Sí Àwọn Ará Róòmù 3:1-31

  • “Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́” (1-8)

  • Àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ (9-20)

  • Òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (21-31)

    • Gbogbo èèyàn kò kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run (23)

3  Kí wá làǹfààní àwọn Júù tàbí kí làǹfààní ìdádọ̀dọ́?*  Ó pọ̀ gan-an ní gbogbo ọ̀nà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìkáwọ́ wọn la fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ Ọlọ́run sí.+  Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ tí àwọn kan ò bá ní ìgbàgbọ́? Ṣé àìnígbàgbọ́ wọn máa mú kí àwọn èèyàn má gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ mọ́ ni?  Ká má ri! Àmọ́ kí Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́,+ kódà bí gbogbo èèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ òpùrọ́,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Kí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ lè fi ọ́ hàn ní olódodo, kí o sì lè jàre ẹjọ́ rẹ.”+  Àmọ́, kí ni ká sọ bí àìṣòdodo wa bá gbé òdodo Ọlọ́run yọ? Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣẹ̀tọ́ nígbà tó bá tú ìrunú rẹ̀ jáde, àbí? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí èèyàn ni o.)  Ká má ri! Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣèdájọ́ ayé?+  Àmọ́ tó bá jẹ́ pé torí irọ́ mi ni òtítọ́ Ọlọ́run fi túbọ̀ fara hàn láti gbé ògo rẹ̀ yọ, kí ló dé tí a tún fi ń ṣèdájọ́ mi bí ẹlẹ́ṣẹ̀?  A ò ṣe kúkú wá sọ bí àwọn kan ṣe ń parọ́ mọ́ wa tí wọ́n ní a sọ pé, “Ẹ jẹ́ ká ṣe àwọn ohun búburú kí àwọn ohun rere lè jáde wá”? Ìdájọ́ àwọn èèyàn yìí bá ìdájọ́ òdodo mu.+  Kí wá ni? Ṣé a sàn jù wọ́n lọ ni? Rárá o! Torí a ti sọ ọ́ níṣàájú pé gbogbo àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;+ 10  bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Kò sí olódodo kankan, kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan;+ 11  kò sí ẹnì kankan tó ní ìjìnlẹ̀ òye; kò sí ẹni tó ń wá Ọlọ́run. 12  Gbogbo èèyàn ti fi ọ̀nà sílẹ̀, gbogbo wọn ti di aláìníláárí; kò sí ẹnì kankan tó ń ṣoore, kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.”+ 13  “Sàréè tó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn, wọ́n ti fi ahọ́n wọn tanni jẹ.”+ “Oró paramọ́lẹ̀* wà lábẹ́ ètè wọn.”+ 14  “Ègún àti ọ̀rọ̀ kíkorò ló kún ẹnu wọn.”+ 15  “Ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”+ 16  “Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn, 17  wọn kò sì mọ ọ̀nà àlàáfíà.”+ 18  “Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lójú wọn.”+ 19  A mọ̀ pé gbogbo nǹkan tí Òfin sọ ló wà fún àwọn tó wà lábẹ́ Òfin, kí a lè pa gbogbo èèyàn lẹ́nu mọ́, kí gbogbo ayé sì lè yẹ fún ìyà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ 20  Nítorí náà, kò sí ẹni* tí a máa pè ní olódodo níwájú rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin,+ torí òfin ló jẹ́ ká ní ìmọ̀ pípéye nípa ẹ̀ṣẹ̀.+ 21  Àmọ́ ní báyìí, láìgbára lé òfin, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn,+ bí Òfin àti àwọn Wòlíì ṣe jẹ́rìí sí i,+ 22  bẹ́ẹ̀ ni, òdodo Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tó wà fún gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́. Nítorí kò sí ìyàtọ̀.+ 23  Torí gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀, wọn ò sì kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,+ 24  bí a ṣe pè wọ́n ní olódodo dà bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ tí wọ́n rí gbà nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ èyí tó wá nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ tí ìràpadà tí Kristi Jésù san mú kó ṣeé ṣe.+ 25  Ọlọ́run fi í lélẹ̀ láti jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn, torí Ọlọ́run, nínú ìmúmọ́ra* rẹ̀, ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nígbà àtijọ́ jini. 26  Èyí jẹ́ láti fi òdodo rẹ̀+ hàn ní àsìkò yìí, kí ó lè jẹ́ olódodo kódà nígbà tó bá ń pe èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù ní olódodo.+ 27  Kí ló wá fa ìyangàn? Kò sáyè fún ìyẹn. Nípasẹ̀ òfin wo? Ṣé ti iṣẹ́ ni?+ Rárá o, àmọ́ nípasẹ̀ òfin ìgbàgbọ́. 28  Nítorí a gbà pé ìgbàgbọ́ ló ń mú kí a pe èèyàn kan ní olódodo kì í ṣe àwọn iṣẹ́ òfin.+ 29  Àbí ṣé Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ni?+ Ṣé kì í ṣe Ọlọ́run àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú?+ Bẹ́ẹ̀ ni, òun náà ni Ọlọ́run àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.+ 30  Nítorí ọ̀kan ni Ọlọ́run,+ ó máa pe àwọn tó dádọ̀dọ́* ní olódodo  + nítorí ìgbàgbọ́, á sì pe àwọn aláìdádọ̀dọ́* ní olódodo  + nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn. 31  Ṣé a wá pa òfin rẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa ni? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la fìdí òfin múlẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìkọlà?”
Tàbí “ejò gùǹte.”
Ní Grk., “ẹran ara.”
Tàbí “ètùtù; ìpadàrẹ́.”
Tàbí “ìpamọ́ra.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”