Sefanáyà 1:1-18

  • Ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé (1-18)

    • Ọjọ́ Jèhófà ń yára bọ̀ kánkán (14)

    • Fàdákà àti wúrà kò ní lè gba àwọn èèyàn là (18)

1  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Sefanáyà* ọmọ Kúúṣì, ọmọ Gẹdaláyà, ọmọ Amaráyà, ọmọ Hẹsikáyà nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì+ ọba Júdà:   “Màá pa ohun gbogbo rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀,” ni Jèhófà wí.+   “Màá pa èèyàn àti ẹranko rẹ́. Màá pa ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹja inú òkun rẹ́+Àti àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀*+ pẹ̀lú àwọn èèyàn burúkú;Màá sì mú àwọn èèyàn kúrò lórí ilẹ̀,” ni Jèhófà wí.   “Màá na ọwọ́ mi sórí JúdàÀti sórí gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,Gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó ń sin* Báálì+ ní ibí yìí ni màá sì pa rẹ́,Àti orúkọ àwọn àlùfáà ọlọ́run àjèjì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà míì,+   Àti àwọn tó ń forí balẹ̀ lórí òrùlé fún àwọn ọmọ ogun ọ̀run+Àti àwọn tó ń forí balẹ̀, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Jèhófà+ làwọn ń ṣeLẹ́sẹ̀ kan náà, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Málíkámù làwọn ń ṣe;+   Àti àwọn tó pa dà lẹ́yìn Jèhófà+Àti àwọn tí kò wá Jèhófà tàbí àwọn tí kò wádìí nípa rẹ̀.”+   Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+ Jèhófà ti pèsè ẹbọ sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn tí ó pè sí mímọ́.   “Ní ọjọ́ tí Jèhófà pèsè ẹbọ, màá pe àwọn ìjòyè wá jíhìn,Àwọn ọmọ ọba+ àti gbogbo àwọn tó ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè.   Màá sì pe gbogbo ẹni tó ń gun pèpéle* wá jíhìn ní ọjọ́ yẹn,Àwọn tó ń mú kí ìwà ipá àti ẹ̀tàn gbilẹ̀ ní ilé ọ̀gá wọn. 10  Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,“Igbe ẹkún máa wá láti Ẹnubodè Ẹja+Àti ìpohùnréré ẹkún láti apá kejì ìlú náà+Àti ìfọ́yángá láti àwọn òkè. 11  Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tó ń gbé Mákítẹ́ṣì,*Torí pé gbogbo àwọn oníṣòwò* ni wọ́n ti pa rẹ́;*Gbogbo àwọn tó ń wọn fàdákà ni wọ́n sì ti pa run. 12  Ní àkókò yẹn, màá fi fìtílà wá inú Jerúsálẹ́mù fínnífínní,Màá sì pe àwọn tó dẹra nù* wá jíhìn, àwọn tó ń sọ nínú ọkàn wọn pé,‘Jèhófà kò ní ṣe rere, kò sì ní ṣe búburú.’+ 13  Wọ́n á kó ọrọ̀ wọn lọ, wọ́n á sì pa ilé wọn run.+ Wọ́n á kọ́ ilé, ṣùgbọ́n wọn kò ní gbé inú rẹ̀;Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kò ní mu wáìnì rẹ̀.+ 14  Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé!+ Ó sún mọ́lé, ó sì ń yára bọ̀ kánkán!*+ Ìró ọjọ́ Jèhófà korò.+ Akíkanjú ológun máa figbe ta níbẹ̀.+ 15  Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú ńlá,+Ọjọ́ wàhálà àti ìdààmú,+Ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro,Ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+ 16  Ọjọ́ ìwo àti ariwo ogun,+Lòdì sí àwọn ìlú olódi àti sí àwọn ilé gogoro tó wà ní àwọn ìkángun odi.+ 17  Màá fa wàhálà bá aráyé,Wọ́n á sì máa rìn bí afọ́jú,+Nítorí pé wọ́n ti ṣẹ Jèhófà.+ A ó tú ẹ̀jẹ̀ wọn jáde bí erukuÀti ẹran ara* wọn bí ìgbẹ́.+ 18  Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú ńlá Jèhófà;+Torí ìtara rẹ̀ tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run,+Nítorí ó máa pa àwọn èèyàn ayé nípakúpa, àní á pa wọ́n yán-án yán-án.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Pa Á Mọ́ (Fi Ṣúra).”
Ó ṣe kedere pé, àwọn nǹkan tàbí iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà ni.
Tàbí “ìràlẹ̀rálẹ̀.”
Tàbí “etí pèpéle.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pèpéle tí wọ́n ṣe sí ìtẹ́ ọba.
Ní Héb., “pa lẹ́nu mọ́.”
Ó jọ pé apá kan Jerúsálẹ́mù nítòsí Ẹnubodè Ẹja ni.
Tàbí “àwọn olówò.”
Ní Héb., “tó ń dì sórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,” bó ṣe máa ń rí nínú àgbá wáìnì.
Tàbí “sáré tete.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “ìfun.”