Nehemáyà 6:1-19
6 Nígbà tí wọ́n sọ fún Sáńbálátì, Tòbáyà+ àti Géṣémù ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá wa yòókù pé mo ti tún ògiri náà kọ́+ àti pé kò sí àlàfo kankan tó ṣẹ́ kù lára rẹ̀ (bó tilẹ̀ jẹ́ pé títí di àkókò yẹn, mi ò tíì gbé ilẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè),+
2 ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sáńbálátì àti Géṣémù ránṣẹ́ sí mi pé: “Wá, jẹ́ ká dá ìgbà tí a jọ máa pàdé ní àwọn abúlé tó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ónò.”+ Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi.
3 Torí náà, mo rán àwọn òjíṣẹ́ sí wọn pé: “Iṣẹ́ ńlá ni mò ń ṣe, mi ò sì lè wá. Ṣé ó yẹ kí iṣẹ́ náà dúró torí pé mo fi í sílẹ̀ láti wá bá yín?”
4 Wọ́n rán iṣẹ́ kan náà sí mi nígbà mẹ́rin, èsì kan náà ni mo sì ń fún wọn.
5 Ni Sáńbálátì bá tún fi iṣẹ́ kan náà rán ìránṣẹ́ rẹ̀ sí mi nígbà karùn-ún tòun ti lẹ́tà kan tí wọn ò lẹ̀.
6 Wọ́n kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé: “A ti gbọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, Géṣémù+ sì ń sọ ọ́ pé, ìwọ àti àwọn Júù ń gbèrò láti dìtẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí o fi ń mọ ògiri náà; ohun tí wọ́n ń sọ sì fi hàn pé ìwọ lo máa di ọba wọn.
7 Bákan náà, o ti yan àwọn wòlíì láti kéde nípa rẹ káàkiri Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ọba kan wà ní Júdà!’ Wò ó, gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ló máa dé etí ọba. Torí náà, wá, jẹ́ ká jọ sọ ọ̀rọ̀ yìí láàárín ara wa.”
8 Àmọ́, èsì tí mo fi ránṣẹ́ sí i nìyí: “Kò sí ìkankan nínú gbogbo ohun tí o sọ tó ṣẹlẹ̀, ohun tí o gbèrò lọ́kàn ara rẹ lò ń sọ.”
9 Gbogbo wọn ló fẹ́ máa dẹ́rù bà wá, wọ́n ń sọ pé: “Wọ́n á dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà, wọn ò sì ní parí rẹ̀.”+ Ní báyìí, mo gbàdúrà, jọ̀wọ́ fún mi lókun.+
10 Mo wá lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà ọmọ Méhétábélì nígbà tó wà ní àhámọ́ níbẹ̀. Ó sọ fún mi pé: “Jẹ́ ká dá ìgbà tí a jọ máa pàdé ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, nínú tẹ́ńpìlì, ká sì ti àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́. Òru ni wọ́n máa wá pa ọ́.”
11 Àmọ́ mo sọ pé: “Ṣé irú mi ló yẹ kó sá lọ? Ṣé irú mi lè wọnú tẹ́ńpìlì, kí n má sì kú?+ Mi ò ní wọ ibẹ̀!”
12 Ìgbà náà ni mo rí i pé, kì í ṣe Ọlọ́run ló rán an, Tòbáyà àti Sáńbálátì+ ló lọ gbà á pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sí mi.
13 Ńṣe ni wọ́n gbà á kó lè dẹ́rù bà mí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn tí wọ́n á fi bà mí lórúkọ jẹ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.
14 Ọlọ́run mi, rántí Tòbáyà+ àti Sáńbálátì àti ohun tí wọ́n ṣe yìí, tún rántí Noadáyà wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì yòókù tó ń dẹ́rù bà mí nígbà gbogbo.
15 Nítorí náà, ọjọ́ méjìléláàádọ́ta (52) la fi mọ ògiri náà, ó sì parí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì.*
16 Nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá wa gbọ́, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wa ká sì rí i, ìtìjú ńlá* bá wọn,+ wọ́n sì rí i pé Ọlọ́run wa ló ràn wá lọ́wọ́ tí a fi lè parí iṣẹ́ náà.
17 Lákòókò yẹn, àwọn èèyàn pàtàkì+ ní Júdà ń fi ọ̀pọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tòbáyà, Tòbáyà sì ń dá èsì pa dà.
18 Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní Júdà búra pé ẹ̀yìn rẹ̀ làwọn wà, torí pé ó jẹ́ àna Ṣẹkanáyà ọmọ Áráhì,+ Jèhóhánánì ọmọ rẹ̀ sì fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámù+ ọmọ Berekáyà.
19 Bákan náà, ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa lójú mi, wọ́n á sì lọ sọ ohun tí mo bá fi fèsì fún un. Tòbáyà á wá kọ àwọn lẹ́tà sí mi láti fi dẹ́rù bà mí.+