Sáàmù 96:1-13
96 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà.+
Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ayé!+
2 Ẹ kọrin sí Jèhófà; ẹ yin orúkọ rẹ̀.
Ẹ máa kéde ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.+
3 Ẹ máa kéde ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo àwọn èèyàn.+
4 Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ.
Ó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.
5 Gbogbo ọlọ́run àwọn èèyàn jẹ́ ọlọ́run asán,+Àmọ́ Jèhófà ló dá ọ̀run.+
6 Ògo àti ọlá ńlá* wà pẹ̀lú rẹ̀;+Agbára àti ẹwà wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.+
7 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ìdílé gbogbo ayé,Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+
8 Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀;+Ẹ mú ẹ̀bùn dání wá sínú àwọn àgbàlá rẹ̀.
9 Ẹ forí balẹ̀ fún* Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́;*Kí jìnnìjìnnì bá yín níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
10 Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Jèhófà ti di Ọba!+
Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kò ṣeé ṣí nípò.*
Òun yóò dá ẹjọ́ àwọn èèyàn* lọ́nà tí ó tọ́.”+
11 Kí ọ̀run yọ̀, kí inú ayé sì dùn;Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá;+
12 Kí àwọn pápá àti gbogbo ohun tó wà lórí wọn máa dunnú.+
Ní àkókò kan náà, kí gbogbo igi igbó kígbe ayọ̀+
13 Níwájú Jèhófà, nítorí ó ń bọ̀,*Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.
Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,*+Yóò sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “iyì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “nítorí ògo ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.”
^ Tàbí “jọ́sìn.”
^ Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
^ Tàbí “kò lè ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”
^ Tàbí “gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rò.”
^ Tàbí “ó ti dé.”
^ Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”