Sáàmù 16:1-11
Míkítámù* ti Dáfídì.
16 Dáàbò bò mí, Ọlọ́run, nítorí ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò.+
2 Mo ti sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Jèhófà, Orísun oore mi.
3 Àwọn ẹni mímọ́ tó wà láyéÀti àwọn ọlọ́lá, ń mú inú mi dùn jọjọ.”+
4 Àwọn tó ń tẹ̀ lé ọlọ́run mìíràn ń sọ ìbànújẹ́ wọn di púpọ̀.+
Mi ò ní bá wọn da ọrẹ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni ètè mi ò ní dárúkọ wọn.*+
5 Jèhófà ni ìpín mi, apá tí ó kàn mí+ àti ife mi.+
O dáàbò bo ogún mi.
6 A ti díwọ̀n àwọn ibi tó dáa jáde fún mi.
Bẹ́ẹ̀ ni, ogún mi tẹ́ mi lọ́rùn.+
7 Màá yin Jèhófà, ẹni tó fún mi ní ìmọ̀ràn.+
Kódà láàárín òru, èrò inú mi* ń tọ́ mi sọ́nà.+
8 Mo gbé Jèhófà síwájú mi nígbà gbogbo.+
Torí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, mìmì kan ò ní mì mí.*+
9 Nítorí náà, ọkàn mi ń yọ̀, gbogbo ara* mi ń dunnú.
Mo* sì ń gbé lábẹ́ ààbò.
10 Torí o ò ní fi mí sílẹ̀* nínú Isà Òkú.*+
O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.*+
11 O jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè.+
Ayọ̀ púpọ̀+ wà ní iwájú* rẹ,Ìdùnnú* sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ìyẹn, orúkọ àwọn ọlọ́run èké.
^ Tàbí “inú mi lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín mi.”
^ Tàbí “mi ò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”
^ Ní Héb., “ògo.”
^ Tàbí “Ara mi.”
^ Tàbí “o ò ní pa ọkàn mi tì.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “ìdíbàjẹ́.”
^ Ní Héb., “ojú.”
^ Tàbí “Adùn.”