Sáàmù 78:1-72
Másíkílì.* Ti Ásáfù.+
78 Ẹ fetí sí òfin* mi, ẹ̀yin èèyàn mi;Ẹ tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 Màá la ẹnu mi láti pa òwe.
Màá pa àwọn àlọ́ tó ti wà tipẹ́tipẹ́.+
3 Àwọn ohun tí a ti gbọ́ tí a sì mọ̀,Èyí tí àwọn bàbá wa sọ fún wa,+
4 A ò ní fi wọ́n pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn;A ó ròyìn fún ìran tó ń bọ̀+Nípa àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ fún ìyìn àti nípa agbára rẹ̀,+Àwọn ohun àgbàyanu tó ti ṣe.+
5 Ó gbé ìránnilétí kan kalẹ̀ ní Jékọ́bù,Ó sì ṣe òfin ní Ísírẹ́lì;Ó pa àṣẹ fún àwọn baba ńlá waPé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ àwọn nǹkan yìí,+
6 Kí ìran tó ń bọ̀,Ìyẹn àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí, lè mọ̀ wọ́n.+
Kí àwọn náà lè ròyìn wọn fún àwọn ọmọ wọn.+
7 Àwọn yìí á wá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.
Wọn ò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run+Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+
8 Wọn ò ní dà bí àwọn baba ńlá wọn,Ìran alágídí àti ọlọ̀tẹ̀,+Ìran tí ọkàn wọn ń ṣe ségesège*+Tí ẹ̀mí wọn ò sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.
9 Àwọn ọmọ Éfúrémù kó ọfà* dání,Àmọ́ wọ́n sá pa dà lọ́jọ́ ogun.
10 Wọn ò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́,+Wọn ò sì tẹ̀ lé òfin rẹ̀.+
11 Wọ́n tún gbàgbé ohun tó ti ṣe,+Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó fi hàn wọ́n.+
12 Ó ṣe àwọn ohun àgbàyanu níwájú àwọn baba ńlá wọn,+Ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní agbègbè Sóánì.+
13 Ó pín òkun sọ́tọ̀, kí wọ́n lè gbà á kọjá,Ó sì mú kí omi òkun dúró bí ìsédò.*+
14 Ó fi ìkùukùu* ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán,Ó sì fi ìmọ́lẹ̀ iná ṣamọ̀nà wọn ní gbogbo òru.+
15 Ó la àpáta ní aginjù,Ó jẹ́ kí wọ́n mu àmutẹ́rùn bíi pé látinú ibú omi.+
16 Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta,Ó sì mú kí omi ṣàn wálẹ̀ bí odò.+
17 Àmọ́ wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí i nìṣó,Bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ ní aṣálẹ̀;+
18 Wọ́n pe Ọlọ́run níjà* nínú ọkàn wọn,+Bí wọ́n ṣe ń béèrè oúnjẹ tí ọkàn wọn fà sí.*
19 Wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run,Wọ́n ní: “Ṣé Ọlọ́run lè tẹ́ tábìlì nínú aginjù ni?”+
20 Wò ó! Ó lu àpátaKí omi lè ṣàn, kí odò sì ya jáde.+
Síbẹ̀ wọ́n ń sọ pé, “Ṣé ó tún lè fún wa ní oúnjẹ ni,Àbí ṣé ó lè pèsè ẹran fún àwọn èèyàn rẹ̀?”+
21 Nígbà tí Jèhófà gbọ́ wọn, inú bí i gan-an;+Iná+ jó Jékọ́bù,Inú rẹ̀ sì ru sí Ísírẹ́lì.+
22 Torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run;+Wọn ò gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó lágbára láti gbà wọ́n là.
23 Torí náà, ó pàṣẹ fún ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ lókè,Ó sì ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run.
24 Ó ń rọ̀jò mánà sílẹ̀ fún wọn láti jẹ;Ó fún wọn ní ọkà ọ̀run.+
25 Àwọn èèyàn jẹ oúnjẹ àwọn alágbára;*+Ó pèsè èyí tó pọ̀ tó kí wọ́n lè jẹ àjẹyó.+
26 Ó ru ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn sókè ní ọ̀run,Ó sì mú kí ẹ̀fúùfù gúúsù fẹ́ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.+
27 Ó rọ̀jò ẹran lé wọn lórí bí eruku,Àwọn ẹyẹ bí iyanrìn etíkun.
28 Ó mú kí wọ́n já bọ́ sí àárín ibùdó rẹ̀,Káàkiri àwọn àgọ́ rẹ̀.
29 Wọ́n jẹ àjẹyó àti àjẹkì;Ó fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.+
30 Àmọ́ kí wọ́n tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn pátápátá,Nígbà tí oúnjẹ wọn ṣì wà lẹ́nu wọn,
31 Ìbínú Ọlọ́run ru sí wọn.+
Ó pa àwọn ọkùnrin wọn tó lágbára jù lọ;+Ó mú àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ísírẹ́lì balẹ̀.
32 Láìka gbogbo èyí sí, ṣe ni wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lé ẹ̀ṣẹ̀,+Wọn ò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+
33 Torí náà, ó fòpin sí ọjọ́ ayé wọn bíi pé èémí lásán ni,+Ó sì fòpin sí ọdún wọn nípasẹ̀ àjálù òjijì.
34 Àmọ́ tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n, wọ́n á wá a;+Wọ́n á pa dà, wọ́n á sì wá Ọlọ́run,
35 Wọ́n á rántí pé Ọlọ́run ni Àpáta wọn+Àti pé Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùdáǹdè* wọn.+
36 Àmọ́ wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn tàn án jẹ,Kí wọ́n sì fi ahọ́n wọn parọ́ fún un.
37 Ọkàn wọn ò ṣe déédéé pẹ̀lú rẹ̀;+Wọn ò sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.+
38 Àmọ́, ó jẹ́ aláàánú;+Ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,* kò sì ní pa wọ́n run.+
Ó máa ń fawọ́ ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn lọ́pọ̀ ìgbà,+Kàkà tí ì bá fi jẹ́ kí gbogbo ìbínú rẹ̀ ru.
39 Nítorí ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,+Afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ kọjá, tí kì í sì í pa dà wá.*
40 Ẹ wo iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù,+Tí wọ́n sì bà á nínú jẹ́ ní aṣálẹ̀!+
41 Léraléra ni wọ́n dán Ọlọ́run wò,+Wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá* Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
42 Wọn ò rántí agbára* rẹ̀,Lọ́jọ́ tó gbà wọ́n* lọ́wọ́ ọ̀tá,+
43 Bó ṣe fi àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ hàn ní Íjíbítì+Àti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní agbègbè Sóánì,
44 Àti bó ṣe sọ àwọn ipa odò Náílì di ẹ̀jẹ̀,+Tí wọn ò fi lè mu omi àwọn odò wọn.
45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ láti jẹ wọ́n run+Àti àwọn àkèré láti ba ilẹ̀ wọn jẹ́.+
46 Ó fi àwọn ohun ọ̀gbìn wọn fún àwọn ọ̀yánnú eéṣú,Ó sì fi èso iṣẹ́ wọn fún ọ̀wọ́ eéṣú.+
47 Ó fi yìnyín pa àjàrà wọn run,+Ó sì fi àwọn òkúta yìnyín pa àwọn igi síkámórè wọn.
48 Ó fi yìnyín pa àwọn ẹran akẹ́rù wọn,+Ó sì sán ààrá* pa àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.
49 Ó tú ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lé wọn lórí,Ìbínú ńlá àti ìrunú àti wàhálà,Ó rán àwùjọ àwọn áńgẹ́lì láti mú àjálù wá.
50 Ó la ọ̀nà fún ìbínú rẹ̀.
Kò dá wọn* sí;Ó sì fi wọ́n* lé àjàkálẹ̀ àrùn lọ́wọ́.
51 Níkẹyìn, ó pa gbogbo àkọ́bí Íjíbítì,+Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn nínú àwọn àgọ́ Hámù.
52 Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde bí agbo ẹran,+Ó sì darí wọn bí ọ̀wọ́ ẹran ní aginjù.
53 Ó darí wọn láìséwu,Wọn ò sì bẹ̀rù ohunkóhun;+Òkun bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀.+
54 Ó mú wọn wá sí ìpínlẹ̀ mímọ́ rẹ̀,+Agbègbè olókè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbà.+
55 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde níwájú wọn;+Ó fi okùn ìdíwọ̀n pín ogún fún wọn;+Ó mú kí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì máa gbé inú ilé wọn.+
56 Àmọ́ wọn ò yéé pe Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ níjà,* wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i;+Wọn ò fiyè sí àwọn ìránnilétí rẹ̀.+
57 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n yíjú pa dà, wọ́n sì di oníbékebèke bí àwọn baba ńlá wọn.+
Wọ́n dà bí ọrun dídẹ̀ tí kò ṣeé gbára lé.+
58 Wọ́n ń fi àwọn ibi gíga wọn mú un bínú ṣáá,+Wọ́n sì fi àwọn ère gbígbẹ́ wọn mú kí ìbínú rẹ̀ ru.*+
59 Ọlọ́run gbọ́, inú sì bí i gidigidi,+Torí náà, ó kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ pátápátá.
60 Níkẹyìn, ó pa àgọ́ ìjọsìn Ṣílò tì,+Àgọ́ tí ó gbé inú rẹ̀ láàárín àwọn èèyàn.+
61 Ó jẹ́ kí àmì agbára rẹ̀ lọ sóko ẹrú;Ó jẹ́ kí ọlá ńlá rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.+
62 Ó jẹ́ kí wọ́n fi idà pa àwọn èèyàn rẹ̀,+Inú sì bí i gidigidi sí ogún rẹ̀.
63 Iná jó àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ run,A kò sì kọ orin ìgbéyàwó fún* àwọn wúńdíá rẹ̀.
64 Wọ́n fi idà pa àwọn àlùfáà rẹ̀,+Àwọn opó wọn ò sì sunkún.+
65 Nígbà náà, Jèhófà jí bíi pé láti ojú oorun,+Bí akíkanjú ọkùnrin+ tí wáìnì dá lójú rẹ̀ nígbà tó jí.
66 Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ pa dà;+Ó mú kí ìtìjú ayérayé bá wọn.
67 Ó kọ àgọ́ Jósẹ́fù sílẹ̀;Kò sì yan ẹ̀yà Éfúrémù.
68 Àmọ́, ó yan ẹ̀yà Júdà,+Òkè Síónì, èyí tí ó nífẹ̀ẹ́.+
69 Ó mú kí ibi mímọ́ rẹ̀ lè máa wà títí lọ bí ọ̀run,*+Bí ayé tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+
70 Ó yan Dáfídì+ ìránṣẹ́ rẹ̀,Ó sì mú un kúrò nínú ọgbà àgùntàn,+
71 Kúrò ní ibi tó ti ń tọ́jú àwọn abo àgùntàn tó ń fọ́mọ lọ́mú;Ó fi í ṣe olùṣọ́ àgùntàn lórí Jékọ́bù, àwọn èèyàn rẹ̀+Àti lórí Ísírẹ́lì, ogún rẹ̀.+
72 Ó fi òtítọ́ ọkàn ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn,+Ó sì darí wọn lọ́nà tó já fáfá.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Ní Héb., “tí ọkàn wọn ò múra sílẹ̀.”
^ Ní Héb., “ọrun.”
^ Tàbí “ògiri.”
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Ní Héb., “dán Ọlọ́run wò.”
^ Tàbí “oúnjẹ fún ọkàn wọn.”
^ Tàbí “àwọn áńgẹ́lì.”
^ Tàbí “Olùgbẹ̀san.”
^ Ní Héb., “Ó máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Pé ẹ̀mí ń jáde lọ, kì í sì í pa dà wá.”
^ Tàbí “Wọ́n sì ṣe ohun tó dun.”
^ Ní Héb., “ọwọ́.”
^ Ní Héb., “rà wọ́n pa dà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “fi ibà amáragbóná fòfò.”
^ Tàbí “ọkàn wọn.”
^ Ní Héb., “ẹ̀mí wọn.”
^ Ní Héb., “dán Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ wò.”
^ Tàbí “mú kí ó jowú.”
^ Ní Héb., “A kò sì yin.”
^ Ní Héb., “Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ kí ó ga bí òkè.”