Sáàmù 83:1-18
Orin. Orin Ásáfù.+
83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;+Má ṣàìsọ̀rọ̀,* má sì dúró jẹ́ẹ́, ìwọ Olú Ọ̀run.
2 Wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú rúkèrúdò;+Àwọn tó kórìíra rẹ ń hùwà ìgbéraga.*
3 Wọ́n fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n gbìmọ̀ pọ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ;Wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ nítorí àwọn àyànfẹ́ rẹ.*
4 Wọ́n sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa wọ́n run kí wọ́n má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,+Kí a má sì rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”
5 Wọ́n fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n máa ṣe;*Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀* láti bá ọ jà,+
6 Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti àwọn ọmọ Hágárì,+
7 Gébálì àti Ámónì+ àti Ámálékì,Filísíà+ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé ní Tírè.+
8 Ásíríà+ pẹ̀lú ti dara pọ̀ mọ́ wọn;Wọ́n ran àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì+ lọ́wọ́.* (Sélà)
9 Kí o ṣe wọ́n bí o ti ṣe Mídíánì,+Bí o ti ṣe Sísérà àti Jábínì ní odò* Kíṣónì.+
10 Wọ́n pa run ní Ẹ́ń-dórì;+Wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn èèyàn pàtàkì wọn bí Órébù àti Séébù,+Kí o sì ṣe àwọn olórí* wọn bíi Séébà àti Sálímúnà,+
12 Nítorí wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba ilẹ̀ tí Ọlọ́run ń gbé.”
13 Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wọ́n bí ẹ̀gún tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yípo yípo,*+Bí àgékù pòròpórò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri.
14 Bí iná tó ń jó igbóÀti bí ọwọ́ iná tó ń jó àwọn òkè,+
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì líle rẹ lépa wọn,+Kí o sì fi ẹ̀fúùfù rẹ kó jìnnìjìnnì bá wọn.+
16 Fi àbùkù bò wọ́n lójú,*Kí wọ́n lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.
17 Kí ojú tì wọ́n, kí jìnnìjìnnì sì bá wọn títí láé;Kí wọ́n tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé;
18 Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,+Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Má pa ẹnu mọ́.”
^ Tàbí “ń gbé orí wọn sókè.”
^ Ní Héb., “àwọn tí o fi pa mọ́.”
^ Tàbí “dá májẹ̀mú.”
^ Ní Héb., “Wọ́n jọ gbàmọ̀ràn pẹ̀lú ọkàn kan.”
^ Ní Héb., “Wọ́n ti di apá fún àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì.”
^ Tàbí “àfonífojì.”
^ Tàbí “àwọn aṣáájú.”
^ Tàbí “ewéko gbígbẹ tí atẹ́gùn ń gbé kiri.”
^ Ní Héb., “kún ojú wọn.”