Sáàmù 147:1-20

  • Ẹ máa yin àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run tó fi ìfẹ́ àti agbára rẹ̀ hàn

    • Ó ń wo àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn sàn (3)

    • Ó ń fi orúkọ pe gbogbo àwọn ìràwọ̀ (4)

    • Ó ń fi yìnyín ránṣẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú (16)

147  Ẹ yin Jáà!* Ó dára láti máa kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run wa;Ẹ wo bí ó ti dùn tó, tí ó sì tọ́ láti máa yìn ín!+  Jèhófà ń kọ́ Jerúsálẹ́mù;+Ó ń kó àwọn tí wọ́n fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ.+  Ó ń mú àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn lára dá;Ó ń di àwọn egbò wọn.  Ó ń ka iye àwọn ìràwọ̀;Gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ pè.+  Olúwa wa tóbi, agbára rẹ̀ sì pọ̀;+Òye rẹ̀ ò ṣeé díwọ̀n.+  Jèhófà ń gbé àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ dìde,+Àmọ́, ó ń rẹ àwọn ẹni burúkú wálẹ̀.  Ẹ kọrin sí Jèhófà pẹ̀lú ìdúpẹ́;Ẹ fi háàpù kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run wa,  Ẹni tó ń fi àwọsánmà bo ojú ọ̀run,Ẹni tó ń pèsè òjò fún ayé,+Ẹni tó ń mú kí koríko hù+ lórí àwọn òkè.  Ó ń fún àwọn ẹranko lóúnjẹ,+Àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò tó ń kígbe fún oúnjẹ.+ 10  Kì í ṣe agbára ẹṣin ló ń mú inú rẹ̀ dùn;+Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe agbára ẹsẹ̀ èèyàn ló ń wú u lórí.+ 11  Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+Sí àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+ 12  Yin Jèhófà lógo, ìwọ Jerúsálẹ́mù. Yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì. 13  Ó ń mú kí ọ̀pá ìdábùú àwọn ẹnubodè rẹ lágbára;Ó ń bù kún àwọn ọmọ rẹ nínú rẹ. 14  Ó ń mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ rẹ;+Ó ń fi àlìkámà* tó dára jù lọ* tẹ́ ọ lọ́rùn.+ 15  Ó ń fi àṣẹ rẹ̀ ránṣẹ́ sí ayé;Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń yára kánkán. 16  Ó ń fi yìnyín ránṣẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú;+Ó ń fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.+ 17  Ó ń fi yìnyín* rẹ̀ sọ̀kò sílẹ̀ bí òkèlè.+ Ta ló lè fara da òtútù rẹ̀?+ 18  Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde, wọ́n sì yọ́. Ó mú kí ẹ̀fúùfù rẹ̀ fẹ́,+ omi sì ń ṣàn. 19  Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù,Ó sọ àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì.+ 20  Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè míì;+Wọn ò mọ nǹkan kan nípa ìdájọ́ rẹ̀. Ẹ yin Jáà!*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kọrin.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “ọ̀rá àlìkámà.”
Tàbí “omi dídì.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.