Sáàmù 32:1-11

  • Aláyọ̀ ni àwọn tó rí ìdáríjì

    • “Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ” (5)

    • Ọlọ́run ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye (8)

Ti Dáfídì. Másíkílì.* 32  Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí àṣìṣe rẹ̀ jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.*+   Aláyọ̀ ni ẹni tí Jèhófà kò ka ẹ̀bi sí lọ́rùn,+Ẹni tí kò sí ẹ̀tàn nínú ẹ̀mí rẹ̀.   Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ń ṣàárẹ̀ torí mò ń kérora láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+   Tọ̀sántòru ni ọwọ́* rẹ le lára mi.+ Okun mi ti gbẹ* bí omi ṣe ń gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. (Sélà)   Níkẹyìn, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;Mi ò bo àṣìṣe mi mọ́lẹ̀.+ Mo sọ pé: “Màá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Jèhófà.”+ O sì dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.+ (Sélà)   Ìdí nìyí tí gbogbo adúróṣinṣin yóò máa gbàdúrà sí ọ+Nígbà tí wọ́n ṣì lè rí ọ.+ Kódà nígbà náà, àkúnya omi kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.   Ìwọ ni ibi ìfarapamọ́ mi;Wàá dáàbò bò mí nínú wàhálà.+ Wàá fi igbe ayọ̀ ìgbàlà yí mi ká.+ (Sélà)   “Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+ Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.+   Ẹ má dà bí ẹṣin tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tí kò ní òye,+Tó jẹ́ pé ìjánu tàbí okùn la fi ń kì í wọ̀ tó bá ń ta pọ́n-ún pọ́n-únKó tó lè sún mọ́ni.” 10  Ọ̀pọ̀ ni ìrora ẹni burúkú;Àmọ́ ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé E ká.+ 11  Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin olódodo;Ẹ kígbe ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ọkàn yín dúró ṣinṣin.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì.”
Tàbí “ìbínú.”
Tàbí “Ọ̀rinrin ayé mi ti yí pa dà.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.