Sáàmù 114:1-8
114 Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì,+Tí ilé Jékọ́bù jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè àjèjì,
2 Júdà di ibi mímọ́ rẹ̀,Ísírẹ́lì di ibi tó ń ṣàkóso lé lórí.+
3 Òkun rí i, ó sì sá lọ;+Odò Jọ́dánì yíjú pa dà.+
4 Àwọn òkè ńlá ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,+Àwọn òkè kéékèèké ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn.
5 Kí ló lé ọ léré, ìwọ òkun?+
Kí ló dé tí o fi yíjú pa dà, ìwọ Jọ́dánì?+
6 Kí ló dé tí ẹ̀yin òkè ńlá fi ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,Tí ẹ̀yin òkè kéékèèké sì ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn?
7 Máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí Olúwa, ìwọ ayé,Nítorí Ọlọ́run Jékọ́bù,+
8 Ẹni tó ń sọ àpáta di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Tó ń sọ akọ àpáta di ìsun omi.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, koríko etí omi.