Oníwàásù 10:1-20
10 Bí òkú eṣinṣin ṣe ń ba òróró ẹni tó ń ṣe lọ́fínńdà jẹ́, tí á sì máa rùn, bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń ba ọgbọ́n àti ògo jẹ́.+
2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí ó tọ́,* àmọ́ ọkàn òmùgọ̀ máa ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí kò tọ́.*+
3 Ibikíbi tí òmùgọ̀ bá rìn sí, kò ní lo làákàyè,*+ ó sì máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé òmùgọ̀ ni òun.+
4 Tí inú* alákòóso bá ru sí ọ, má ṣe kúrò níbi tí o wà,+ torí pé ìwà pẹ̀lẹ́ ń pẹ̀tù sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.+
5 Ohun kan wà tó ń kó ìdààmú báni tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run,* àṣìṣe tí àwọn tí agbára wà lọ́wọ́ wọn ń ṣe:+
6 Àwọn òmùgọ̀ ló ń wà ní ọ̀pọ̀ ipò gíga, àmọ́ àwọn tó dáńgájíá* kì í kúrò ní ipò tó rẹlẹ̀.
7 Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àmọ́ tí àwọn olórí ń fẹsẹ̀ rìn bí ìránṣẹ́.+
8 Ẹni tó ń gbẹ́ kòtò lè já sínú rẹ̀;+ ẹni tó sì ń wó ògiri olókùúta, ejò lè bù ú ṣán.
9 Ẹni tó ń gbẹ́ òkúta, òkúta náà lè ṣe é léṣe, ẹni tó sì ń la gẹdú, gẹdú náà lè ṣe é ní jàǹbá.*
10 Tí irinṣẹ́ kan kò bá mú, tí ẹni tó fẹ́ lò ó kò sì pọ́n ọn, ó máa ní láti lo agbára tó pọ̀ gan-an. Àmọ́ ọgbọ́n ń mú kéèyàn ṣe àṣeyọrí.
11 Tí ejò bá buni ṣán kí wọ́n tó tù ú lójú, kí làǹfààní atujú tó gbówọ́.*
12 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n ń mú ire wá,+ àmọ́ ètè òmùgọ̀ ń fa ìparun rẹ̀.+
13 Ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ jáde lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀,+ èyí tó sì sọ gbẹ̀yìn jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè tó ń ṣekú pani.
14 Síbẹ̀, ńṣe ni òmùgọ̀ á máa sọ̀rọ̀ lọ.+
Èèyàn ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀; ta ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un?+
15 Iṣẹ́ àṣekára òmùgọ̀ ń tán an lókun, torí kò tiẹ̀ mọ bó ṣe máa rí ọ̀nà tó máa gbà lọ sínú ìlú.
16 Ẹ wo bó ṣe máa burú tó fún ilẹ̀ kan tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọdékùnrin,+ tí àwọn ìjòyè rẹ̀ sì máa ń bẹ̀rẹ̀ àsè wọn ní àárọ̀!
17 Ẹ wo bó ṣe máa jẹ́ ohun ayọ̀ tó fún ilẹ̀ náà, tí ọba rẹ̀ bá jẹ́ ọmọ èèyàn pàtàkì, tí àwọn ìjòyè rẹ̀ sì ń jẹun ní àkókò tí ó tọ́ kí wọ́n lè lágbára, kì í ṣe kí wọ́n lè mutí yó!+
18 Ìwà ọ̀lẹ tó lé kenkà ló ń mú kí igi àjà tẹ̀, ọwọ́ tó dilẹ̀ sì ló ń mú kí ilé jò.+
19 Oúnjẹ* wà fún ẹ̀rín, wáìnì sì ń mú kí èèyàn gbádùn ayé;+ àmọ́ owó la fi ń ṣe ohun gbogbo tí a nílò.+
20 Kódà nínú èrò rẹ,* má ṣe bú* ọba,+ má sì bú olówó nínú yàrá rẹ; torí pé ẹyẹ kan* lè gbé ọ̀rọ̀* náà tàbí kí ohun tó ní ìyẹ́ tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.”
^ Ní Héb., “wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.”
^ Ní Héb., “ọkàn á kù fún un.”
^ Ní Héb., “ẹ̀mí; èémí.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Tàbí “àwọn ọlọ́rọ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “yẹ kó ṣọ́ra pẹ̀lú rẹ̀.”
^ Ní Héb., “ẹni tó láṣẹ ní ahọ́n.”
^ Ní Héb., “Búrẹ́dì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “lórí ibùsùn rẹ.”
^ Tàbí “ṣépè fún.”
^ Ní Héb., “ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run.”
^ Tàbí “iṣẹ́.”