Sáàmù 119:1-176
-
Mọrírì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeyebíye
א [Áléfì]
119 Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlẹ́bi* ní ọ̀nà wọn,Àwọn tó ń rìn nínú òfin Jèhófà.+
2 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ̀,+Àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá a.+
3 Wọn kì í hùwà àìṣòdodo;Wọ́n ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.+
4 O ti pàṣẹ péKí a máa pa òfin rẹ mọ́ délẹ̀délẹ̀.+
5 Ká ní mo lè máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó*+Kí n lè máa pa àwọn ìlànà rẹ mọ́!
6 Nígbà náà, ojú ò ní tì mí+Tí mo bá ń ronú nípa gbogbo àṣẹ rẹ.
7 Màá fi ọkàn tó dúró ṣinṣin yìn ọ́Nígbà tí mo bá kọ́ nípa àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo.
8 Màá pa àwọn ìlànà rẹ mọ́.
Má fi mí sílẹ̀ pátápátá.
ב [Bétì]
9 Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Tó bá ń kíyè sára, tó sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+
10 Gbogbo ọkàn mi ni mo fi wá ọ.
Má ṣe jẹ́ kí n yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+
11 Mo fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ìṣúra nínú ọkàn mi+Kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.+
12 Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà;Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.
13 Mo fi ètè mi kédeGbogbo àwọn ìdájọ́ tí o ti ṣe.
14 Àwọn ìránnilétí rẹ ń mú inú mi dùn+Ju gbogbo àwọn ohun míì tó ṣeyebíye.+
15 Màá máa ronú lórí* àwọn àṣẹ rẹ,+Màá sì máa fojú sí àwọn ọ̀nà rẹ.+
16 Mo fẹ́ràn àwọn òfin rẹ.
Mi ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.+
ג [Gímélì]
17 Ṣe dáadáa sí èmi ìránṣẹ́ rẹ,Kí n lè wà láàyè, kí n sì máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+
18 La ojú mi kí n lè ríÀwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú òfin rẹ kedere.
19 Àjèjì lásán ni mí lórí ilẹ̀ yìí.+
Má fi àwọn àṣẹ rẹ pa mọ́ fún mi.
20 Ìfẹ́ àwọn ìdájọ́ rẹGbà mí lọ́kàn nígbà gbogbo.
21 O bá àwọn tó ń kọjá àyè wọn wí,Àwọn ẹni ègún tó ń yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,*Nítorí pé mo ti kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ.
23 Kódà nígbà tí àwọn olórí bá jọ jókòó, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ mi láìdáa,Àwọn ìlànà rẹ ni èmi ìránṣẹ́ rẹ ń ronú lé lórí.*
24 Mo fẹ́ràn àwọn ìránnilétí rẹ;+Àwọn ló ń gbà mí nímọ̀ràn.+
ד [Dálétì]
25 Mo* dùbúlẹ̀ nínú eruku.+
Mú kí n máa wà láàyè bí o ṣe sọ.+
26 Mo sọ àwọn ọ̀nà mi fún ọ, o sì dá mi lóhùn;Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+
27 Jẹ́ kí n mọ ìtumọ̀* àwọn àṣẹ rẹ,Kí n lè máa ronú lórí* àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+
28 Ẹ̀dùn ọkàn ò jẹ́ kí n* rí oorun sùn.
Fún mi lókun bí o ṣe sọ.
29 Mú ọ̀nà ẹ̀tàn kúrò lọ́dọ̀ mi,+Kí o sì fi òfin rẹ ṣojú rere sí mi.
30 Mo ti yan ọ̀nà òdodo.+
Mo gbà pé àwọn ìdájọ́ rẹ tọ̀nà.
31 Mo rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí rẹ.+
Jèhófà, má ṣe jẹ́ kí n rí ìjákulẹ̀.*+
32 Màá yára rìn ní* ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,Torí pé o ti wá àyè fún un nínú ọkàn mi.*
ה [Híì]
33 Jèhófà,+ kọ́ mi kí n lè máa tè lé àwọn ìlànà rẹ,Màá sì tẹ̀ lé e délẹ̀délẹ̀.+
34 Jẹ́ kí n ní òye,Kí n lè máa tẹ̀ lé òfin rẹ,Kí n sì máa fi gbogbo ọkàn mi pa á mọ́.
35 Darí mi* ní ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,+Torí ó ń mú inú mi dùn.
36 Mú kí ọkàn mi máa fà sí àwọn ìránnilétí rẹ,Kó má ṣe fà sí èrè tí kò tọ́.*+
37 Yí ojú mi kúrò kí n má ṣe máa wo ohun tí kò ní láárí;+Mú kí n máa wà láàyè ní ọ̀nà rẹ.
38 Mú ìlérí tí o ṣe* fún ìránṣẹ́ rẹ ṣẹ,Ká lè máa bẹ̀rù rẹ.*
39 Mú ìtìjú tí mò ń bẹ̀rù kúrò,Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ dára.+
40 Wo bí ọkàn mi ṣe ń fà sí àwọn àṣẹ rẹ.
Mú kí n máa wà láàyè nínú òdodo rẹ.
ו [Wọ́ọ̀]
41 Jèhófà, jẹ́ kí n rí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+Kí n rí ìgbàlà rẹ bí o ti ṣèlérí;*+
42 Nígbà náà, màá fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi lésì,Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ kúrò ní ẹnu mi,Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé* ìdájọ́ rẹ.
44 Èmi yóò máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo,Títí láé àti láéláé.+
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní ibi ààbò,*+Nítorí mò ń wá àwọn àṣẹ rẹ.
46 Èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí rẹ níwájú àwọn ọba,Mi ò sì ní tijú.+
47 Mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ,Àní, mo nífẹ̀ẹ́ wọn.+
48 Màá tẹ́ ọwọ́ mi sókè sí ọ nítorí àwọn àṣẹ rẹ, torí mo nífẹ̀ẹ́ wọn,+Màá sì máa ronú lórí* àwọn ìlànà rẹ.+
ז [Sáyìn]
49 Rántí ọ̀rọ̀ tí o sọ* fún ìránṣẹ́ rẹ,Èyí tí o fi mú kí n nírètí.*
50 Ohun tó ń tù mí nínú nìyí nínú ìpọ́njú mi,+Ọ̀rọ̀ rẹ ló ń mú kí n wà láàyè.
51 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn kàn mí lábùkù,Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú òfin rẹ.+
52 Jèhófà, mo rántí àwọn ìdájọ́ rẹ ti ìgbà àtijọ́,+Wọ́n sì ń tù mí nínú.+
53 Mo gbaná jẹ gidigidi nítorí àwọn ẹni burúkúTó ń pa òfin rẹ tì.+
54 Orin ni àwọn ìlànà rẹ jẹ́ fún miNíbikíbi tí mo bá ń gbé.*
55 Jèhófà, mò ń rántí orúkọ rẹ ní òru,+Kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́.
56 Ó ti jẹ́ ìṣe mi,Nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.
ח [Hétì]
57 Jèhófà, ìwọ ni ìpín mi;+Mo ti ṣèlérí pé màá pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+
58 Mo fi gbogbo ọkàn mi bẹ̀ ọ́;*+Ṣojú rere sí mi+ bí o ti ṣèlérí.*
59 Mo ti yẹ àwọn ọ̀nà mi wò,Kí n lè yí ẹsẹ̀ mi pa dà sí àwọn ìránnilétí rẹ.+
60 Mo yára, mi ò sì jáfaraLáti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+
61 Okùn àwọn ẹni burúkú yí mi ká,Àmọ́ mi ò gbàgbé òfin rẹ.+
62 Mo jí ní ọ̀gànjọ́ òru kí n lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ+Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo.
63 Ọ̀rẹ́ mi ni gbogbo àwọn tó bẹ̀rù rẹÀti àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+
64 Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ kún inú ayé;+Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.
ט [Tétì]
65 Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ,O ti hùwà sí ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà tó dáa.
66 Kọ́ mi kí n lè ní làákàyè àti ìmọ̀,+Nítorí àwọn àṣẹ rẹ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.
67 Kí a tó fìyà jẹ mí, mo máa ń ṣe ségesège,*
Àmọ́ ní báyìí, ohun tí o sọ ni mò ń ṣe.+
68 Ẹni rere ni ọ́,+ àwọn iṣẹ́ rẹ sì dára.
Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+
69 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn ti fi irọ́ yí mi lára,Àmọ́ mò ń fi gbogbo ọkàn mi pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.
70 Ọkàn wọn ti yigbì,*+Àmọ́ mo fẹ́ràn òfin rẹ.+
71 Ó dára bí a ṣe fìyà jẹ mí,+Kí n lè kọ́ àwọn ìlànà rẹ.
72 Òfin tí o kéde dára fún mi,+Ó dára ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.+
י [Yódì]
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi, tí ó sì mọ mí.
Fún mi ní òye,+Kí n lè kọ́ àwọn àṣẹ rẹ.
74 Àwọn tó bẹ̀rù rẹ rí mi, wọ́n sì ń yọ̀,Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*+
75 Jèhófà, mo mọ̀ pé àwọn ìdájọ́ rẹ jẹ́ òdodo+Àti pé nínú òtítọ́ rẹ ni o fìyà jẹ mí.+
76 Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ tù mí nínú,Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe* fún ìránṣẹ́ rẹ.
77 Ṣàánú mi, kí n lè máa wà láàyè,+Nítorí mo fẹ́ràn òfin rẹ.+
78 Kí ojú ti àwọn tó ń kọjá àyè wọn,Nítorí wọ́n ń ṣe ohun tí kò dáa sí mi láìnídìí.*
Àmọ́ èmi yóò máa ronú lórí* àwọn àṣẹ rẹ.+
79 Kí àwọn tó bẹ̀rù rẹ pa dà sọ́dọ̀ mi,Àwọn tó mọ ìránnilétí rẹ.
80 Kí ọkàn mi jẹ́ aláìlẹ́bi bí mo ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ,+Kí ojú má bàa tì mí.+
כ [Káfì]
81 Ọkàn mi ń fà sí* ìgbàlà rẹ,+Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*
82 Ojú mi fẹ́ máa rí ọ̀rọ̀ rẹ+Nígbà tí mo béèrè pé: “Ìgbà wo lo máa tù mí nínú?”+
83 Nítorí mo dà bí ìgò awọ tí èéfín ti mú kí ó gbẹ,Àmọ́ mi ò gbàgbé àwọn ìlànà rẹ.+
84 Ọjọ́ mélòó ni kí ìránṣẹ́ rẹ fi dúró?
Ìgbà wo lo máa dá àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi lẹ́jọ́?+
85 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn gbẹ́ kòtò fún mi,Àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.
Àwọn èèyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí; ràn mí lọ́wọ́!+
87 Díẹ̀ ló kù kí wọ́n pa mí rẹ́ kúrò láyé,
Àmọ́ mi ò pa àwọn àṣẹ rẹ tì.
88 Mú kí n máa wà láàyè nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
Kí n lè máa pa àwọn ìránnilétí tí o sọ mọ́.
ל [Lámédì]
89 Jèhófà, títí láéNi ọ̀rọ̀ rẹ yóò wà ní ọ̀run.+
90 Òtítọ́ rẹ wà láti ìran dé ìran.+
O ti fìdí ayé múlẹ̀ gbọn-in, kó lè máa wà nìṣó.+
91 Nípasẹ̀ ìdájọ́ rẹ ni wọ́n* fi wà títí di òní,Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni gbogbo wọn.
92 Tí kì í bá ṣe pé mo fẹ́ràn òfin rẹ ni,Mi ò bá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.+
93 Mi ò ní gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ láé,Torí pé nípasẹ̀ wọn lo fi mú kí n wà láàyè.+
94 Tìrẹ ni mo jẹ́; gbà mí sílẹ̀,+Nítorí pé mo ti wá àwọn àṣẹ rẹ.+
95 Àwọn ẹni burúkú dènà dè mí láti pa mí,Àmọ́ mò ń fiyè sí àwọn ìránnilétí rẹ.
96 Mo ti rí i pé kò sí ohun tó dáa tí kò kù síbì kan,Àmọ́ àṣẹ rẹ dára láìkù síbì kan.*
מ [Mémì]
97 Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!+
Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.*+
98 Àṣẹ rẹ mú kí n gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,+Nítorí pé ó wà pẹ̀lú mi títí láé.
99 Mo ní òye tó jinlẹ̀ ju ti gbogbo àwọn olùkọ́ mi,+Nítorí pé mò ń ronú lórí* àwọn ìránnilétí rẹ.
100 Mò ń fi òye hùwà ju àwọn àgbààgbà lọ,Nítorí pé mò ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.
101 Mi ò rìn ní ọ̀nà ibi èyíkéyìí,+Kí n lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.
102 Mi ò yà kúrò nínú àwọn ìdájọ́ rẹ,Nítorí o ti kọ́ mi.
103 Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mà dùn mọ́ òkè ẹnu mi o,Ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi!+
104 Àwọn àṣẹ rẹ ló mú kí n máa fòye hùwà.+
Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+
נ [Núnì]
105 Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ miÀti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.+
106 Mo ti búra, màá sì mú un ṣẹ,Kí n lè máa pa àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo mọ́.
107 A ti fìyà jẹ mí gan-an.+
Jọ̀ọ́ Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè bí o ṣe sọ.+
108 Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí inú rẹ dùn sí ọrẹ ìyìn àtọkànwá mi,*+Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìdájọ́ rẹ.+
109 Ẹ̀mí mi wà nínú ewu* nígbà gbogbo,Àmọ́ mi ò gbàgbé òfin rẹ.+
110 Àwọn ẹni burúkú ti dẹ pańpẹ́ dè mí,Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+
111 Mo fi àwọn ìránnilétí rẹ ṣe ohun ìní mi tí á máa wà títí lọ,*Nítorí àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.+
112 Mo ti pinnu* láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹNígbà gbogbo, màá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.
ס [Sámékì]
113 Mo kórìíra àwọn aláàbọ̀-ọkàn,*+Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ.+
114 Ìwọ ni ibi ààbò mi àti apata mi,+Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*+
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,+Kí n lè pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́.
116 Tì mí lẹ́yìn bí o ti ṣèlérí,*+Kí n lè máa wà láàyè;Má ṣe jẹ́ kí ìrètí mi já sí asán.*+
117 Tì mí lẹ́yìn, kí n lè rí ìgbàlà;+Nígbà náà, èmi yóò máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlànà rẹ.+
118 O kọ àwọn tó ń yà kúrò nínú àwọn ìlànà rẹ,+Nítorí wọ́n jẹ́ onírọ́ àti ẹlẹ́tàn.
119 O kó gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé dà nù bíi pàǹtírí.*+
Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí rẹ.
120 Ẹ̀rù rẹ mú kí ara* mi máa gbọ̀n;Mò ń bẹ̀rù àwọn ìdájọ́ rẹ.
ע [Áyìn]
121 Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òdodo.
Má ṣe fi mí lé ọwọ́ àwọn tó ń ni mí lára!
122 Fi dá ìránṣẹ́ rẹ lójú pé wàá tì í lẹ́yìn;Kí àwọn tó ń kọjá àyè wọn má ṣe ni mí lára.
123 Ojú mi ti di bàìbàì bí mo ṣe ń dúró de ìgbàlà rẹ+Àti ìlérí* òdodo rẹ.+
124 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ,+Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+
125 Ìránṣẹ́ rẹ ni mí; fún mi ní òye,+Kí n lè mọ àwọn ìránnilétí rẹ.
126 Jèhófà, ó ti tó àkókò fún ọ láti gbé ìgbésẹ̀,+Nítorí wọ́n ti rú òfin rẹ.
127 Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹJu wúrà, kódà ju wúrà tó dára* lọ.+
128 Nítorí náà, mo gbà pé gbogbo ẹ̀kọ́* tó bá wá látọ̀dọ̀ rẹ tọ̀nà;+Mo kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+
פ [Péè]
129 Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ àgbàyanu.
Ìdí nìyẹn tí mo* fi ń kíyè sí wọn.
130 Ṣíṣí ọ̀rọ̀ rẹ payá ń mú ìmọ́lẹ̀ wá,+Ó ń fún àwọn aláìmọ̀kan ní òye.+
131 Mo la gbogbo ẹnu mi, mo sì mí kanlẹ̀,*Nítorí pé ọkàn mi ń fà sí àwọn àṣẹ rẹ.+
132 Yíjú sí mi, kí o sì ṣojú rere sí mi,+Gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ rẹ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ.+
133 Fi ọ̀rọ̀ rẹ darí ìṣísẹ̀ mi láìséwu;*Kí aburú kankan má ṣe jọba lórí mi.+
134 Gbà mí* lọ́wọ́ àwọn aninilára,Màá sì pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.
135 Mú kí ojú rẹ tàn sára* ìránṣẹ́ rẹ,+Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.
136 Omijé ń dà ní ojú miNítorí àwọn èèyàn kò pa òfin rẹ mọ́.+
צ [Sádì]
137 Olódodo ni ọ́, Jèhófà,+Àwọn ìdájọ́ rẹ sì tọ́.+
138 Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ òdodo,Wọ́n sì ṣeé gbára lé pátápátá.
139 Ìtara mi fún ọ gbà mí lọ́kàn,+Nítorí àwọn ọ̀tá mi ti gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.
140 Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́ dáadáa,+Ìránṣẹ́ rẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+
141 Mi ò já mọ́ nǹkan kan, mo sì jẹ́ ẹni ẹ̀gàn;+Síbẹ̀, mi ò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.
142 Òdodo rẹ jẹ́ òdodo ayérayé,+Òfin rẹ sì jẹ́ òtítọ́.+
143 Bí wàhálà àti ìṣòro tilẹ̀ bá mi,Síbẹ̀, mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ.
144 Òdodo àwọn ìránnilétí rẹ wà títí láé.
Fún mi ní òye,+ kí n lè máa wà láàyè.
ק [Kófì]
145 Gbogbo ọkàn mi ni mo fi pè ọ́. Dá mi lóhùn, Jèhófà.
Màá pa àwọn ìlànà rẹ mọ́.
146 Mo ké pè ọ́; gbà mí!
Màá pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́.
147 Mo ti jí kí ilẹ̀ tó mọ́,* kí n lè kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*
148 Ojú mi là kí àwọn ìṣọ́ òru tó bẹ̀rẹ̀,Kí n lè ronú lórí* ọ̀rọ̀ rẹ.+
149 Jọ̀wọ́ gbọ́ ohùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+
Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ.
150 Àwọn tó ń hu ìwà àìnítìjú* sún mọ́ tòsí;Wọ́n jìnnà réré sí òfin rẹ.
151 Jèhófà, o wà nítòsí,+Òtítọ́ sì ni gbogbo àṣẹ rẹ.+
152 Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti kọ́ nípa àwọn ìránnilétí rẹ,Pé o ṣe wọ́n kí wọ́n lè wà títí láé.+
ר [Réṣì]
153 Wo ìyà tó ń jẹ mí, kí o sì gbà mí sílẹ̀,+Nítorí mi ò gbàgbé òfin rẹ.
154 Gbèjà mi,* kí o sì gbà mí sílẹ̀;+Mú kí n máa wà láàyè bí o ti ṣèlérí.*
155 Ìgbàlà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,Nítorí wọn kò wá àwọn ìlànà rẹ.+
156 Àánú rẹ pọ̀, Jèhófà.+
Mú kí n máa wà láàyè nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ.
157 Àwọn ọ̀tá mi àti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi pọ̀;+Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú àwọn ìránnilétí rẹ.
158 Ojú burúkú ni mo fi ń wo àwọn oníbékebèke,Torí wọn kì í pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+
159 Wo bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹ!
Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+
160 Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ,+Gbogbo ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo sì wà títí láé.
ש [Sínì] tàbí [Ṣínì]
161 Àwọn olórí ń ṣe inúnibíni sí mi+ láìnídìí,Àmọ́ ìbẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ wà lọ́kàn mi.+
162 Ọ̀rọ̀ rẹ ń mú inú mi dùn,+Bí ẹni tó rí ẹrù púpọ̀ kó lójú ogun.
163 Mo kórìíra irọ́, mo kórìíra rẹ̀ gidigidi,+Mo nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ.+
164 Ìgbà méje lóòjọ́ ni mò ń yìn ọ́Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.
165 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ;+Kò sí ohun tó lè mú wọn kọsẹ̀.*
166 Mò ń retí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ, Jèhófà,Mo sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.
167 Mò* ń pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,Mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn púpọ̀.+
168 Mò ń pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,Nítorí o mọ gbogbo ohun tí mò ń ṣe.+
ת [Tọ́ọ̀]
169 Kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ, Jèhófà.+
Fún mi ní òye nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.+
170 Kí ìbéèrè mi fún ojú rere wá síwájú rẹ.
Gbà mí bí o ti ṣèlérí.*
171 Kí ìyìn kún ẹnu mi,*+Nítorí o ti kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.
172 Kí ahọ́n mi máa fi ọ̀rọ̀ rẹ kọrin,+Nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Kí ọwọ́ rẹ ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́,+Nítorí mo ti pinnu pé màá máa pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+
174 Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, Jèhófà,Mo sì fẹ́ràn òfin rẹ.+
175 Jẹ́ kí n* máa wà láàyè, kí n lè máa yìn ọ́;+Kí àwọn ìdájọ́ rẹ máa ràn mí lọ́wọ́.
176 Mo ti ṣìnà bí àgùntàn tó sọ nù.+ Wá ìránṣẹ́ rẹ,Nítorí mi ò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”
^ Ní Héb., “Ì bá ṣe pé àwọn ọ̀nà mi fìdí múlẹ̀ gbọn-in.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”
^ Ní Héb., “Yí ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lórí mi.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.”
^ Tàbí “Ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “ọ̀nà.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “kí ojú tì mí.”
^ Ní Héb., “Màá sáré ní.”
^ Tàbí kó jẹ́, “o mú kí ọkàn mi ní ìgboyà.”
^ Tàbí “Mú mi rìn.”
^ Tàbí “Kó má ṣe fà sí èrè.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ tí o sọ.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Èyí tí o ṣe fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ.”
^ Tàbí “sọ.”
^ Tàbí “mo dúró de.”
^ Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”
^ Tàbí “ìlérí tí o ṣe.”
^ Tàbí “Èyí tí o mú kí n dúró dè.”
^ Tàbí “Ní ilé tí mo ti jẹ́ àjèjì.”
^ Tàbí “tù ọ́ lójú (wá ẹ̀rín rẹ).”
^ Tàbí “sọ.”
^ Tàbí “mo máa ń dẹ́ṣẹ̀ láì mọ̀ọ́mọ̀.”
^ Ní Héb., “kú tipiri, bí ọ̀rá.”
^ Tàbí “ni mo dúró dè.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ tí o sọ.”
^ Tàbí kó jẹ́, “wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”
^ Tàbí “Ọkàn mi ń kú lọ nítorí.”
^ Tàbí “ni mo dúró dè.”
^ Ìyẹn, gbogbo ohun tó dá.
^ Ní Héb., “gbòòrò gan-an.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”
^ Ní Héb., “ọrẹ àtọkànwá ẹnu mi.”
^ Tàbí “Ọkàn mi wà ní ọwọ́ mi.”
^ Tàbí “ogún mi ayérayé.”
^ Ní Héb., “tẹ ọkàn mi.”
^ Tàbí “àwọn tí ọkàn wọn pínyà.”
^ Tàbí “Màá dúró de ọ̀rọ̀ rẹ.”
^ Tàbí “sọ.”
^ Tàbí “ìtìjú.”
^ Ní Héb., “ìdàrọ́.”
^ Ní Héb., “ẹran ara.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”
^ Tàbí “àṣẹ.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ní Héb., “mí hẹlẹ.”
^ Tàbí “mú kí ìṣísẹ̀ mi ṣe tààrà.”
^ Ní Héb., “Rà mí pa dà.”
^ Tàbí “rẹ́rìn-ín sí.”
^ Tàbí “nígbà tí ọ̀yẹ̀ ń là.”
^ Tàbí “ni mò ń dúró dè.”
^ Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”
^ Tàbí “ìwà tó ń ríni lára.”
^ Tàbí “Gba ẹjọ́ mi rò.”
^ Tàbí “sọ.”
^ Tàbí “Kò sí ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan fún wọn.”
^ Tàbí “Ọkàn mi.”
^ Tàbí “sọ.”
^ Ní Héb., “Kí ìyìn máa dà ní ètè mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”