Sáàmù 11:1-7
Sí olùdarí. Ti Dáfídì.
11 Jèhófà ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.+
Torí náà, ẹ ṣe lè sọ fún mi* pé:
“Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ!
2 Wo bí àwọn ẹni burúkú ṣe tẹ ọrun;Wọ́n fi ọfà wọn sára okùn ọrun,*Kí wọ́n lè ta á látinú òkùnkùn lu àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.
3 Nígbà tí ìpìlẹ̀* bá bà jẹ́,Kí ni olódodo lè ṣe?”
4 Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+
Ìtẹ́ Jèhófà wà ní ọ̀run.+
Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ tó rí ohun gbogbo* ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ èèyàn.+
5 Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú;+Ó* kórìíra ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.+
6 Yóò dẹ ọ̀pọ̀ pańpẹ́ fún* àwọn ẹni burúkú;Iná, imí ọjọ́+ àti ẹ̀fúùfù gbígbóná ni yóò wà nínú ife wọn.
7 Nítorí olódodo ni Jèhófà;+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo.+
Àwọn adúróṣinṣin yóò rí ojú* rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọṣán.”
^ Tàbí “ìpìlẹ̀ ìdájọ́ òdodo.”
^ Tàbí “tó ń tàn yanran.”
^ Tàbí “Ọkàn rẹ̀; Òun alára.”
^ Tàbí kó jẹ́, “rọ̀jò ẹyin iná sórí.”
^ Tàbí “ojú rere.”