Sí Àwọn Ará Róòmù 8:1-39
8 Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi kankan fún àwọn tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù.
2 Nítorí òfin ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè nínú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀+ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.
3 Ohun tí Òfin kò lè ṣe+ torí pé ẹran ara kò jẹ́ kó lágbára+ ni Ọlọ́run ṣe bó ṣe rán Ọmọ rẹ̀+ jáde bí èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dá ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi,
4 kí ohun òdodo tí Òfin béèrè lè ṣẹ nínú àwa+ tí à ń rìn nípa tẹ̀mí,+ kì í ṣe nípa tara.
5 Nítorí àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tara máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tara,+ àmọ́ àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tẹ̀mí máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí.+
6 Nítorí ríronú nípa àwọn nǹkan tara ń yọrí sí ikú,+ àmọ́ ríronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà;+
7 torí pé ríronú nípa àwọn nǹkan tara ń sọni di ọ̀tá Ọlọ́run,+ nítorí kò sí lábẹ́ òfin Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni, kò lè sí níbẹ̀.
8 Torí náà, àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tara kò lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
9 Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, á jẹ́ pé ìgbé ayé tẹ̀mí lẹ̀ ń gbé,+ kì í ṣe tara. Àmọ́ tí ẹnì kan ò bá ní ẹ̀mí Kristi, ẹni náà kì í ṣe tirẹ̀.
10 Ṣùgbọ́n tí Kristi bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín,+ ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ń mú ìyè wá nítorí òdodo.
11 Ní báyìí, tí ẹ̀mí ẹni tó gbé Jésù dìde kúrò nínú ikú bá ń gbé inú yín, ẹni tó gbé Kristi Jésù dìde kúrò nínú ikú+ pẹ̀lú yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tó ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè.+
12 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a wà lábẹ́ ọ̀ranyàn, àmọ́ kì í ṣe láti máa gbé ìgbé ayé tara, ká lè máa ṣe ìfẹ́ tara;+
13 torí ó dájú pé ẹ máa kú, tí ẹ bá ń gbé ìgbé ayé tara; àmọ́ tí ẹ bá fi ẹ̀mí lu àwọn iṣẹ́ tara pa,+ ẹ ó yè.+
14 Nítorí gbogbo àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí ni ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́.+
15 Torí kì í ṣe ẹ̀mí ìsìnrú tó ń múni pa dà sínú ìbẹ̀rù lẹ gbà, ẹ̀mí ìsọdọmọ lẹ gbà, ẹ̀mí tó ń mú ká ké jáde pé: “Ábà,* Bàbá!”+
16 Ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa + pé ọmọ Ọlọ́run ni wá.+
17 Nígbà náà, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú, lóòótọ́ a jẹ́ ajogún Ọlọ́run, àmọ́ a jẹ́ ajùmọ̀jogún+ pẹ̀lú Kristi, kìkì tí a bá jọ jìyà,+ kí a lè ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.+
18 Nítorí mo gbà pé àwọn ìyà àsìkò yìí kò já mọ́ nǹkan kan tí a bá fi wé ògo tí a máa fi hàn nínú wa.+
19 Torí ìṣẹ̀dá ń dúró de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run+ lójú méjèèjì.
20 Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún asán,+ kì í ṣe nípa ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, àmọ́ nípasẹ̀ ẹni tó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí,
21 kí a lè dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀+ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́, kí ó sì lè ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.
22 Nítorí a mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora títí di báyìí.
23 Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àmọ́ àwa fúnra wa pẹ̀lú tí a ní àkọ́so, ìyẹn, ẹ̀mí náà, bẹ́ẹ̀ ni, àwa fúnra wa ń kérora nínú ara wa,+ bí a ṣe ń dúró de ìsọdọmọ+ lójú méjèèjì, ìyẹn ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ara wa nípasẹ̀ ìràpadà.
24 Nítorí a gbà wá là nínú ìrètí yìí; àmọ́ ìrètí tí èèyàn bá ti rí kì í ṣe ìrètí mọ́, torí tí èèyàn bá ti rí nǹkan, ṣé á tún máa retí rẹ̀ ni?
25 Ṣùgbọ́n tí a bá ń retí+ ohun tí a kò rí,+ a ó máa fi ìfaradà dúró dè é+ lójú méjèèjì.
26 Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ nínú àìlera wa;+ torí ìṣòro ibẹ̀ ni pé a ò mọ ohun tó yẹ ká fi sínú àdúrà bó ṣe yẹ ká ṣe, àmọ́ ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń bá wa bẹ̀bẹ̀ nígbà tí a wà nínú ìrora inú lọ́hùn-ún.*
27 Ẹni tó ń wá inú ọkàn+ mọ ohun tí ẹ̀mí ń sọ, nítorí ó ń bá àwọn ẹni mímọ́ bẹ̀bẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.
28 A mọ̀ pé Ọlọ́run ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe máa ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ire àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí a pè nítorí ìfẹ́ rẹ̀;+
29 nítorí àwọn tó kọ́kọ́ fún ní àfiyèsí ló tún yàn ṣáájú láti jẹ́ àwòrán Ọmọ rẹ̀,+ kó lè jẹ́ àkọ́bí+ láàárín ọ̀pọ̀ arákùnrin.+
30 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó yàn ṣáájú+ ni àwọn tó pè;+ àwọn tó pè ni àwọn tó kéde ní olódodo.+ Níkẹyìn, àwọn tó kéde ní olódodo ni àwọn tó ṣe lógo.+
31 Kí ni ká wá sọ sọ́rọ̀ yìí? Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?+
32 Bí kò ṣe dá Ọmọ rẹ̀ pàápàá sí, àmọ́ tó fi í lélẹ̀ nítorí gbogbo wa,+ ṣé kò wá ní fi gbogbo ohun mìíràn kún Ọmọ rẹ̀ fún wa nítorí inú rere rẹ̀ ni?
33 Ta ló máa fẹ̀sùn kan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run? + Ọlọ́run ni Ẹni tó pè wọ́n ní olódodo.+
34 Ta ló máa dá wọn lẹ́bi? Kristi Jésù ló kú, bẹ́ẹ̀ ni, yàtọ̀ síyẹn, òun la gbé dìde, tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ tó sì ń bá wa bẹ̀bẹ̀.+
35 Ta ló máa yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? + Ṣé ìpọ́njú ni àbí wàhálà àbí inúnibíni àbí ebi àbí ìhòòhò àbí ewu àbí idà?+
36 Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Torí rẹ ni wọ́n ṣe ń pa wá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀; wọ́n ti kà wá sí àgùntàn tó wà fún pípa.”+
37 Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú gbogbo àwọn nǹkan yìí, à ń ja àjàṣẹ́gun+ nípasẹ̀ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa.
38 Torí ó dá mi lójú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ tàbí àwọn agbára+
39 tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.