Sáàmù 150:1-6

  • Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà

    • Halelúyà! (1, 6)

150  Ẹ yin Jáà!*+ Ẹ yin Ọlọ́run nínú ibi mímọ́ rẹ̀.+ Ẹ yìn ín nínú òfúrufú* agbára rẹ̀.+  Ẹ yìn ín nítorí àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ̀.+ Ẹ yìn ín nítorí títóbi rẹ̀ tó ta yọ.+  Ẹ fun ìwo láti fi yìn ín.+ Ẹ fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù yìn ín.+  Ẹ fi ìlù tanboríìnì+ àti ijó àjóyípo yìn ín. Ẹ fi àwọn nǹkan olókùn tín-ín-rín+ àti fèrè*+ yìn ín.  Ẹ fi àwọn síńbálì* tó ń dún yìn ín. Ẹ fi àwọn síńbálì+ tó ń dún gooro yìn ín.  Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà. Ẹ yin Jáà!*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “ojú ọ̀run tó ń jẹ́rìí sí.”
Tàbí “ape.”
Tàbí “aro.”
Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.