Orin Sólómọ́nì 6:1-13

  • Àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù (1)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (2, 3)

    • “Olólùfẹ́ mi ló ni mí, èmi ni mo sì ni olólùfẹ́ mi” (3)

  • Ọba (4-10)

    • “O rẹwà bíi Tírísà” (4)

    • Ohun tí àwọn obìnrin sọ (10)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (11, 12)

  • Ọba (àti àwọn míì) (13a)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (13b)

  • Ọba (àti àwọn míì) (13d)

6  “Ibo ni olólùfẹ́ rẹ lọ,Ìwọ tó rẹwà jù nínú àwọn obìnrin? Ibo ni olólùfẹ́ rẹ gbà? Jẹ́ ká jọ wá a lọ.”   “Olólùfẹ́ mi ti lọ sí ọgbà rẹ̀,Síbi ebè tí wọ́n gbin àwọn ewé tó ń ta sánsán sí,Kó lè tọ́jú àwọn àgùntàn nínú ọgbà,Kó sì já àwọn òdòdó lílì.+   Olólùfẹ́ mi ló ni mí,Èmi ni mo sì ni olólùfẹ́ mi.+ Ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn láàárín àwọn òdòdó lílì.”+   “Olólùfẹ́ mi,+ o rẹwà bíi Tírísà,*+ O wuni bíi Jerúsálẹ́mù,+ O gbayì gan-an bí àwọn ọmọ ogun tó yí ọ̀págun wọn ká.+   Yí ojú rẹ+ kúrò lọ́dọ̀ mi,Torí ara mi ò gbà á. Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́ Tó ń rọ́ bọ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Gílíádì.+   Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn,Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,Gbogbo wọn bí ìbejì,Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.   Àwọn ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.   Ọgọ́ta (60) ayaba lè wà,Ọgọ́rin (80) wáhàrì* lè wà,Ọ̀dọ́bìnrin sì lè pọ̀ láìníye.+   Àmọ́ ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi,+ onítèmi tí ẹwà rẹ̀ ò lábùlà. Ọ̀kan ṣoṣo tí ìyá rẹ̀ ní. Òun ni ààyò* ẹni tó bí i. Àwọn ọmọbìnrin rí i, wọ́n sì ń pè é ní aláyọ̀;Àwọn ayaba àti wáhàrì rí i, wọ́n sì ń yìn ín. 10  ‘Ta ni obìnrin yìí tó ń tàn* bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,Tó lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú,Tó mọ́ rekete bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn,Tó gbayì gan-an bí àwọn ọmọ ogun tó yí ọ̀págun wọn ká?’”+ 11  “Mo lọ sínú ọgbà igi eléso,+Kí n lè rí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù ní àfonífojì,Kí n lè rí i bóyá àjàrà ti hù,* Bóyá àwọn igi pómégíránétì ti yọ òdòdó. 12  Kí n tó mọ̀,Ohun tó wù mí* ti mú kí n déIbi tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn èèyàn mi pàtàkì* wà.” 13  “Pa dà wá, pa dà wá, Ṣúlámáítì! Pa dà wá, pa dà wá,Ká lè máa wò ẹ́!” “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wo Ṣúlámáítì?”+ “Ó dà bí ijó àwùjọ méjì!”*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ìlú Tó Wuni.”
Tàbí “ẹ̀bátí.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “ẹni mímọ́.”
Ní Héb., “tó ń sọ̀ kalẹ̀.”
Tàbí “yọ ìtànná.”
Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn.”
Tàbí “ijó Máhánáímù.”