Oníwàásù 4:1-16
4 Mo tún fiyè sí gbogbo ìwà ìnilára tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.* Mo rí omijé àwọn tí wọ́n ń ni lára, kò sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú.+ Agbára wà lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára, kò sì sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú.
2 Mo bá àwọn tó ti kú yọ̀ dípò àwọn tó ṣì wà láàyè.+
3 Ẹni tó sàn ju àwọn méjèèjì lọ ni ẹni tí wọn ò tíì bí,+ tí kò tíì rí ohun tó ń kó ìdààmú báni tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+
4 Mo ti rí bí ìdíje+ ṣe ń mú kí àwọn èèyàn máa sapá,* kí wọ́n sì máa fòye ṣiṣẹ́; asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*
5 Òmùgọ̀ ká ọwọ́ gbera, bẹ́ẹ̀ ló ń rù sí i.*+
6 Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.*+
7 Mo fiyè sí àpẹẹrẹ ohun míì tó jẹ́ asán lábẹ́ ọ̀run:*
8 Ọkùnrin kan wà tó dá wà, kò ní ẹnì kejì; kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ará, àmọ́ iṣẹ́ àṣekára tó ń ṣe kò lópin. Ojú rẹ̀ kò kúrò nínú kíkó ọrọ̀ jọ.+ Àmọ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bi ara rẹ̀ pé, ‘Ta ni mò ń tìtorí rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára tí mo sì ń fi àwọn ohun rere du ara mi’?+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ó sì jẹ́ iṣẹ́ tó ń tánni lókun.+
9 Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ,+ nítorí pé wọ́n ní èrè* fún iṣẹ́ àṣekára wọn.
10 Torí tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé e* dìde. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó ṣubú tí kò sí ẹni tó máa gbé e dìde?
11 Bákan náà, tí àwọn méjì bá dùbúlẹ̀ pa pọ̀, ara wọn á móoru, àmọ́ báwo ni ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè móoru?
12 Ẹnì kan lè borí ẹni tó dá wà, àmọ́ àwọn méjì tó wà pa pọ̀ lè kojú rẹ̀. Okùn onífọ́nrán mẹ́ta kò ṣeé tètè* fà já.
13 Ọmọdé tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n sàn ju àgbàlagbà ọba tó jẹ́ òmùgọ̀,+ tí làákàyè rẹ̀ kò tó láti gba ìkìlọ̀ mọ́.+
14 Nítorí inú ẹ̀wọ̀n ló* ti jáde lọ di ọba,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà tí ẹni yẹn ń ṣàkóso lọ́wọ́ ni wọ́n bí i ní aláìní.+
15 Mo kíyè sí gbogbo àwọn alààyè tó ń rìn káàkiri lábẹ́ ọ̀run,* mo tún kíyè sí bí nǹkan ṣe rí fún ọmọ tó wá gba ipò ọba náà.
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ń tì í lẹ́yìn kò lóǹkà, inú àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn kò ní dùn sí i.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Tàbí “ṣiṣẹ́ kára.”
^ Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
^ Ní Héb., “ó ń jẹ ẹran ara rẹ̀.”
^ Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Tàbí “èrè púpọ̀.”
^ Ìyẹn, alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.
^ Tàbí “kò rọrùn láti.”
^ Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ọlọ́gbọ́n ọmọ náà.
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”