Sáàmù 139:1-24
Fún olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.
139 Jèhófà, o ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, o sì mọ̀ mí.+
2 O mọ ìgbà tí mo bá jókòó àti ìgbà tí mo bá dìde.+
Láti ibi tó jìnnà réré, o mọ ohun tí mò ń rò.+
3 Ò ń kíyè sí* mi nígbà tí mo bá ń rìnrìn àjò àti nígbà tí mo bá dùbúlẹ̀;Gbogbo àwọn ọ̀nà mi ò ṣàjèjì sí ọ.+
4 Kí n tó sọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,Wò ó, Jèhófà, o ti mọ gbogbo ohun tí mo fẹ́ sọ.+
5 Lẹ́yìn mi àti níwájú mi, o yí mi ká;O sì gbé ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kọjá òye mi.*
Ó kọjá ohun tí ọwọ́ mi lè tẹ̀.*+
7 Ibo ni mo lè sá sí tí màá fi bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ,Ibo ni mo sì lè sá lọ kí ojú rẹ má bàa tó mi?+
8 Tí mo bá lọ sọ́run, wàá wà níbẹ̀,Tí mo bá sì tẹ́ ibùsùn mi sínú Isà Òkú,* wò ó! wàá ti wà níbẹ̀.+
9 Tí mo bá fi ìyẹ́ apá ọ̀yẹ̀ fò lọ,Kí n lè máa gbé létí òkun tó jìnnà jù lọ,
10 Kódà, ọwọ́ rẹ yóò darí mi níbẹ̀,Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mí mú.+
11 Tí mo bá sọ pé: “Dájúdájú, òkùnkùn yóò fi mí pa mọ́!”
Nígbà náà, òkùnkùn tó yí mi ká yóò di ìmọ́lẹ̀.
12 Kódà, òkùnkùn náà kò ní ṣú jù fún ọ,Ṣe ni òru yóò mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;+Ìkan náà ni òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ lójú rẹ.+
13 Ìwọ lo ṣe àwọn kíndìnrín mi;O yà mí sọ́tọ̀* ní inú ìyá mi.+
14 Mo yìn ọ́ nítorí pé lọ́nà tó ń bani lẹ́rù ni o ṣẹ̀dá mi tìyanutìyanu.+
Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,+Mo* mọ èyí dáadáa.
15 Àwọn egungun mi ò pa mọ́ fún ọNígbà tí o ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀,Nígbà tí o hun mí ní ìsàlẹ̀ ayé.+
16 Kódà, ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn;*Gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹNí ti àwọn ọjọ́ tí o ṣẹ̀dá wọn,Kí ìkankan lára wọn tó wà.
17 Lójú tèmi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣeyebíye o!+
Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn mà pọ̀ o!+
18 Tí mo bá ní kí n máa kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ.+
Nígbà tí mo jí, mo ṣì wà pẹ̀lú rẹ.*+
19 Ọlọ́run, ká ní o bá pa ẹni burúkú!+
Nígbà náà, àwọn oníwà ipá* yóò kúrò lọ́dọ̀ mi,
20 Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú èrò ibi lọ́kàn;*Àwọn ni ọ̀tá rẹ tí wọ́n ń lo orúkọ rẹ lọ́nà tí kò ní láárí.+
21 Mo kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ, Jèhófà,+Mi ò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń dìtẹ̀ sí ọ.+
22 Mo kórìíra wọn gan-an;+Wọ́n ti di ọ̀tá paraku sí mi.
23 Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn mi.+
Ṣàyẹ̀wò mi, kí o sì mọ àwọn ohun tó ń gbé mi lọ́kàn sókè.*+
24 Wò ó bóyá ìwà burúkú kankan wà nínú mi,+Kí o sì darí mi+ sí ọ̀nà ayérayé.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “díwọ̀n.”
^ Tàbí “yà mí lẹ́nu gan-an.”
^ Tàbí “jinlẹ̀ ju ohun tí mo lè lóye.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “hun mí.”
^ Tàbí “Ọkàn mi.”
^ Tàbí “tí mo ṣì jẹ́ ọlẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́., “màá ṣì máa kà wọ́n.”
^ Tàbí “ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀.”
^ Tàbí “lórí èrò tiwọn.”
^ Tàbí “tó ń dà mí lọ́kàn rú.”