Oníwàásù 3:1-22

  • Ohun gbogbo ni àkókò wà fún (1-8)

  • Ká gbádùn ayé, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni (9-15)

    • Ayérayé wà ní ọkàn èèyàn (11)

  • Òdodo ni Ọlọ́run fi ń ṣe ìdájọ́ gbogbo èèyàn (16, 17)

  • Bí èèyàn ṣe ń kú náà ni ẹranko ń kú (18-22)

    • Gbogbo wọn á pa dà sí erùpẹ̀ (20)

3  Ohun gbogbo ni àkókò wà fún,Àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́ lábẹ́ ọ̀run:   Ìgbà bíbímọ àti ìgbà kíkú;Ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn tu;   Ìgbà pípa àti ìgbà wíwòsàn;Ìgbà wíwólulẹ̀ àti ìgbà kíkọ́;   Ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín;Ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà jíjó;*   Ìgbà jíju òkúta sọ nù àti ìgbà kíkó òkúta jọ;Ìgbà gbígbánimọ́ra àti ìgbà téèyàn ò ní gbáni mọ́ra;   Ìgbà wíwá àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọ nù;Ìgbà fífi pa mọ́ àti ìgbà jíjù sọ nù;   Ìgbà fífàya+ àti ìgbà ríránpọ̀;Ìgbà dídákẹ́+ àti ìgbà sísọ̀rọ̀;+   Ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra;+ Ìgbà ogun àti ìgbà àlàáfíà.  Kí ni èrè tí òṣìṣẹ́ rí jẹ látinú gbogbo ìsapá rẹ̀?+ 10  Mo ti rí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún ọmọ aráyé láti mú kí ọwọ́ wọn dí. 11  Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 12  Mo ti wá rí i pé kò sí ohun tó dáa fún wọn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ayé wọn,+ 13  àti pé kí kálukú máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.+ 14  Mo ti wá mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe máa wà títí láé. Kò sí nǹkan kan tí a máa fi kún un, kò sì sí nǹkan kan tí a máa yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe é bẹ́ẹ̀ kí àwọn èèyàn lè máa bẹ̀rù rẹ̀.+ 15  Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí, ohun tó sì ń bọ̀ ti wà tẹ́lẹ̀;+ àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ń wá ohun tí a ti lépa.* 16  Mo tún ti rí i lábẹ́ ọ̀run* pé: Ìwà burúkú ti rọ́pò ìdájọ́ òdodo, ìwà burúkú sì ti rọ́pò òdodo.+ 17  Torí náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ẹni burúkú,+ nítorí àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́ àti gbogbo akitiyan.” 18  Mo tún sọ nípa àwọn ọmọ aráyé lọ́kàn mi pé Ọlọ́run tòótọ́ máa dán wọn wò, á sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé bí ẹranko ni wọ́n rí, 19  nítorí pé ohun* kan wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn, ohun kan sì wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko; ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ Bí ọ̀kan ṣe ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní.+ Torí náà, èèyàn kò lọ́lá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni ohun gbogbo. 20  Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ.+ Inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá,+ inú erùpẹ̀ sì ni gbogbo wọn ń pa dà sí.+ 21  Ta ló mọ̀ bóyá ẹ̀mí èèyàn ń lọ sí òkè tàbí ẹ̀mí ẹranko ń lọ sí ilẹ̀?+ 22  Mo sì rí i pé kò sí ohun tó dáa fún èèyàn ju pé kó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀,+ nítorí ìyẹn ni èrè* rẹ̀; torí ta ló lè mú kó rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti lọ?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “fífò sókè; títa pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.”
Tàbí “létòlétò; lọ́nà tó yẹ; lọ́nà tó bá a mu.”
Tàbí kó jẹ́, “ohun tó ti kọjá lọ.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “àtúbọ̀tán.”
Tàbí “ìpín.”