Sáàmù 113:1-9

  • Ọlọ́run lókè máa ń gbé aláìní dìde

    • Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí láé (2)

    • Ọlọ́run máa ń tẹ̀ ba (6)

113  Ẹ yin Jáà!* Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,Ẹ yin orúkọ Jèhófà.   Kí á máa yin orúkọ JèhófàLáti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.+   Láti yíyọ oòrùn títí dé wíwọ̀ rẹ̀,Kí á máa yin orúkọ Jèhófà.+   Jèhófà ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+Ògo rẹ̀ ga ju ọ̀run lọ.+   Ta ló dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa,+Ẹni tó ń gbé* ibi gíga?   Ó tẹ̀ ba láti wo ọ̀run àti ayé,+   Ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku. Ó ń gbé tálákà dìde látorí eérú*+   Kí ó lè mú un jókòó pẹ̀lú àwọn èèyàn pàtàkì,Àwọn ẹni pàtàkì nínú àwọn èèyàn rẹ̀.   Ó ń fún àgàn ní iléKí ó lè di abiyamọ aláyọ̀, ìyá àwọn ọmọ.*+ Ẹ yin Jáà!*

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “tó gúnwà sí.”
Tàbí kó jẹ́, “ààtàn.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.