Sáàmù 18:1-50
Sí olùdarí. Látọ̀dọ̀ Dáfídì ìránṣẹ́ Jèhófà, tí ó kọ ọ̀rọ̀ yìí lórin sí Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà gbà á lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. Ó sọ pé:+
18 Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ ni okun mi.+
2 Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi ààbò mi àti Ẹni tó ń gbà mí sílẹ̀.+
Ọlọ́run mi ni àpáta mi,+ ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,Apata mi àti ìwo* ìgbàlà mi,* ibi ààbò mi.*+
3 Mo ké pe Jèhófà, ẹni tí ìyìn yẹ,Yóò sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+
4 Àwọn okùn ikú yí mi ká;+Àwọn ọkùnrin tí kò ní láárí ya lù mí bí omi.+
5 Àwọn okùn Isà Òkú* yí mi ká;Ikú dẹ pańpẹ́ síwájú mi.+
6 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,Mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́.
Ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀,+Igbe tí mo ké sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.+
7 Nígbà náà, ayé bẹ̀rẹ̀ sí í mì, ó sì ń mì jìgìjìgì;+Ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì,Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí a ti mú un bínú.+
8 Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,Iná tó ń jóni run jáde láti ẹnu rẹ̀,+Ẹyin iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
9 Ó tẹ ọ̀run wálẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀.+
Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+
10 Ó gun kérúbù, ó sì ń fò bọ̀.+
Ó ń bọ̀ ṣòòrò wálẹ̀ lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.*+
11 Ó wá fi òkùnkùn bo ara rẹ̀,+Ó bò ó yí ká bí àgọ́,Nínú ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀.+
12 Láti inú ìmọ́lẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀,Yìnyín àti ẹyin iná gba inú àwọsánmà jáde.
13 Nígbà náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sán ààrá ní ọ̀run;+Ẹni Gíga Jù Lọ mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀+Pẹ̀lú yìnyín àti ẹyin iná.
14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú wọn ká;+Ó ju mànàmáná rẹ̀, ó sì kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+
15 Ìsàlẹ̀ odò* hàn síta;+Àwọn ìpìlẹ̀ ayé hàn síta nítorí ìbáwí rẹ, Jèhófà,Nípa èémí tó tú jáde ní ihò imú rẹ.+
16 Ó na ọwọ́ rẹ̀ láti òkè;Ó mú mi, ó sì fà mí jáde látinú omi jíjìn.+
17 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+Lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi, tí wọ́n sì lágbára jù mí lọ.+
18 Wọ́n kò mí lójú ní ọjọ́ àjálù mi,+Ṣùgbọ́n Jèhófà ni alátìlẹyìn mi.
19 Ó mú mi jáde wá sí ibi ààbò;*Ó gbà mí sílẹ̀ nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.+
20 Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi;+Ó san èrè fún mi nítorí pé ọwọ́ mi mọ́.*+
21 Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,Mi ò hùwà burúkú, kí n wá fi Ọlọ́run mi sílẹ̀.
22 Gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wà ní iwájú mi;Mi ò ní pa àwọn òfin rẹ̀ tì.
23 Màá jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀,+Màá sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+
24 Kí Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi+Àti nítorí pé ọwọ́ mi mọ́ ní iwájú rẹ̀.+
25 Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin;+Ìwọ ń hùwà àìlẹ́bi sí ọkùnrin aláìlẹ́bi;+
26 Ìwọ jẹ́ mímọ́ sí ẹni tí ó mọ́,+Àmọ́ ìwọ ń jẹ́ kí àwọn oníbékebèke mọ̀ pé òmùgọ̀ ni wọ́n.+
27 Ò ń gba àwọn ẹni rírẹlẹ̀* là+Ṣùgbọ́n ò ń rẹ àwọn agbéraga*+ wálẹ̀.
28 Jèhófà, ìwọ lò ń tan fìtílà mi,Ọlọ́run mi tó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn+ mi.
29 Ìrànlọ́wọ́ rẹ ni mo fi lè gbéjà ko àwọn jàǹdùkú;*+Agbára Ọlọ́run ni mo fi lè gun ògiri.+
30 Pípé ni ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́;+Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+
Apata ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.+
31 Ta ni Ọlọ́run bí kò ṣe Jèhófà?+
Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+
32 Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹni tó ń gbé agbára wọ̀ mí,+Yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé.+
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ti àgbọ̀nrín,Ó sì mú mi dúró ní àwọn ibi gíga.+
34 Ó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ogun,Apá mi sì lè tẹ ọrun tí a fi bàbà ṣe.
35 O fún mi ní apata rẹ láti gbà mí là,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń tì mí lẹ́yìn,*Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá.+
36 O fẹ ọ̀nà fún ẹsẹ̀ mi;Kí ẹsẹ̀* mi má bàa yọ̀.+
37 Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì bá wọn;Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́.
38 Màá fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má lè gbérí mọ́;+Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 Wàá fún mi lókun láti jagun,Wàá sì mú kí àwọn ọ̀tá mi ṣubú sábẹ́ mi.+
40 Wàá mú kí àwọn ọ̀tá mi pa dà lẹ́yìn mi,*Màá sì pa àwọn tó kórìíra mi run.*+
41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó máa gbà wọ́n;Kódà, wọ́n ké pe Jèhófà, àmọ́ kò dá wọn lóhùn.
42 Màá gún wọn kúnná bí eruku inú ẹ̀fúùfù,Màá sì dà wọ́n nù bí ẹrẹ̀ ojú ọ̀nà.
43 Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń wá àléébù.+
Wàá yàn mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.+
Àwọn èèyàn tí mi ò mọ̀ yóò sìn mí.+
44 Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nìkan yóò mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi;Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi.+
45 Ọkàn àwọn àjèjì á domi;*Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn.
46 Jèhófà wà láàyè! Ìyìn ni fún Àpáta mi!+
Kí a gbé Ọlọ́run ìgbàlà mi ga.+
47 Ọlọ́run tòótọ́ ń gbẹ̀san fún mi;+Ó ń ṣẹ́gun àwọn èèyàn lábẹ́ mi.
48 Ó ń gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi tí inú ń bí;Ìwọ gbé mi lékè àwọn tó ń gbéjà kò mí;+O gbà mí lọ́wọ́ oníwà ipá.
49 Jèhófà, ìdí nìyẹn tí màá fi yìn ọ́ lógo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Màá sì fi orin yin* orúkọ rẹ.+
50 Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà* ńlá fún ọba rẹ̀;+Ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,+Sí Dáfídì àti àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ títí láé.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “olùgbàlà mi tó lágbára.”
^ Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ìyẹ́ afẹ́fẹ́.”
^ Tàbí “Ipa odò.”
^ Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”
^ Tàbí “mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.”
^ Tàbí “àwọn tí ìyà ń jẹ.”
^ Ní Héb., “àwọn olójú gíga.”
^ Tàbí “akónilẹ́rù.”
^ Tàbí “ń gbé mi ró.”
^ Tàbí “ọrùn ẹsẹ̀.”
^ Tàbí “Wàá jẹ́ kí n gbá ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọ̀tá mi mú.”
^ Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”
^ Tàbí “Àwọn àjèjì á pòórá.”
^ Tàbí “kọ orin sí.”
^ Tàbí “ìṣẹ́gun.”
^ Ní Héb., “èso.”