Sáàmù 99:1-9

  • Jèhófà, Ọba mímọ́

    • Ó gúnwà lórí àwọn kérúbù (1)

    • Ọlọ́run tó ń dárí jini tó sì ń fìyà jẹni (8)

99  Jèhófà ti di Ọba.+ Kí jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn. Ó gúnwà lórí* àwọn kérúbù.+ Kí ayé mì tìtì.   Jèhófà tóbi ní Síónì,Ó sì ga ju gbogbo èèyàn lọ.+   Kí wọ́n yin orúkọ ńlá rẹ,+Torí ó ń bani lẹ́rù, ó sì jẹ́ mímọ́.   Ọba alágbára ńlá tó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo ni.+ O ti fìdí ohun tí ó tọ́ múlẹ̀ ṣinṣin. O ti mú kí ìdájọ́ òdodo+ àti òtítọ́ wà ní Jékọ́bù.   Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+ kí ẹ sì forí balẹ̀* níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;+Ẹni mímọ́ ni.+   Mósè àti Áárónì wà lára àwọn àlùfáà rẹ̀,+Sámúẹ́lì sì wà lára àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ̀.+ Wọ́n ń pe Jèhófà,Ó sì ń dá wọn lóhùn.+   Ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ látinú ọwọ̀n ìkùukùu.*+ Wọ́n pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti àṣẹ tó fún wọn mọ́.+   Jèhófà Ọlọ́run wa, o dá wọn lóhùn.+ Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń dárí jì wọ́n,+Àmọ́ o fìyà jẹ wọ́n* nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá.+   Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+Kí ẹ sì forí balẹ̀* níwájú òkè mímọ́ rẹ̀.+ Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́,“láàárín.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “o gbẹ̀san lára wọn.”
Tàbí “jọ́sìn.”