Sefanáyà 2:1-15

  • Ẹ wá Jèhófà kí ọjọ́ ìbínú rẹ̀ tó dé (1-3)

    • Ẹ wá òdodo àti ìwà pẹ̀lẹ́ (3)

    • “Bóyá ẹ ó rí ààbò” (3)

  • Ìdájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká (4-15)

2  Ẹ kóra jọ, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ kó ara yín jọ,+Ẹ̀yin èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú.+   Kí àṣẹ náà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́,Kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò,*Kí ìbínú tó ń jó fòfò látọ̀dọ̀ Jèhófà tó wá sórí yín,+Kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó dé bá yín,   Ẹ wá Jèhófà,+ gbogbo ẹ̀yin oníwà pẹ̀lẹ́* ayé,Tó ń pa àṣẹ òdodo* rẹ̀ mọ́. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìwà pẹ̀lẹ́.* Bóyá* ẹ ó rí ààbò ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.+   Nítorí Gásà máa di ìlú tí a pa tì;Áṣíkẹ́lónì á sì di ahoro.+ Áṣídódì ni wọ́n á lé jáde ní ọ̀sán gangan,*Ẹ́kírónì ni a ó sì fà tu.+   “Ẹ gbé! Ẹ̀yin tó ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè àwọn Kérétì.+ Jèhófà ti bá yín wí. Ìwọ Kénáánì, ilẹ̀ àwọn Filísínì, màá pa ọ́ run,Tí kò fi ní sí olùgbé kan tó máa ṣẹ́ kù.   Etí òkun náà á di ilẹ̀ ìjẹko,Tó ní àwọn kànga fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti àwọn ọgbà tí a fi òkúta ṣe fún àwọn àgùntàn.   Á sì di agbègbè fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára ilé Júdà;+Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa jẹun. Wọ́n á dùbúlẹ̀ sí àwọn ilé Áṣíkẹ́lónì ní ìrọ̀lẹ́. Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wọn máa ṣíjú àánú wò wọ́n,*Á sì kó àwọn tó wà ní oko ẹrú lára wọn pa dà.”+   “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ẹnu Móábù+ àti èébú àwọn ọmọ Ámónì,+Àwọn tó kẹ́gàn àwọn èèyàn mi, tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ wọn láti gba ilẹ̀ wọn.+   Nítorí náà, bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,“Móábù máa dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,+Àti àwọn ọmọ Ámónì bíi Gòmórà,+Ibi tí èsìsì wà, tí kòtò iyọ̀ wà, tó sì ti di ahoro títí láé.+ Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn mi á kó wọn lọ,Àwọn tó ṣẹ́ kù nínú orílẹ̀-èdè mi á sì gba tọwọ́ wọn. 10  Èyí ni ohun tí wọ́n máa gbà nítorí ìgbéraga wọn,+Torí pé wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì ń gbé ara wọn ga sí àwọn èèyàn Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. 11  Jèhófà máa dẹ́rù bà wọ́n;*Nítorí ó máa mú kí gbogbo àwọn ọlọ́run tó wà ní ayé di asán,*Gbogbo erékùṣù àwọn orílẹ̀-èdè á sì forí balẹ̀ fún un,*+Láti ibi tí kálukú wọn wà. 12  Ẹ̀yin ará Etiópíà, idà mi ni yóò pa ẹ̀yin náà.+ 13  Ó máa na ọwọ́ rẹ̀ sí àríwá, á sì pa Ásíríà run,Á sọ Nínéfè di ahoro,+ á sì gbẹ bí aṣálẹ̀. 14  Àwọn agbo ẹran máa dùbúlẹ̀ sí àárín rẹ̀, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́.* Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ máa sùn mọ́jú láàárín àwọn ọpọ́n orí òpó rẹ̀. Ohùn kan á kọrin lójú fèrèsé.* Ibi àbáwọlé á di ahoro;Torí pé, ó máa mú kí ilẹ̀kùn kédárì jẹ. 15  Èyí ni ìlú agbéraga tó wà ní ààbò,Tó ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíì.’ Ẹ wo bó ṣe di ohun àríbẹ̀rù,Ibi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ dùbúlẹ̀ sí! Gbogbo ẹni tó bá ń gba ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá á súfèé, á sì mi orí rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
Tàbí “ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀.”
Ní Héb., “ìdájọ́ rẹ̀.”
Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀.”
Tàbí “Ó lè jẹ́ pé.”
Tàbí “ọ̀sán ganrínganrín.”
Tàbí “tọ́jú wọn.”
Tàbí “jọ́sìn rẹ̀.”
Tàbí “rù hangogo.”
Tàbí “mú kí àyà wọn já.”
Ní Héb., “ẹranko orílẹ̀-èdè.”
Tàbí “wíńdò.”