Sáàmù 2:1-12

  • Jèhófà àti ẹni àmì òróró rẹ̀

    • Jèhófà ń fi àwọn orílẹ̀-èdè rẹ́rìn-ín (4)

    • Jèhófà fi ọba rẹ̀ jẹ (6)

    • Bọlá fún ọmọ náà (12)

2  Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe awuyewuyeTí àwọn èèyàn sì ń sọ ohun asán lẹ́nu wúyẹ́wúyẹ́?*+   Àwọn ọba ayé dúróÀwọn aláṣẹ sì kóra jọ*+Láti dojú kọ Jèhófà àti ẹni àmì òróró* rẹ̀.+   Wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn kúrò lára waKá sì ju okùn wọn dà nù!”   Ẹni tó wà lórí ìtẹ́ ní ọ̀run á rẹ́rìn-ín;Jèhófà máa fi wọ́n ṣẹ̀sín.   Ní àkókò yẹn, á sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ìbínú rẹ̀Á sì kó jìnnìjìnnì bá wọn nínú ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná,   Á sọ pé: “Èmi fúnra mi ti fi ọba mi jẹ+Lórí Síónì,+ òkè mímọ́ mi.”   Ẹ jẹ́ kí n kéde àṣẹ Jèhófà;Ó sọ fún mi pé: “Ìwọ ni ọmọ mi;+Òní ni mo di bàbá rẹ.+   Béèrè lọ́wọ́ mi, màá fi àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ogún fún ọMàá sì fi gbogbo ìkángun ayé ṣe ohun ìní fún ọ.+   Wàá fi ọ̀pá àṣẹ onírin+ ṣẹ́ wọn,Wàá sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”+ 10  Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye;Ẹ gba ìtọ́sọ́nà,* ẹ̀yin onídàájọ́ ayé. 11  Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà,Kí inú yín sì máa dùn nínú ìbẹ̀rù. 12  Ẹ bọlá fún ọmọ náà,*+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run* máa bínúẸ sì máa ṣègbé kúrò lójú ọ̀nà,+Nítorí ìbínú Rẹ̀ tètè máa ń ru. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó fi Í ṣe ibi ààbò.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ṣe àṣàrò lórí ohun asán.”
Tàbí “gbìmọ̀ pọ̀.”
Tàbí “Kristi.”
Tàbí “Ẹ ṣọ́ra.”
Ní Héb., “Ẹ fẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu.”
Ní Héb., “ó.”