Nehemáyà 5:1-19

  • Nehemáyà fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ (1-13)

  • Nehemáyà kò mọ tara rẹ̀ nìkan (14-19)

5  Àwọn èèyàn náà àti àwọn ìyàwó wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún nítorí ohun tí àwọn Júù, arákùnrin wọn ń ṣe.+  Àwọn kan ń sọ pé: “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin wa pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀. A gbọ́dọ̀ rí oúnjẹ* tí a máa jẹ, kí a má bàa kú.”  Àwọn míì ń sọ pé: “Àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa pẹ̀lú àwọn ilé wa la fi ṣe ohun ìdúró, ká lè rí ọkà lásìkò tí kò sí oúnjẹ.”  Àwọn míì sì tún ń sọ pé: “A ti fi àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa yá owó ká lè rí ìṣákọ́lẹ̀* ọba san.+  Ara kan náà àti ẹ̀jẹ̀ kan náà ni àwa àti àwọn arákùnrin wa,* bí àwọn ọmọ wọn ṣe rí náà ni àwọn ọmọ wa rí; síbẹ̀ a ní láti sọ àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa di ẹrú, kódà lára àwọn ọmọbìnrin wa ti di ẹrú.+ Àmọ́, a ò ní agbára kankan láti dá èyí dúró, nítorí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa ti di ti àwọn ẹlòmíì.”  Inú bí mi gan-an nígbà tí mo gbọ́ igbe ẹkún wọn àti ọ̀rọ̀ yìí.  Nítorí náà, mo ro gbogbo rẹ̀ lọ́kàn mi, mo sì bá àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn alábòójútó wí, mo sọ fún wọn pé: “Kálukú yín ń gba èlé* lọ́wọ́ arákùnrin rẹ̀.”+ Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣètò àpéjọ ńlá kan nítorí wọn.  Mo sọ fún wọn pé: “A ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí wọ́n tà fún àwọn orílẹ̀-èdè pa dà débi tí agbára wa gbé e dé; àmọ́, ṣé ẹ máa wá ta àwọn arákùnrin yín ni,+ ṣé ó yẹ ká tún rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ yín ni?” Ni kẹ́kẹ́ bá pa mọ́ wọn lẹ́nu, wọn ò sì rí nǹkan kan sọ.  Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe yìí kò dára. Ṣé kò yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run wa+ kí àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn ọ̀tá wa má bàa pẹ̀gàn wa ni? 10  Yàtọ̀ síyẹn, èmi àti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi ń yá wọn ní owó àti ọkà. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ ká jáwọ́ nínú gbígba èlé lórí ohun tí a yáni.+ 11  Ẹ jọ̀ọ́, ẹ dá àwọn nǹkan tí ẹ ti gbà pa dà fún wọn lónìí,+ ìyẹn ilẹ̀ wọn, ọgbà àjàrà wọn, oko ólífì wọn àti ilé wọn, títí kan ìdá ọgọ́rùn-ún* owó, ọkà, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ̀ ń gbà lọ́wọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí èlé.” 12  Wọ́n wá fèsì pé: “A máa dá nǹkan wọ̀nyí pa dà fún wọn, a ò sì ní béèrè ohunkóhun pa dà. A máa ṣe ohun tí o sọ.” Torí náà, mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí wọ́n búra pé wọ́n á mú ìlérí yìí ṣẹ. 13  Mo tún gbọn ibi tó ṣẹ́ po lára aṣọ* mi jáde, mo sì sọ pé: “Ní ọ̀nà yìí, kí Ọlọ́run tòótọ́ gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ìlérí yìí ṣẹ kúrò nínú ilé rẹ̀ àti kúrò nínú ohun ìní rẹ̀, ọ̀nà yìí sì ni kí a gbà gbọ̀n ọ́n dà nù kí ó sì di òfo.” Gbogbo ìjọ fèsì pé: “Àmín!”* Wọ́n yin Jèhófà, àwọn èèyàn náà sì ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí. 14  Bákan náà, láti ọjọ́ tí ọba ti yàn mí láti di gómìnà wọn+ ní ilẹ̀ Júdà, láti ogún ọdún+ sí ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Ọba Atasásítà,+ ó jẹ́ ọdún méjìlá (12), èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ tó yẹ gómìnà.+ 15  Àmọ́, àwọn gómìnà tó wà ṣáájú mi ti di ẹrù tó wúwo sórí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń gba ogójì (40) ṣékélì* fàdákà lọ́wọ́ wọn fún oúnjẹ àti wáìnì lójoojúmọ́. Àwọn ìránṣẹ́ wọn tún ń ni àwọn èèyàn lára. Ṣùgbọ́n mi ò ṣe bẹ́ẹ̀+ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+ 16  Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣe nínú iṣẹ́ ògiri yìí, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi kóra jọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà, a kò sì gba ilẹ̀ kankan.+ 17  Àádọ́jọ (150) Júù àti àwọn alábòójútó ló ń jẹun lórí tábìlì mi, títí kan àwọn tó wá sọ́dọ̀ wa látinú àwọn orílẹ̀-èdè. 18  Lójoojúmọ́, akọ màlúù kan, àgùntàn mẹ́fà tó dáa àti àwọn ẹyẹ* ni wọ́n ń pa fún mi,* a sì máa ń pèsè ọ̀pọ̀ wáìnì lóríṣiríṣi lẹ́ẹ̀kan lọ́jọ́ mẹ́wàá. Síbẹ̀, mi ò béèrè oúnjẹ tó yẹ gómìnà, nítorí pé iṣẹ́ tó wà lọ́rùn àwọn èèyàn náà pọ̀, ó sì ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn. 19  Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí mi sí rere* lórí gbogbo ohun tí mo ti ṣe nítorí àwọn èèyàn yìí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ọkà.”
Tàbí “owó òde.”
Ní Héb., “Bí ara àwọn arákùnrin wa ṣe rí ni tiwa náà rí.”
Tàbí “èlé gọbọi.”
Tàbí “ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún,” ìyẹn, lóṣooṣù.
Ní Héb., “gbọn àyà mi dà nù.”
Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí!”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “adìyẹ.”
Tàbí “ni mò ń fún wọn lówó pé kí wọ́n pa fún mi.”
Tàbí “fún ire.”