Sáàmù 141:1-10
Orin Dáfídì.
141 Jèhófà, mo ké pè ọ́.+
Tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+
Fetí sílẹ̀ nígbà tí mo bá pè ọ́. +
2 Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí+ tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ,+Kí ọwọ́ tí mo gbé sókè dà bí ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́.+
3 Jèhófà, jọ̀wọ́ yan ẹ̀ṣọ́ fún ẹnu mi,Kí o sì máa ṣọ́ ilẹ̀kùn ètè mi.+
4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun búburú kankan,+Kí n má bàa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ibi pẹ̀lú àwọn aṣebi;Kí n má ṣe jẹ oúnjẹ aládùn wọn láé.
5 Tí olódodo bá gbá mi, á jẹ́ pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí mi;+Tó bá bá mi wí, á dà bí òróró ní orí mi,+Tí orí mi kò ní kọ̀ láé.+
Mi ò ní dákẹ́ àdúrà kódà nígbà tí àjálù bá bá wọn.
6 Bí a tilẹ̀ ju àwọn onídàájọ́ wọn sílẹ̀ láti ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta,Àwọn èèyàn yóò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, torí pé ó lárinrin.
7 Bí ìgbà tí ẹnì kan bá ń tú ilẹ̀, tó sì ń tú u ká,Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tú egungun wa ká ní ẹnu Isà Òkú.*
8 Ojú rẹ ni mò ń wò, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+
Ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.
Má ṣe gba ẹ̀mí mi.*
9 Dáàbò bò mí kí n má bàa kó sí ẹnu pańpẹ́ tí wọ́n dẹ dè mí,Lọ́wọ́ ìdẹkùn àwọn aṣebi.
10 Àwọn ẹni burúkú lápapọ̀ yóò já sínú àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ,+Èmi á sì kọjá lọ láìséwu.