Sáàmù 50:1-23
Orin Ásáfù.+
50 Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Jèhófà,*+ ti sọ̀rọ̀;Ó pe ayéLáti yíyọ oòrùn títí dé wíwọ̀ rẹ̀.*
2 Láti Síónì, tí ó ní ẹwà pípé,+ ni Ọlọ́run ti tàn jáde.
3 Ọlọ́run wa yóò wá, kò sì ní dákẹ́.+
Iná tó ń jó nǹkan run wà níwájú rẹ̀,+Ìjì tó lágbára sì ń jà ní gbogbo àyíká rẹ̀.+
4 Ó pe ọ̀run lókè, ó sì pe ayé,+Kí ó lè ṣèdájọ́ àwọn èèyàn rẹ̀,+ ó ní:
5 “Ẹ kó àwọn ẹni ìdúróṣinṣin mi jọ sọ́dọ̀ mi,Àwọn tí wọ́n fi ẹbọ bá mi dá májẹ̀mú.”+
6 Àwọn ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀,Nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́ Onídàájọ́.+ (Sélà)
7 “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;Ìwọ Ísírẹ́lì, màá ta kò ọ́.+
Èmi ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.+
8 Mi ò bá ọ wí nítorí àwọn ẹbọ rẹTàbí nítorí àwọn odindi ẹbọ sísun rẹ tó wà níwájú mi nígbà gbogbo.+
9 Mi ò nílò akọ màlúù láti ilé rẹ,Bẹ́ẹ̀ ni mi ò nílò àwọn ewúrẹ́* látinú ọgbà ẹran rẹ.+
10 Nítorí pé tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó,+Títí kan àwọn ẹranko tó wà lórí gbogbo òkè.
11 Mo mọ gbogbo ẹyẹ tó wà lórí àwọn òkè;+Àìlóǹkà àwọn ẹran tó wà nínú pápá jẹ́ tèmi.
12 Ká ní ebi ń pa mí, mi ò ní sọ fún ọ,Nítorí ilẹ̀ eléso àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ tèmi.+
13 Ṣé mo fẹ́ jẹ ẹran màlúù* niÀbí mo fẹ́ mu ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?+
14 Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,+Kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ;+
15 Pè mí ní àkókò wàhálà.+
Màá gbà ọ́ sílẹ̀, wàá sì máa yìn mí lógo.”+
16 Àmọ́ Ọlọ́run yóò sọ fún ẹni burúkú pé:
“Ẹ̀tọ́ wo lo ní láti máa sọ àwọn ìlànà mi+Tàbí láti máa sọ nípa májẹ̀mú mi?+
17 Nítorí o kórìíra ìbáwí,*O sì ń kọ ẹ̀yìn sí ọ̀rọ̀ mi.*+
18 Nígbà tí o rí olè, o tẹ́wọ́ gbà á,*+O sì ń bá àwọn alágbèrè kẹ́gbẹ́.
19 Ò ń fi ẹnu rẹ sọ ohun búburú kiri,Ẹ̀tàn sì wà lórí ahọ́n rẹ.+
20 O jókòó, o sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí arákùnrin rẹ;+O fi àléébù ọmọ ìyá rẹ hàn.*
21 Nígbà tí o ṣe àwọn nǹkan yìí, mi ò sọ̀rọ̀,Torí náà, o rò pé màá dà bíi tìẹ.
Àmọ́ ní báyìí, màá bá ọ wí,Màá sì pè ọ́ lẹ́jọ́.+
22 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rò ó wò ná, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọ́run,+Kí n má bàa fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tó máa gbà yín sílẹ̀.
23 Ẹni tó mú ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi ń yìn mí lógo,+Ní ti ẹni tó sì ń rin ọ̀nà tí ó tọ́,Màá mú kí ó rí ìgbàlà látọ̀dọ̀ mi.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Olú Ọ̀run, Ọlọ́run, Jèhófà.”
^ Tàbí “Láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”
^ Ní Héb., “òbúkọ.”
^ Ìyẹn, akọ màlúù.
^ Ní Héb., “ń ju ọ̀rọ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.”
^ Tàbí “ẹ̀kọ́.”
^ Tàbí kó jẹ́, “o dara pọ̀ mọ́ ọn.”
^ Tàbí “sọ̀rọ̀ ọmọ ìyá rẹ láìdáa.”