Sáàmù 98:1-9
-
Jèhófà jẹ́ Olùgbàlà àti Onídàájọ́ òdodo
-
Jèhófà jẹ́ kí a mọ ìgbàlà rẹ̀ (2, 3)
-
Orin.
98 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+Nítorí ó ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àní apá mímọ́ rẹ̀, ti mú ìgbàlà wá.*+
2 Jèhófà ti jẹ́ kí á mọ ìgbàlà rẹ̀;+Ó ti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè rí òdodo rẹ̀.+
3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sí ilé Ísírẹ́lì.+
Gbogbo ayé ti rí ìgbàlà* Ọlọ́run wa.+
4 Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ayé.
Ẹ túra ká, ẹ kígbe ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.*+
5 Ẹ fi háàpù kọ orin ìyìn* sí Jèhófà,Àní háàpù àti orin tó dùn.
6 Pẹ̀lú kàkàkí àti ìró ìwo,+Ẹ kígbe ìṣẹ́gun níwájú Ọba náà, Jèhófà.
7 Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá,Ayé* àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.
8 Kí àwọn odò pàtẹ́wọ́;Kí àwọn òkè kígbe ayọ̀ pa pọ̀+
9 Níwájú Jèhófà, nítorí ó ń bọ̀ wá* ṣe ìdájọ́ ayé.
Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,*+Yóò sì dá ẹjọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí ó tọ́.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ti jẹ́ kó ṣẹ́gun.”
^ Tàbí “ìṣẹ́gun.”
^ Tàbí “kọrin.”
^ Tàbí “kọrin.”
^ Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”
^ Tàbí “ó ti dé láti.”
^ Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”