Sáàmù 107:1-43
(Sáàmù 107-150)
107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+
2 Kí àwọn tí Jèhófà gbà* pa dà sọ bẹ́ẹ̀,Àwọn tó gbà pa dà lọ́wọ́* ọ̀tá,+
3 Àwọn tó kó jọ láti àwọn ilẹ̀,+Láti ìlà oòrùn àti láti ìwọ̀ oòrùn,*Láti àríwá àti láti gúúsù.+
4 Wọ́n rìn kiri ní aginjù, ní aṣálẹ̀;Wọn ò rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.
5 Ebi pa wọ́n, òùngbẹ sì gbẹ wọ́n;Àárẹ̀ mú wọn* torí wọn ò lókun mọ́.
6 Wọ́n ń ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.+
7 Ó mú wọn gba ọ̀nà tí ó tọ́+Kí wọ́n lè dé ìlú tí wọ́n á lè máa gbé.+
8 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà+ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+
9 Nítorí ó mú kí àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ mu àmutẹ́rùn,Ó sì mú kí àwọn* tí ebi ń pa jẹ ohun rere ní àjẹtẹ́rùn.+
10 Àwọn kan ń gbé inú òkùnkùn biribiri,Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ìyà ń jẹ, tí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sì wà lọ́wọ́ wọn.
11 Nítorí wọ́n ta ko ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;Wọn ò ka ìmọ̀ràn Ẹni Gíga Jù Lọ sí.+
12 Torí náà, ó fi ìnira rẹ ọkàn wọn sílẹ̀;+Wọ́n kọsẹ̀, kò sì sí ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Wọ́n ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn,Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.
14 Ó mú wọn jáde nínú òkùnkùn biribiri,Ó sì fa ìdè wọn já.+
15 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀+Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.
16 Nítorí ó ti fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà,Ó sì ti gé àwọn ọ̀pá ìdábùú onírin.+
17 Wọ́n ya òmùgọ̀, wọ́n sì jìyà+Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àṣìṣe wọn.+
18 Oúnjẹ kankan ò lọ lẹ́nu wọn;*Wọ́n sún mọ́ àwọn ẹnubodè ikú.
19 Wọ́n á ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn;Á sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.
20 Á fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn, á mú wọn lára dá,+Á sì yọ wọ́n nínú kòtò tí wọ́n há sí.
21 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.
22 Kí wọ́n rú ẹbọ ọpẹ́,+Kí wọ́n sì máa fi igbe ayọ̀ kéde àwọn iṣẹ́ rẹ̀.
23 Àwọn tó ń fi ọkọ̀ rìnrìn àjò lórí òkun,Tí wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,+
24 Wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ JèhófàÀti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ nínú ibú;+
25 Bó ṣe fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kí ìjì máa jà,+Tó sì ń ru ìgbì òkun sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run;Wọ́n já wálẹ̀ ṣòòròṣò sínú ibú.
Ọkàn wọn domi nítorí àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.
27 Wọ́n ń rìn tàgétàgé, wọ́n sì ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ọ̀mùtí,Gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ní já sí pàbó.+
28 Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.
29 Ó mú kí ìjì náà rọlẹ̀,Ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́.+
30 Inú wọn dùn nígbà tí gbogbo rẹ̀ pa rọ́rọ́,Ó sì ṣamọ̀nà wọn dé èbúté tí wọ́n fẹ́.
31 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+
32 Kí wọ́n máa gbé e ga nínú ìjọ àwọn èèyàn,+Kí wọ́n sì máa yìn ín nínú ìgbìmọ̀* àwọn àgbààgbà.
33 Ó ń sọ àwọn odò di aṣálẹ̀,Ó sì ń sọ ìṣàn omi di ilẹ̀ tó gbẹ táútáú,+
34 Ó ń sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀,+Nítorí ìwà burúkú àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.
35 Ó ń sọ aṣálẹ̀ di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Ó sì ń sọ ilẹ̀ gbígbẹ di ìṣàn omi.+
36 Ó ń mú kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,+Kí wọ́n lè tẹ ìlú dó láti máa gbé.+
37 Wọ́n dáko, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà+Tí irè oko rẹ̀ pọ̀ dáadáa.+
38 Ó bù kún wọn, wọ́n sì pọ̀ gidigidi;Kò jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn pẹ̀dín.+
39 Àmọ́ wọ́n tún dín kù, ẹ̀tẹ́ sì bá wọnNítorí ìnilára, àjálù àti ẹ̀dùn ọkàn.
40 Ó rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,Ó sì mú kí wọ́n rìn kiri ní ilẹ̀ tó ti di ahoro, tí kò sì lójú ọ̀nà.+
41 Àmọ́ ó dáàbò bo àwọn aláìní* lọ́wọ́ ìnilára,+Ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.
42 Àwọn adúróṣinṣin rí èyí, wọ́n sì yọ̀;+Àmọ́ gbogbo àwọn aláìṣòdodo pa ẹnu wọn mọ́.+
43 Ẹni tó bá gbọ́n yóò kíyè sí àwọn nǹkan yìí,+Yóò sì fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “rà.”
^ Tàbí “gbà kúrò ní ìkáwọ́.”
^ Tàbí “Láti yíyọ oòrùn àti láti wíwọ̀ oòrùn.”
^ Tàbí “ọkàn wọn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “Ọkàn wọn kọ gbogbo oúnjẹ.”
^ Ní Héb., “ní ìjókòó.”
^ Ìyẹn, koríko etí omi.
^ Tàbí “ó gbé àwọn aláìní ga,” ìyẹn, kí ọwọ́ má bàa tó wọn.