Orin Sólómọ́nì 3:1-11

  • Ọ̀dọ́bìnrin (1-5)

    • ‘Ní òru, mo wá ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́’ (1)

  • Àwọn ọmọbìnrin Síónì (6-11)

    • Sólómọ́nì àti àwọn tó ń tẹ̀ lé e

3  “Lórí ibùsùn mi ní òru,Mo wá ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́.*+ Mo wá a, àmọ́ mi ò rí i.+   Màá dìde, màá sì lọ káàkiri inú ìlú;Kí n lè wá ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́,*Ní ojú ọ̀nà àti ní àwọn ojúde ìlú. Mo wá a, àmọ́ mi ò rí i.   Àwọn tó ń ṣọ́ ìlú rí mi nígbà tí wọ́n ń lọ yí ká.+ Mo bi wọ́n pé, ‘Ṣé ẹ bá mi rí olólùfẹ́ mi?’*   Bí mo ṣe ní kí n kúrò lọ́dọ̀ wọn báyìíNi mo rí olólùfẹ́ mi.* Mo rọ̀ mọ́ ọn, mi ò sì jẹ́ kó lọ,Títí mo fi mú un wá sínú ilé ìyá mi,+Sínú yàrá ẹni tó lóyún mi.   Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù,Kí ẹ fi àwọn egbin àti àwọn abo àgbọ̀nrín inú pápá búra: Pé kí ẹ má ṣe ta ìfẹ́ jí, ẹ má sì ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí á fi wá fúnra rẹ̀.”+   “Kí ló ń jáde látinú aginjù yìí, tó ń rú túú bí èéfín,Tí òjíá àti tùràrí ń ta sánsán lára rẹ̀,Pẹ̀lú gbogbo àtíkè oníṣòwò tó ń ta sánsán?”+   “Wò ó! Ìtẹ́ Sólómọ́nì ni. Ọgọ́ta (60) alágbára ọkùnrin ló yí i ká,Lára àwọn alágbára ọkùnrin ní Ísírẹ́lì,+   Gbogbo wọn ló ní idà,Gbogbo wọn kọ́ṣẹ́ ogun jíjà,Kálukú fi idà rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ Torí ewu ní òru.”   “Ìtẹ́* Ọba Sólómọ́nì ni,Tó fi igi Lẹ́bánónì+ ṣe fún ara rẹ̀. 10  Fàdákà ló fi ṣe àwọn òpó rẹ̀,Wúrà ló fi gbé e ró. Òwú aláwọ̀ pọ́pù ló fi ṣe ìjókòó rẹ̀;Àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mùṢe inú rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ tìfẹ́tìfẹ́.” 11  “Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbìnrin Síónì,Kí ẹ lọ wo Ọba Sólómọ́nìTó dé adé ọkọ ìyàwó* tí ìyá rẹ̀+ ṣe fún unNí ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,Ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ ń dùn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.”
Àga tí wọ́n fi nǹkan bò lórí, tí wọ́n fi ń gbé èèyàn pàtàkì.
Tàbí “adé tí wọ́n fi òdòdó hun.”