Sáàmù 1:1-6

  • Ọ̀nà méjì tó yàtọ̀ síra

    • Kíka òfin Ọlọ́run ń fúnni láyọ̀ (2)

    • Àwọn olódodo dà bí igi eléso (3)

    • Àwọn èèyàn burúkú dà bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ (4)

1  Aláyọ̀ ni ẹni tí kì í tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn èèyàn burúkúTí kì í dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀+Tí kì í sì í jókòó lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́gàn.+   Ṣùgbọ́n òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn,+Ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka* òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.+   Ó máa dà bí igi tí a gbìn sétí odò,Tó ń so èso ní àsìkò rẹ̀,Tí ewé rẹ̀ kì í sì í rọ. Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.+   Àwọn èèyàn burúkú kò rí bẹ́ẹ̀;Wọ́n dà bí ìyàngbò* tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ.   Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn burúkú kò fi ní lè dúró nígbà ìdájọ́;+Tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò sì ní lè dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.+   Nítorí Jèhófà mọ ọ̀nà àwọn olódodo,+Àmọ́ ọ̀nà àwọn èèyàn burúkú máa ṣègbé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ṣe àṣàrò lórí.”
Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.