Sáàmù 127:1-5

  • Láìsí Ọlọ́run, asán ni gbogbo nǹkan

    • “Bí Jèhófà ò bá kọ́ ilé” (1)

    • Àwọn ọmọ jẹ́ èrè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (3)

Orin Ìgòkè. Ti Sólómọ́nì. 127  Bí Jèhófà ò bá kọ́ ilé,Lásán ni àwọn tó ń kọ́ ọ ṣiṣẹ́ kára lórí rẹ̀.+ Bí Jèhófà ò bá ṣọ́ ìlú,+Lásán ni ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò.  Lásán lẹ̀ ń dìde ní kùtùkùtù,Tí ẹ̀ ń pẹ́ kí ẹ tó sùn,Tí ẹ sì ń fi gbogbo agbára ṣiṣẹ́ kí ẹ lè rí oúnjẹ,Torí Ọlọ́run ń pèsè fún àwọn tó fẹ́ràn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí oorun sùn.+  Wò ó! Àwọn ọmọ* jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà;+Èso ikùn* jẹ́ èrè.+  Bí ọfà ní ọwọ́ alágbára ọkùnrin,Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ téèyàn bí nígbà ọ̀dọ́.+  Aláyọ̀ ni ọkùnrin tó fi wọ́n kún apó rẹ̀.+ Ojú kò ní tì wọ́n,Nítorí wọ́n á bá àwọn ọ̀tá sọ̀rọ̀ ní ẹnubodè ìlú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ọmọkùnrin.”
Tàbí “ilé ọlẹ̀.”