Sí Àwọn Ará Róòmù 16:1-27
16 Mo fẹ́ kí ẹ mọ* Fébè arábìnrin wa, tó jẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ tó wà ní Kẹnkíríà,+
2 kí ẹ lè tẹ́wọ́ gbà á nínú Olúwa lọ́nà tó yẹ àwọn ẹni mímọ́, kí ẹ sì ràn án lọ́wọ́ nínú ohun tó bá nílò,+ torí òun fúnra rẹ̀ ti gbèjà ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan èmi náà.
3 Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà,+ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi Jésù,
4 àwọn tí wọ́n fi ẹ̀mí* ara wọn wewu nítorí mi,*+ kì í ṣe èmi nìkan ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pátá náà ń dúpẹ́.
5 Bákan náà, ẹ kí ìjọ tó wà ní ilé wọn.+ Ẹ kí Épénétù àyànfẹ́ mi, tó jẹ́ àkọ́so ní Éṣíà fún Kristi.
6 Ẹ kí Màríà, tó ti ṣiṣẹ́ kára fún yín.
7 Ẹ kí Andironíkọ́sì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi,+ tí a jọ ṣẹ̀wọ̀n, àwọn tí àwọn àpọ́sítélì mọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ti pẹ́ jù mí lọ nínú Kristi.
8 Ẹ bá mi kí Áńpílíátù, àyànfẹ́ mi nínú Olúwa.
9 Ẹ kí Úbánọ́sì, tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi àti Sítákísì àyànfẹ́ mi.
10 Ẹ kí Ápélésì, ẹni ìtẹ́wọ́gbà nínú Kristi. Ẹ kí àwọn tó wà ní agbo ilé Àrísítóbúlù.
11 Ẹ kí Hẹ́ródíónì, ìbátan mi. Ẹ kí àwọn tó wà nínú Olúwa ní agbo ilé Nákísọ́sì.
12 Ẹ kí Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa. Ẹ kí Pésísì, àyànfẹ́ wa, torí ó ti ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa.
13 Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì àyànfẹ́ nínú Olúwa àti ìyá rẹ̀, tó tún jẹ́ ìyá mi.
14 Ẹ kí Asinkirítọ́sì, Fílégónì, Hẹ́mísì, Pátíróbásì, Hẹ́másì àti àwọn ará tó wà pẹ̀lú wọn.
15 Ẹ kí Fílólógọ́sì àti Júlíà, Néréúsì àti arábìnrin rẹ̀ àti Òlíńpásì pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ tó wà pẹ̀lú wọn.
16 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo àwọn ìjọ Kristi kí yín.
17 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣọ́ àwọn tó ń fa ìyapa àti ìkọ̀sẹ̀ tó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, kí ẹ sì yẹra fún wọn.+
18 Nítorí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹrú Olúwa wa Kristi, bí kò ṣe ti ohun tí wọ́n fẹ́ jẹ,* wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ dídùn àti ọ̀rọ̀ ìpọ́nni fa ọkàn àwọn tí kò fura mọ́ra.
19 Gbogbo èèyàn ti gbọ́ nípa ìgbọràn yín, torí náà, inú mi ń dùn nítorí yín. Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti ohun rere, ṣùgbọ́n aláìmọ̀kan ní ti ohun búburú.+
20 Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà máa mú kí ẹsẹ̀ yín tẹ Sátánì rẹ́+ láìpẹ́. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù wà pẹ̀lú yín.
21 Tímótì, tí a jọ ń ṣiṣẹ́, kí yín, Lúkíọ́sì àti Jásónì pẹ̀lú Sósípátérì, àwọn ìbátan mi+ náà kí yín.
22 Èmi, Tẹ́tíọ́sì, tí mo kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.
23 Gáyọ́sì,+ tó gba èmi àti gbogbo ìjọ lálejò, kí yín. Érásítù, ẹni tó ń bójú tó ìṣúra ìlú,* kí yín, Kúátọ́sì, arákùnrin rẹ̀ náà kí yín.
24 * ——
25 Ní báyìí, Ẹni tó lè fìdí yín múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere tí mò ń kéde àti ìwàásù Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìfihàn àṣírí mímọ́+ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ látọjọ́ pípẹ́,
26 àmọ́ tí a ti fi hàn kedere* ní báyìí, ti a sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ alásọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa pé ká fi ìgbàgbọ́ gbé ìgbọràn ga;
27 Ọlọ́run, ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,+ ni kí ògo nípasẹ̀ Jésù Kristi jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Mo dámọ̀ràn.”
^ Ní Grk., “ọrùn.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ti ikùn wọn.”
^ Tàbí “ẹni tó jẹ́ ìríjú ìlú.”
^ Tàbí “tí a ṣí payá.”