Sáàmù 7:1-17
-
Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà
-
“Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà” (8)
-
Orin arò* Dáfídì tí ó kọ sí Jèhófà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ Kúṣì ọmọ Bẹ́ńjámínì.
7 Jèhófà Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.+
Gbà mí lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi, kí o sì dá mi nídè.+
2 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n á fà mí* ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bíi kìnnìún,+Wọ́n á gbé mi lọ láìsí ẹni tó máa gbà mí sílẹ̀.
3 Jèhófà Ọlọ́run mi, tí mo bá jẹ̀bi nínú ọ̀ràn yìí,Tí mo bá ṣe àìtọ́,
4 Tí mo bá ṣe àìdáa sí ẹni tó ṣe rere sí mi,+Tàbí kẹ̀, tí mo bá kó ẹrù ọ̀tá mi lọ láìnídìí,*
5 Kí ọ̀tá máa lépa mi, kó sì bá mi;*Kó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀Kó sì mú kí ògo mi pa rẹ́ mọ́ ilẹ̀. (Sélà)
6 Dìde nínú ìbínú rẹ, Jèhófà;Gbéra láti kojú àwọn ọ̀tá mi nínú ìbínú wọn;+Jí nítorí mi, kí o sì mú kí wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo.+
7 Kí àwọn orílẹ̀-èdè yí ọ ká;Kí o sì gbéjà kò wọ́n látòkè.
8 Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn.+
Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí òdodo miÀti gẹ́gẹ́ bí ìwà títọ́ mi.+
9 Jọ̀wọ́, fòpin sí ìwà ibi àwọn ẹni burúkú.
Àmọ́, fìdí olódodo múlẹ̀,+Nítorí pé Ọlọ́run olódodo ni ọ́,+ tó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn+ àti inú lọ́hùn-ún.*+
10 Ọlọ́run ni apata mi,+ Olùgbàlà àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+
11 Ọlọ́run jẹ́ Onídàájọ́ òdodo,+Ọlọ́run sì ń kéde ìdájọ́ rẹ̀* lójoojúmọ́.
12 Bí ẹnikẹ́ni kò bá ronú pìwà dà,+ Á pọ́n idà rẹ̀;+Á tẹ ọrun rẹ̀, á sì mú kó wà ní sẹpẹ́.+
13 Ó ń ṣètò àwọn ohun ìjà rẹ̀ tó ń ṣekú pani sílẹ̀;Ó ń mú kí àwọn ọfà rẹ̀ tó ń jó fòfò wà ní sẹpẹ́.+
14 Wo ẹni tó lóyún ìwà ìkà;Ọmọ* ìjàngbọ̀n wà nínú rẹ̀, ó sì bí èké.+
15 Ó ti wa kòtò, ó sì gbẹ́ ẹ jìn,Àmọ́ ó já sínú ihò tí òun fúnra rẹ̀ gbẹ́.+
16 Wàhálà tó dá sílẹ̀ á pa dà sí orí òun fúnra rẹ̀;+Ìwà ipá rẹ̀ á sì já lé àtàrí rẹ̀.
17 Màá yin Jèhófà nítorí òdodo rẹ̀,+Màá sì fi orin yin* orúkọ Jèhófà+ Ẹni Gíga Jù Lọ.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọ̀fọ̀.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Tí mo sì dá ẹni tó ń ta kò mí sí láìnídìí.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “dán ọkàn àti kíndìnrín wò.”
^ Tàbí “rọ̀jò ìdálẹ́bi.”
^ Tàbí “Ọlẹ̀.”
^ Tàbí “kọ orin sí.”