Sáàmù 41:1-13

  • Àdúrà lórí ibùsùn àìsàn

    • Ọlọ́run ń fún aláìsàn lókun (3)

    • Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ dalẹ̀ mi (9)

Sí olùdarí. Orin Dáfídì. 41  Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ro ti àwọn aláìní;+Jèhófà yóò gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ àjálù.   Jèhófà yóò dáàbò bò ó, yóò sì pa á mọ́. A ó pè é ní aláyọ̀ ní ayé;+O kò sì ní jẹ́ kí èrò* àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣẹ lé e lórí.+   Jèhófà yóò fún un lókun lórí ibùsùn àìsàn rẹ̀;+Ìwọ yóò pààrọ̀ ibùsùn rẹ̀ nígbà tó ń ṣàìsàn.   Mo sọ pé: “Jèhófà, ṣojú rere sí mi.+ Wò mí* sàn,+ torí mo ti ṣẹ̀ sí ọ.”+   Àmọ́ àwọn ọ̀tá mi ń sọ ọ̀rọ̀ burúkú nípa mi pé: “Ìgbà wo ló máa kú, tí orúkọ rẹ̀ á sì pa rẹ́?”   Tí ọ̀kan nínú wọn bá wá rí mi, irọ́ tó wà lọ́kàn rẹ̀ lá máa pa. Ọ̀rọ̀ tó ń dunni lá máa kó jọ;Lẹ́yìn náà, á jáde lọ, á sì máa sọ ọ́ kiri.   Gbogbo àwọn tó kórìíra mi ń bára wọn sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́;Wọ́n ń gbèrò ibi sí mi pé:   “Ohun tó ń bani lẹ́rù ti dé bá a;Ní báyìí tó ti ṣubú lulẹ̀, kò ní dìde mọ́.”+   Kódà, ẹni tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo fọkàn tán,+Ẹni tí a jọ ń jẹun, ti jìn mí lẹ́sẹ̀.*+ 10  Àmọ́, Jèhófà, ṣojú rere sí mi, kí o sì gbé mi dìde,Kí n lè san án pa dà fún wọn. 11  Ohun tí màá fi mọ̀ pé inú rẹ dùn sí mi nìyí: Kí àwọn ọ̀tá mi má lè kígbe ìṣẹ́gun lé mi lórí.+ 12  Ní tèmi, o ti dì mí mú nítorí ìwà títọ́ mi;+Wàá fi mí sí iwájú rẹ títí láé.+ 13  Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì Títí láé àti láéláé.*+ Àmín àti Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìfẹ́ ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “yíjú pa dà sí mi.”
Tàbí “Láti ayérayé dé ayérayé.”