Sáàmù 33:1-22
33 Ẹ̀yin olódodo, ẹ kígbe ayọ̀, nítorí Jèhófà.+
Ó yẹ àwọn adúróṣinṣin láti máa yìn ín.
2 Ẹ fi háàpù dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà;Ẹ fi orin yìn ín* pẹ̀lú ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá.
3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;+Ẹ fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín dárà, bí ẹ ti ń kígbe ayọ̀.
4 Nítorí ọ̀rọ̀ Jèhófà dúró ṣinṣin,+Gbogbo ohun tó bá ṣe ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.
5 Ó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.+
Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ kún inú ayé.+
6 Ọ̀rọ̀ ni Jèhófà fi dá àwọn ọ̀run,+Nípa èémí* ẹnu rẹ̀ sì ni gbogbo ohun tó wà nínú wọn* fi wà.
7 Ó gbá omi òkun jọ bí ìsédò;+
Ó fi omi tó ń ru gùdù sínú àwọn ilé ìṣúra.
8 Kí gbogbo ayé bẹ̀rù Jèhófà.+
Kí gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ń méso jáde máa bẹ̀rù rẹ̀.
9 Nítorí ó sọ̀rọ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀;+Ó pàṣẹ, àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀.+
10 Jèhófà ti mú kí ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè gbèrò* já sí òfo;+Ó ti dojú ìmọ̀ràn* àwọn èèyàn dé.+
11 Àmọ́ àwọn ìpinnu* Jèhófà yóò dúró títí láé;+Èrò ọkàn rẹ̀ wà láti ìran dé ìran.
12 Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀,+Àwọn èèyàn tí ó ti yàn láti jẹ́ ohun ìní rẹ̀.+
13 Jèhófà bojú wolẹ̀ láti ọ̀run;Ó ń rí gbogbo ọmọ èèyàn.+
14 Láti ibi tó ń gbé,Ó ń wo gbogbo àwọn tó ń gbé ayé.
15 Òun ló ń mọ ọkàn gbogbo èèyàn bí ẹni mọ ìkòkò;Ó ń gbé gbogbo iṣẹ́ wọn yẹ̀ wò.+
16 Ọ̀pọ̀ ọmọ ogun kọ́ ló ń gba ọba là;+Agbára ńlá kò sì lè gba ẹni tó ni ín sílẹ̀.+
17 Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹṣin pé á gbani là* jẹ́ asán;+Agbára ńlá rẹ̀ kò sọ pé kéèyàn yè bọ́.
18 Wò ó! Ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+Àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
19 Láti gbà wọ́n* sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú,Kí ó sì mú kí wọ́n máa wà láàyè ní àkókò ìyàn.+
20 À* ń dúró de Jèhófà.
Òun ni olùrànlọ́wọ́ wa àti apata wa.+
21 Ọkàn wa ń yọ̀ nínú rẹ̀,Nítorí a gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.+
22 Jèhófà, kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa,+Bí a ti ń dúró dè ọ́.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ẹ kọ orin sí i.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun wọn.”
^ Tàbí “ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè.”
^ Tàbí “èrò.”
^ Tàbí “ìmọ̀ràn.”
^ Tàbí “fúnni ní ìṣẹ́gun.”
^ Tàbí “ọkàn wọn.”
^ Tàbí “Ọkàn wa.”