Sáàmù 24:1-10
-
Ọba ológo wọ ẹnubodè
-
“Jèhófà ló ni ayé” (1)
-
Ti Dáfídì. Orin.
24 Jèhófà ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+Ilẹ̀ tó ń méso jáde àti àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.
2 Nítorí ó ti fìdí rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkun+Ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sórí àwọn odò.
3 Ta ló lè gun orí òkè Jèhófà,+Ta ló sì lè dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
4 Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí ọkàn rẹ̀ sì mọ́,+Ẹni tí kò fi ẹ̀mí Mi* búra èké,Tí kò sì búra ẹ̀tàn.+
5 Yóò gba ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà+Àti òdodo* látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.+
6 Ìran àwọn tó ń wá a nìyí,Ti àwọn tó ń wá ojú rẹ, ìwọ Ọlọ́run Jékọ́bù. (Sélà)
7 Ẹ gbé orí yín sókè, ẹ̀yin ẹnubodè;+Ẹ ṣí sílẹ̀,* ẹ̀yin ẹnu ọ̀nà àtijọ́,Kí Ọba ológo lè wọlé!+
8 Ta ni Ọba ológo yìí?
Jèhófà ni, ẹni tó ní okun àti agbára,+Jèhófà, akin lójú ogun.+
9 Ẹ gbé orí yín sókè, ẹ̀yin ẹnubodè;+Ẹ ṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ẹnu ọ̀nà àtijọ́,Kí Ọba ológo lè wọlé!
10 Ta ni Ọba ológo yìí?
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni, òun ni Ọba ológo náà.+ (Sélà)
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn Mi,” ó ń tọ́ka sí wíwàláàyè Jèhófà tí àwọn èèyàn fi ń búra.
^ Tàbí “ìdájọ́ òdodo.”
^ Tàbí “Ẹ nàró.”