+ 36  àti àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa àti ti ẹran ọ̀sìn wa+ pẹ̀lú àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran wa àti ti agbo ẹran wa bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin. A ó mú wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa, sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run wa.+ 37  Bákan náà, a ó máa mú àkọ́so ọkà tí a kò lọ̀ kúnná+ wá àti àwọn ọrẹ pẹ̀lú èso oríṣiríṣi igi+ àti wáìnì tuntun pẹ̀lú òróró,+ a ó sì kó wọn wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé Ọlọ́run wa,+ a ó sì kó ìdá mẹ́wàá irè oko ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ torí àwọn ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. 38  Kí àlùfáà, ọmọ Áárónì, wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì mú ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá ti ilé Ọlọ́run wa,+ kí wọ́n sì kó o sí àwọn yàrá* tó wà ní ilé ìkẹ́rùsí. 39  Inú àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì máa mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá,+ ibẹ̀ sì ni kí àwọn nǹkan èlò ibi mímọ́ máa wà títí kan àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn akọrin. A kò sì ní pa ilé Ọlọ́run wa tì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.
Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó dàgbà tó láti lóye.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”
Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”
Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”