Sáàmù 121:1-8

  • Jèhófà ń ṣọ́ àwọn èèyàn rẹ̀

    • “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá” (2)

    • Jèhófà kì í sùn (3, 4)

Orin Ìgòkè. 121  Mo gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè.+ Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?  Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá,+Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.  Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ yọ̀.*+ Ẹni tó ń ṣọ́ ọ kò ní tòògbé láé.  Wò ó! Ẹni tó ń ṣọ́ Ísírẹ́lì kì í tòògbé,Bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.+  Jèhófà ń ṣọ́ ọ. Jèhófà ni ibòji+ tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+  Oòrùn kò ní pa ọ́ lára ní ọ̀sán,+Tàbí òṣùpá ní òru.+  Jèhófà yóò máa ṣọ́ ọ kí jàǹbá kankan má ṣe ọ́.+ Yóò máa ṣọ́ ẹ̀mí* rẹ.+  Jèhófà yóò máa ṣọ́ ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe*Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ṣọ́ ìjáde àti ìwọlé rẹ.”