Sáàmù 72:1-20
Nípa Sólómọ́nì.
72 Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+
2 Kí ó fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ rò,Kí ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.+
3 Kí àwọn òkè ńlá fún àwọn èèyàn ní àlàáfíà,Kí àwọn òkè kéékèèké sì mú òdodo wá.
4 Kí ó gbèjà* àwọn tó jẹ́ aláìní,Kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là,Kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́.+
5 Láti ìran dé ìran,Wọ́n á máa bẹ̀rù rẹ níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà,Tí òṣùpá sì ń yọ.+
6 Yóò dà bí òjò tó ń rọ̀ sórí koríko tí a gé,Bí ọ̀wààrà òjò tó ń mú kí ilẹ̀ rin.+
7 Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀,*+Àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀+ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.
8 Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́* láti òkun dé òkunÀti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+
9 Àwọn tó ń gbé ní aṣálẹ̀ yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.+
10 Àwọn ọba Táṣíṣì àti ti àwọn erékùṣù yóò máa san ìṣákọ́lẹ̀.*+
Àwọn ọba Ṣébà àti ti Sébà yóò mú ẹ̀bùn wá.+
11 Gbogbo àwọn ọba yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa sìn ín.
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,Yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
13 Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà,Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tálákà là.
14 Yóò gbà wọ́n* lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá,Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye lójú rẹ̀.
15 Kí ó máa wà láàyè, kí a sì fún un ní wúrà Ṣébà.+
Kí a máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo,Kí a sì máa bù kún un láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
16 Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ* máa wà lórí ilẹ̀;+Ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.
Èso rẹ̀ máa dára bíi ti Lẹ́bánónì,+Nínú àwọn ìlú, àwọn èèyàn máa pọ̀ bí ewéko ilẹ̀.+
17 Kí orúkọ rẹ̀ wà títí láé,+Kí ó sì máa lókìkí níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà.
Kí àwọn èèyàn gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀;+Kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀.
18 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+Òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+
19 Kí á yin orúkọ rẹ̀ ológo títí láé,+Kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ayé.+
Àmín àti Àmín.
20 Ibí ni àdúrà Dáfídì, ọmọ Jésè+ parí sí.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “dá ẹjọ́.”
^ Ní Héb., “rú jáde.”
^ Tàbí “ṣàkóso.”
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Tàbí “owó òde.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ra ọkàn wọn pa dà.”
^ Tàbí “ọkà.”