Orin Sólómọ́nì 4:1-16

  • Olùṣọ́ àgùntàn (1-5)

    • “O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi” (1)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (6)

  • Olùṣọ́ àgùntàn (7-16a)

    • ‘O ti gbà mí lọ́kàn, ìyàwó mi’ (9)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (16b)

4  “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi. Wò ó! O rẹwà gan-an. Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà, lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú. Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́Tí wọ́n ń rọ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè Gílíádì.+   Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,Gbogbo wọn bí ìbejì,Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.   Ètè rẹ rí bí òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétìLábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.   Ọrùn rẹ+ dà bí ilé gogoro Dáfídì,+Tí wọ́n fi òkúta kọ́,Tí wọ́n gbé ẹgbẹ̀rún apata kọ́ sí ara rẹ̀,Gbogbo apata* tó jẹ́ ti àwọn ọkùnrin alágbára.+   Ọmú rẹ méjèèjì dà bí ọmọ àgbọ̀nrín méjì,Ó dà bí ọmọ egbin+ tí wọ́n jẹ́ ìbejì,Tí wọ́n ń jẹko láàárín àwọn òdòdó lílì.”   “Màá lọ sórí òkè òjíá,Màá gba ọ̀nà òkè tùràrí lọ,+Títí afẹ́fẹ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́,* tí òjìji kò sì ní sí mọ́.”   “O rẹwà látòkè délẹ̀, olólùfẹ́ mi,+Kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ.   Jẹ́ ká jọ máa bọ̀ láti Lẹ́bánónì, ìyàwó mi,Jẹ́ ká jọ máa bọ̀ láti Lẹ́bánónì.+ Sọ̀ kalẹ̀ láti téńté òkè Ámánà,*Láti téńté òkè Sénírì, téńté òkè Hámónì,+Látinú ihò kìnnìún, látorí àwọn òkè tí àwọn àmọ̀tẹ́kùn ń gbé.   O ti gbà mí lọ́kàn,+ arábìnrin mi, ìyàwó mi,Bí o ṣe ṣíjú wò mí báyìí, tí mo rí ọ̀kan nínú ẹ̀gbà ọrùn rẹ,Bẹ́ẹ̀ lo gbà mí lọ́kàn. 10  Arábìnrin mi, ìyàwó mi, ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi mà dára o!+ Ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi dára ju wáìnì lọ,+Kò sì sí lọ́fínńdà tó ń ta sánsán bíi tìrẹ!+ 11  Oyin inú afárá+ ń kán tótó ní ètè rẹ, ìyàwó mi. Oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,+Aṣọ rẹ sì ń ta sánsán bíi ti Lẹ́bánónì. 12  Arábìnrin mi, ìyàwó mi, dà bí ọgbà tí wọ́n tì,Ọgbà tí wọ́n tì, orísun omi tí wọ́n sé pa. 13  Àwọn ẹ̀ka* rẹ dà bí ọgbà pómégíránétì,* Tó ní àwọn èso tó dára jù, àwọn ewé làálì pẹ̀lú ewé sípíkénádì, 14  Sípíkénádì+ àti òdòdó sáfúrónì, pòròpórò*+ àti igi sínámónì,+Pẹ̀lú oríṣiríṣi igi tùràrí, òjíá àti álóè+Àti gbogbo lọ́fínńdà tó dára jù.+ 15  Orísun omi inú ọgbà ni ọ́, kànga omi tó mọ́Àti odò tó ń ṣàn láti Lẹ́bánónì.+ 16  Jí, ìwọ atẹ́gùn àríwá;Wọlé wá, ìwọ atẹ́gùn gúúsù. Fẹ́* sórí ọgbà mi. Jẹ́ kí ìtasánsán rẹ̀ gbalẹ̀ kan.” “Jẹ́ kí olólùfẹ́ mi wá sínú ọgbà rẹ̀ Kó sì jẹ àwọn èso rẹ̀ tó dára jù lọ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ẹ̀bátí.”
Tàbí “apata ribiti.”
Ní Héb., “Títí ọjọ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í mí.”
Tàbí “Òkè Lẹ́bánónì Kejì.”
Tàbí kó jẹ́, “Awọ.”
Tàbí “párádísè pómégíránétì.”
Esùsú tó ń ta sánsán.
Tàbí “Fẹ́ yẹ́ẹ́.”