Sí Àwọn Ará Róòmù 12:1-21
12 Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín+ fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, tó jẹ́ mímọ́,+ tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, kí ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ pẹ̀lú agbára ìrònú yín.+
2 Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí* máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà,+ kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí+ ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.
3 Torí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ,+ àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fún kálukú ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́.*+
4 Nítorí bí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara ṣe wà nínú ara kan,+ àmọ́ tí gbogbo ẹ̀yà ara kì í ṣe iṣẹ́ kan náà,
5 bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí a tiẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a jẹ́ ẹ̀yà ara fún ẹnì kejì wa.+
6 Nígbà tí a sì ti ní àwọn ẹ̀bùn tó yàtọ̀ síra nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún wa,+ tó bá jẹ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ ni, ẹ jẹ́ ká máa sọ tẹ́lẹ̀ bí ìgbàgbọ́ wa ṣe tó;
7 tó bá jẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni, ẹ jẹ́ kí a wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí; tàbí ẹni tó ń kọ́ni, kó wà lẹ́nu kíkọ́ni rẹ̀;+
8 tàbí ẹni tó ń fúnni níṣìírí,* kó máa fúnni níṣìírí;*+ ẹni tó ń pín nǹkan fúnni,* kó máa ṣe é tinútinú;+ ẹni tó ń ṣe àbójútó,* kó máa ṣe é kárakára;*+ ẹni tó ń ṣàánú, kó máa fi ọ̀yàyà ṣe é.+
9 Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí ẹ̀tàn.*+ Ẹ kórìíra ohun búburú;+ ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.
10 Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín. Nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.*+
11 Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára,* ẹ má ṣọ̀lẹ.*+ Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.+ Ẹ máa ṣẹrú fún Jèhófà.*+
12 Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀. Ẹ máa fara da ìpọ́njú.+ Ẹ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.+
13 Ẹ máa ṣàjọpín nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò.+ Ẹ máa ṣe aájò àlejò.+
14 Ẹ máa súre fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni;+ ẹ máa súre, ẹ má sì máa ṣépè.+
15 Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.
16 Bí ẹ ṣe ń ṣe sí ara yín ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹlòmíì; ẹ má ṣe máa ronú nípa àwọn ohun ńláńlá,* àmọ́ ẹ máa ronú nípa àwọn ohun tó rẹlẹ̀.+ Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.+
17 Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.+ Ẹ jẹ́ kí ìrònú yín dá lé ohun tó dára lójú gbogbo èèyàn.
18 Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.+
19 Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú;*+ nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san, ni Jèhófà* wí.”+
20 Àmọ́ “tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní nǹkan mu; torí bí o ṣe ń ṣe èyí, wàá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí.”*+
21 Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, àmọ́ máa fi ire ṣẹ́gun ibi.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “yan ìgbàgbọ́ fún kálukú; pín ìgbàgbọ́ fún kálukú.”
^ Tàbí “lójú méjèèjì.”
^ Tàbí “mú ipò iwájú.”
^ Tàbí “fúnni ní nǹkan.”
^ Tàbí “gbani níyànjú.”
^ Tàbí “gbani níyànjú.”
^ Tàbí “àgàbàgebè.”
^ Tàbí “ẹ máa lo ìdánúṣe.”
^ Tàbí “Ẹ jẹ́ aláápọn; Ẹ jẹ́ onítara.”
^ Tàbí “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yín.”
^ Tàbí “ní èrò gíga.”
^ Ìyẹn, ìrunú Ọlọ́run.
^ Ìyẹn, láti mú kí ọkàn ẹni náà rọ̀, kí inú rẹ̀ sì yọ́.