Orin Sólómọ́nì 5:1-16

  • Olùṣọ́ àgùntàn (1a)

  • Àwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù (1b)

    • ‘Ẹ mu ìfẹ́ yó!’

  • Ọ̀dọ́bìnrin (2-8)

    • Ó sọ àlá rẹ̀

  • Àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù (9)

    • ‘Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn míì lọ?’

  • Ọ̀dọ́bìnrin (10-16)

    • “Kò sí ẹni tí a lè fi í wé láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin” (10)

5  “Mo ti wọnú ọgbà mi,+Ìwọ arábìnrin mi, ìyàwó mi. Mo ti já òjíá mi àti ewéko olóòórùn dídùn mi.+ Mo ti jẹ afárá oyin mi àti oyin mi;Mo ti mu wáìnì mi àti wàrà mi.”+ “Ẹ jẹun, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n! Ẹ mu ìfẹ́,+ kí ẹ sì yó!”   “Mo ti sùn lọ, àmọ́ ọkàn mi ò sùn.+ Mo gbọ́ ìró olólùfẹ́ mi tó ń kan ilẹ̀kùn!” “Ṣílẹ̀kùn fún mi, arábìnrin mi, olólùfẹ́ mi,Àdàbà mi, ẹni tí ẹwà rẹ̀ ò lábùlà! Torí ìrì ti sẹ̀ sí mi lórí,Ìrì òru+ ti mú kí irun mi tutù.”   “‘Mo ti bọ́ aṣọ mi. Ṣé kí n tún wọ̀ ọ́ pa dà ni? Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi. Ṣé kí n tún jẹ́ kó dọ̀tí ni?’   Olólùfẹ́ mi mú ọwọ́ kúrò lára ihò ilẹ̀kùn,Ọkàn mi sì túbọ̀ fà sí i.   Mo dìde kí n lè ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi;Òjíá ń kán tótó ní ọwọ́ mi,Òjíá olómi ń kán ní àwọn ìka mi,Sára ọwọ́ ilẹ̀kùn.   Mo ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi,Àmọ́ olólùfẹ́ mi ti pa dà, ó ti lọ. Àfi bíi pé kò sí ìrètí fún mi* nígbà tó lọ.* Mo wá a, ṣùgbọ́n mi ò rí i.+ Mo pè é, àmọ́ kò dá mi lóhùn.   Àwọn tó ń ṣọ́ ìlú rí mi nígbà tí wọ́n ń lọ yí ká. Wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe. Àwọn tó ń ṣọ́ ògiri ṣí ìborùn* mi kúrò lára mi.   Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù: Tí ẹ bá rí olólùfẹ́ mi,Kí ẹ sọ fún un pé òjòjò ìfẹ́ ń ṣe mí.”   “Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn olólùfẹ́ míì lọ,Ìwọ tó rẹwà jù nínú àwọn obìnrin? Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn olólùfẹ́ míì lọ,Tí o fi mú ká ṣe irú ìbúra yìí?” 10  “Olólùfẹ́ mi rẹwà, ó sì mọ́ra;Kò sí ẹni tí a lè fi í wé láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin. 11  Wúrà ni orí rẹ̀, wúrà tó dára jù. Irun orí rẹ̀ dà bí imọ̀ ọ̀pẹ tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́,* Ó dúdú bí ẹyẹ ìwò. 12  Ojú rẹ̀ dà bí àwọn àdàbà tó wà létí odò,Tí wọ́n ń wẹ̀ nínú wàrà,Tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó kún.* 13  Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dà bí ebè tí wọ́n gbin ewé tó ń ta sánsán sí,+Òkìtì ewéko tó ń ta sánsán. Ètè rẹ̀ dà bí òdòdó lílì, òjíá olómi+ sì ń kán tótó ní ètè rẹ̀. 14  Ọwọ́ rẹ̀ dà bí òpó wúrà, tí wọ́n fi kírísóláítì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Ikùn rẹ̀ dà bí eyín erin tó ń dán, tí wọ́n fi òkúta sàfáyà bò. 15  Ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta mábù ṣe, tó ní ìtẹ́lẹ̀ wúrà tó dára jù. Ó rí bíi Lẹ́bánónì, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bí àwọn igi kédárì.+ 16  Ẹnu* rẹ̀ gangan ni adùn,Kò sóhun tí kò wuni nípa rẹ̀.+ Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, olólùfẹ́ mi nìyí, òun lẹni tí mo nífẹ̀ẹ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú nígbà tó sọ̀rọ̀.”
Tàbí “Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú.”
Tàbí “aṣọ ìbòjú.”
Tàbí kó jẹ́, “dà bí òṣùṣù èso déètì.”
Tàbí kó jẹ́, “létí orísun omi.”
Ní Héb., “Òkè ẹnu.”